Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 6:2 - Bibeli Mimọ

2 Ọpọ ijọ enia si tọ̀ ọ lẹhin, nitoriti nwọn ri iṣẹ àmi rẹ̀, ti o nṣe lara awọn alaisàn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Ọ̀pọ̀ eniyan ń tẹ̀lé e nítorí wọ́n rí iṣẹ́ ìyanu tí ó ń ṣe lára àwọn aláìsàn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, nítorí tí wọ́n rí iṣẹ́ ààmì rẹ̀ tí ó ń ṣe lára àwọn aláìsàn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 6:2
19 Iomraidhean Croise  

Nigbati Jesu ṣi mọ̀, o yẹ̀ ara rẹ̀ kuro nibẹ̀; ọ̀pọ ijọ enia tọ̀ ọ lẹhin, o si mu gbogbo wọn larada.


Ọpọlọpọ enia pejọ sọdọ rẹ̀, tobẹ̃ ti o fi bọ sinu ọkọ̀, o joko; gbogbo enia si duro leti okun.


Jesu jade lọ, o ri ọ̀pọlọpọ enia, inu rẹ̀ si yọ́ si wọn, o si ṣe dida arùn ara wọn.


NIGBATI o ti ori òke sọkalẹ, ọ̀pọ enia ntọ̀ ọ lẹhin.


Ṣugbọn o jade, o si bẹrẹ si ikokiki, ati si itàn ọ̀ran na kalẹ, tobẹ̃ ti Jesu kò si le wọ̀ ilu ni gbangba mọ́, ṣugbọn o wà lẹhin odi nibi iju: nwọn si tọ̀ ọ wá lati ìha gbogbo wá.


Awọn enia si ri wọn nigbati nwọn nlọ, ọ̀pọlọpọ si mọ̀ ọ, nwọn si sare ba ti ẹsẹ lọ sibẹ̀ lati ilu nla gbogbo wá, nwọn si ṣiwaju wọn, nwọn si jùmọ wá sọdọ rẹ̀.


Nigbana li awọn olori alufa ati awọn Farisi pè igbimọ jọ, nwọn si wipe, Kili awa nṣe? nitori ọkunrin yi nṣe ọ̀pọlọpọ iṣẹ àmi.


Nitori eyi ni ijọ enia si ṣe lọ ipade rẹ̀, nitoriti nwọn gbọ́ pe o ti ṣe iṣẹ àmi yi.


Ṣugbọn bi o ti ṣe ọ̀pọlọpọ iṣẹ ami to bayi li oju wọn, nwọn kò gbà a gbọ́;


Akọṣe iṣẹ àmi yi ni Jesu ṣe ni Kana ti Galili, o si fi ogo rẹ̀ hàn; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si gbà a gbọ́.


Nigbati o si wà ni Jerusalemu, ni ajọ irekọja, lakoko ajọ na, ọ̀pọ enia gbà orukọ rẹ̀ gbọ nigbati nwọn ri iṣẹ àmi rẹ̀ ti o ṣe.


Ọpọlọpọ iṣẹ àmi miran ni Jesu ṣe niwaju awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ti a kò kọ sinu iwe yi:


On na li o tọ̀ Jesu wá li oru, o si wi fun u pe, Rabbi, awa mọ̀ pe olukọni lati ọdọ Ọlọrun wá ni iwọ iṣe: nitoripe kò si ẹniti o le ṣe iṣẹ àmi wọnyi ti iwọ nṣe, bikoṣepe Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀.


Nitorina nigbati awọn ọkunrin na ri iṣẹ àmi ti Jesu ṣe, nwọn wipe, Lõtọ eyi ni woli na ti mbọ̀ wá aiye.


Ni ijọ keji, nigbati awọn enia ti o duro li apakeji okun ri pe, kò si ọkọ̀ miran nibẹ̀, bikoṣe ọkanna ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wọ̀, ati pe Jesu kò ba awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wọ̀ inu ọkọ̀ na, ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nikan li o lọ;


Jesu da wọn lohùn o si wipe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnyin nwá mi, ki iṣe nitoriti ẹnyin ri iṣẹ àmi, ṣugbọn nitori ẹnyin jẹ iṣu akara wọnni, ẹnyin si yó.


Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Iṣẹ ami kini iwọ nṣe, ki awa le ri, ki a si gbà ọ gbọ́? Iṣẹ kini iwọ ṣe?


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan