Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 7:18 - Bibeli Mimọ

18 Ẹniti nsọ̀ ti ara rẹ̀ nwá ogo ara rẹ̀: ṣugbọn ẹniti nwá ogo ẹniti o rán a, on li olõtọ, kò si si aiṣododo ninu rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

18 Ẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ti ara rẹ̀ ń wá ògo ti ara rẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí ó bá ń wá ògo ẹni tí ó rán an níṣẹ́ jẹ́ olóòótọ́, kò sí aiṣododo ninu rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

18 Ẹni tí ń sọ ti ara rẹ̀ ń wá ògo ara rẹ̀: ṣùgbọ́n ẹni tí ń wá ògo ẹni tí ó rán an, òun ni olóòtítọ́, kò sì sí àìṣòdodo nínú rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 7:18
19 Iomraidhean Croise  

Kò dara lati mã jẹ oyin pupọ: bẹni kò dara lati mã wa ogo ara ẹni.


Mose si wi fun u pe, Iwọ njowú nitori mi? gbogbo enia OLUWA iba le jẹ́ wolĩ, ki OLUWA ki o fi ẹmi rẹ̀ si wọn lara!


Nitorina bayi ni ki ẹnyin mã gbadura: Baba wa ti mbẹ li ọrun; Ki a bọ̀wọ fun orukọ rẹ.


Nigbati Jesu si gbọ́, o wipe, Aisan yi kì iṣe si ikú, ṣugbọn fun ogo Ọlọrun, ki a le yìn Ọmọ Ọlọrun logo nipasẹ rẹ̀.


Baba, ṣe orukọ rẹ logo. Nitorina ohùn kan ti ọrun wá, wipe, Emi ti ṣe e logo na, emi o si tún ṣe e logo.


Nitori nwọn fẹ iyìn enia jù iyìn ti Ọlọrun lọ.


Emi kò gbà ogo lọdọ enia.


Jesu dahùn wipe, Bi mo ba nyìn ara mi li ogo, ogo mi kò jẹ nkan: Baba mi ni ẹniti nyìn mi li ogo, ẹniti ẹnyin wipe, Ọlọrun nyin ni iṣe:


Bẹni awa kò wá ogo lọdọ enia, tabi lọdọ nyin, tabi lọdọ awọn ẹlomiran, nigbati awa iba fẹ ọla lori nyin bi awọn aposteli Kristi.


Bi ẹnikẹni ba nsọ̀rọ, ki o mã sọ bi ọ̀rọ Ọlọrun; bi ẹnikẹni ba nṣe iṣẹ iranṣẹ, ki o ṣe e bi agbara ti Ọlọrun fifun u: ki a le mã yìn Ọlọrun logo li ohun gbogbo nipa Jesu Kristi, ẹniti ogo ati ìjọba wà fun lai ati lailai. Amin.


Bi ẹnyin ba mọ̀ pe olododo ni on, ẹ mọ̀ pe a bi olukuluku ẹniti nṣe ododo nipa rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan