Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 6:57 - Bibeli Mimọ

57 Gẹgẹ bi Baba alãye ti rán mi, ti emi si ye nipa Baba: gẹgẹ bẹ̃li ẹniti o jẹ mi, on pẹlu yio yè nipa mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

57 Gẹ́gẹ́ bí Baba alààyè ti rán mi, bẹ́ẹ̀ ni mo wà láàyè nítorí ti Baba. Ẹni tí ó bá jẹ ẹran ara mi, yóo yè nítorí tèmi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

57 Gẹ́gẹ́ bí Baba alààyè ti rán mi, tí èmi sì yè nípa Baba gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó jẹ mí, òun pẹ̀lú yóò yè nípa mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 6:57
19 Iomraidhean Croise  

Oluwa mbẹ; olubukún si li apáta mi; ki a si gbé Ọlọrun igbala mi leke.


Ṣugbọn Oluwa, Ọlọrun otitọ ni, on ni Ọlọrun alãye, ati Ọba aiyeraiye! aiye yio warìri nigbati o ba binu, orilẹ-ède kì yio le duro ni ibinu rẹ̀.


Simoni Peteru dahùn, wipe, Kristi, Ọmọ Ọlọrun alãye ni iwọ iṣe.


Nigba diẹ si i, aiye ki ó si ri mi mọ́; ṣugbọn ẹnyin ó ri mi: nitoriti emi wà lãye, ẹnyin ó wà lãye pẹlu.


Jesu wi fun u pe, Emi li ọ̀na, ati otitọ, ati iye: kò si ẹnikẹni ti o le wá sọdọ Baba, bikoṣe nipasẹ mi.


Ki gbogbo nwọn ki o le jẹ ọ̀kan; gẹgẹ bi iwọ, Baba, ti jẹ ninu mi, ati emi ninu rẹ, ki awọn pẹlu ki o le jẹ ọ̀kan ninu wa: ki aiye ki o le gbagbọ́ pe, iwọ li o rán mi.


Nitori Ọlọrun kò rán Ọmọ rẹ̀ si aiye lati da araiye lẹjọ; ṣugbọn ki a le ti ipasẹ rẹ̀ gbà araiye là.


Nitoripe gẹgẹ bi Baba ti ni iye ninu ara rẹ̀; gẹgẹ bẹ̃li o si fifun Ọmọ lati ni iye ninu ara rẹ̀;


Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Eyi ni iṣẹ Ọlọrun pe, ki ẹnyin ki o gbà ẹniti o rán gbọ́.


Nitori emi sọkalẹ lati ọrun wá, ki iṣe lati mã ṣe ifẹ ti emi tikarami, bikoṣe ifẹ ti ẹniti o rán mi.


Nitori bi gbogbo enia ti kú ninu Adamu, bẹ̃ni a ó si sọ gbogbo enia di alãye ninu Kristi.


Bẹ̃li a si kọ ọ pe, Adamu ọkunrin iṣaju, alãye ọkàn li a da a; Adamu ikẹhin ẹmí isọnidãye.


Nitoripe a kàn a mọ agbelebu nipa ailera, ṣugbọn on wà lãye nipa agbara Ọlọrun. Nitori awa pẹlu jasi alailera ninu rẹ̀, ṣugbọn awa ó wà lãye pẹlu rẹ̀ nipa agbara Ọlọrun si nyin.


A ti kàn mi mọ agbelebu pẹlu Kristi: ṣugbọn mo wà lãye, sibẹ ki iṣe emi mọ́, ṣugbọn Kristi wà lãye ninu mi: wiwà ti mo si wà lãye ninu ara, mo wa lãye ninu igbagbọ Ọmọ Ọlọrun, ẹniti o fẹ mi, ti o si fi on tikararẹ̀ fun mi.


Nitoripe awọn tikarawọn ròhin nipa wa, irú iwọle ti awa ti ni sọdọ nyin, bi ẹnyin si ti yipada si Ọlọrun kuro ninu ère lati mã sìn Ọlọrun alãye ati otitọ;


Melomelo li ẹ̀jẹ Kristi, ẹni nipa Ẹmí aiyeraiye ti a fi ara rẹ̀ rubọ si Ọlọrun li aini àbawọn, yio wẹ̀ ẹrí-ọkàn nyin mọ́ kuro ninu okú ẹṣẹ lati sìn Ọlọrun alãye?


Nipa eyi li a gbé fi ifẹ Ọlọrun hàn ninu wa, nitoriti Ọlọrun rán Ọmọ bíbi rẹ̀ nikanṣoṣo si aiye, ki awa ki o le yè nipasẹ rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan