Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 5:44 - Bibeli Mimọ

44 Ẹnyin o ti ṣe le gbagbọ́, ẹnyin ti ngbà ogo lọdọ ara nyin, ti kò wá ogo ti o ti ọdọ Ọlọrun nikan wá?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

44 Báwo ni ẹ ti ṣe lè gbàgbọ́ nígbà tí ó jẹ́ pé láàrin ara yín ni ẹ ti ń gba ọlá, tí ẹ kò wá ọlá ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun nìkan ṣoṣo?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

44 Ẹ̀yin ó ti ṣe lè gbàgbọ́, ẹ̀yin tí ń gba ògo lọ́dọ̀ ara yín tí kò wá ògo tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nìkan wá?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 5:44
26 Iomraidhean Croise  

Oluwa si sọ fun Dafidi baba mi pe, nitoriti o wà li ọkàn rẹ lati kọ́ ile fun orukọ mi, iwọ ṣeun li eyiti o wà li ọkàn rẹ.


Ara Etiopia le yi àwọ rẹ̀ pada, tabi ẹkùn le yi ilà ara rẹ̀ pada? bẹ̃ni ẹnyin pẹlu iba le ṣe rere, ẹnyin ti a kọ́ ni ìwa buburu?


Ṣugbọn gbogbo iṣẹ wọn ni nwọn nṣe nitori ki awọn enia ki o ba le ri wọn: nwọn sọ filakteri wọn di gbigbòro, nwọn fi kún iṣẹti aṣọ wọn.


O si wi fun u pe, O ṣeun, iwọ ọmọ-ọdọ rere: nitoriti iwọ ṣe olõtọ li ohun kikini, gbà aṣẹ lori ilu mẹwa.


Nitori nwọn fẹ iyìn enia jù iyìn ti Ọlọrun lọ.


Iye ainipẹkun na si li eyi, ki nwọn ki o le mọ̀ ọ, iwọ nikan Ọlọrun otitọ, ati Jesu Kristi, ẹniti iwọ rán.


Nitori olukuluku ẹniti o ba hùwa buburu ni ikorira imọlẹ, ki isi wá si imọlẹ, ki a máṣe ba iṣẹ rẹ̀ wí.


Emi kò gbà ogo lọdọ enia.


Ẽtiṣe ti ède mi kò fi yé nyin? nitori ẹ ko le gbọ́ ọ̀rọ mi ni.


Ṣugbọn ogo, ati ọlá, ati alafia, fun olukuluku ẹni ti nhuwa rere, fun Ju ṣaju, ati fun Hellene pẹlu:


Ṣugbọn Ju ti inu ni Ju, ati ikọla ti ọkàn, ninu ẹmi ni, kì iṣe ti ode ara; iyìn ẹniti kò si lọdọ enia, bikoṣe lọdọ Ọlọrun.


Fun awọn ti nfi sũru ni rere-iṣe wá ogo ati ọlá ati aidibajẹ, ìye ainipẹkun;


Nitorina, ẹ máṣe ṣe idajọ ohunkohun ṣaju akokò na, titi Oluwa yio fi de, ẹniti yio mu ohun òkunkun ti o farasin wá si imọlẹ, ti yio si fi ìmọ ọkàn hàn: nigbana li olukuluku yio si ni iyìn tirẹ̀ lọdọ Ọlọrun.


Nitoripe kì iṣe ẹniti nyìn ara rẹ̀ li o yanju, bikoṣe ẹniti Oluwa yìn.


Ẹ máṣe fi ìja tabi ogo asan ṣe ohunkohun: ṣugbọn ni irẹlẹ ọkàn ki olukuluku ro awọn ẹlomiran si ẹniti o san ju on tikararẹ̀ lọ.


Bẹni awa kò wá ogo lọdọ enia, tabi lọdọ nyin, tabi lọdọ awọn ẹlomiran, nigbati awa iba fẹ ọla lori nyin bi awọn aposteli Kristi.


Njẹ fun Ọba aiyeraiye, aidibajẹ, airi, Ọlọrun kanṣoṣo, ni ọlá ati ogo wà fun lai ati lailai. Amin.


Ẹ kiyesara, ará, ki ọkàn buburu ti aigbagbọ́ ki o máṣe wà ninu ẹnikẹni nyin, ni lilọ kuro lọdọ Ọlọrun alãye.


ẸNYIN ará mi, ẹ máṣe fi iṣãju enia dì igbagbọ́ Oluwa wa Jesu Kristi Oluwa ogo mu.


Ki idanwò igbagbọ́ nyin, ti o ni iye lori jù wura ti iṣegbe lọ, bi o tilẹ ṣe pe iná li a fi ndán a wò, ki a le ri i fun iyìn, ati ọlá, ati ninu ogo ni igba ifarahàn Jesu Kristi:


Ti Ọlọrun ọlọ́gbọn nikanṣoṣo, Olugbala wa, li ogo ati ọlá nla, ijọba ati agbara, nisisiyi ati titi lailai. Amin.


O si wipe, emi ti dẹ̀ṣẹ: ṣugbọn bu ọlá fun mi, jọwọ, niwaju awọn agbãgbà enia mi, ati niwaju Israeli, ki o si tun yipada pẹlu mi, ki emi ki o le tẹriba niwaju Oluwa Ọlọrun rẹ.


Nitorina Oluwa Ọlọrun Israeli wipe, Emi ti wi nitotọ pe, ile rẹ ati ile baba rẹ, yio ma rin niwaju mi titi: ṣugbọn nisisiyi Oluwa wipe, ki a má ri i; awọn ti o bu ọla fun mi li emi o bu ọla fun, ati awọn ti kò kà mi si li a o si ṣe alaikasi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan