Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 5:3 - Bibeli Mimọ

3 Ninu wọnyi li ọ̀pọ awọn abirùn enia gbé dubulẹ si, awọn afọju, arọ ati awọn gbigbẹ, nwọn si nduro dè rirú omi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Níbẹ̀ ni ọpọlọpọ àwọn aláìsàn ti máa ń jókòó: àwọn afọ́jú, àwọn arọ, ati àwọn tí ó ní àrùn ẹ̀gbà. Wọn a máa retí ìgbà tí omi yóo rú pọ̀; [

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Ní ẹ̀gbẹ́ odò yìí ni ọ̀pọ̀ àwọn abirùn ènìyàn máa ń gbé dùbúlẹ̀ sí, àwọn afọ́jú, arọ àti aláàrùn ẹ̀gbà, wọ́n sì ń dúró de rírú omi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 5:3
12 Iomraidhean Croise  

O si ṣe, nigbati Jeroboamu, ọba gbọ́ ọ̀rọ enia Ọlọrun, ti o ti kigbe si pẹpẹ na, o wipe, Ẹ mu u. Ọwọ́ rẹ̀ ti o nà si i, si gbẹ, bẹ̃ni kò si le fa a pada sọdọ rẹ̀ mọ.


Ibukún ni fun ẹniti o gbọ́ temi, ti o nṣọ́ ẹnu-ọ̀na mi lojojumọ, ti o si nduro ti opó ẹnu-ilẹkun mi.


O dara ti a ba mã reti ni idakẹjẹ fun igbala Oluwa.


Egbe ni fun oluṣọ agutan asan na ti o fi ọwọ́-ẹran silẹ! idà yio wà li apá rẹ̀, ati li oju ọ̀tun rẹ̀: apá rẹ̀ yio gbẹ patapata, oju ọ̀tun rẹ̀ yio si ṣõkùnkun biribiri.


Ọpọ enia si tọ̀ ọ wá ti awọn ti amukun, afọju, odi, ati arọ, ati ọ̀pọ awọn miran, nwọn si sọ̀ wọn kalẹ lẹba ẹsẹ Jesu, o si mu wọn larada:


Okikí rẹ̀ si kàn yi gbogbo Siria ká; nwọn si gbé awọn alaisàn ti o ni onirũru àrun ati irora wá sọdọ rẹ̀, ati awọn ti o li ẹmi èṣu, ati awọn ti o nsinwin, ati awọn ti o li ẹ̀gba; o si wò wọn sàn.


Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Ẹ pada lọ, ẹ ròhin nkan ti ẹnyin ri, ti ẹnyin si gbọ́ fun Johanu: awọn afọju nriran, awọn amukun nrìn ṣaṣa, a sọ awọn adẹtẹ̀ di mimọ́, awọn aditi ngbọran, a njí awọn okú dide, ati fun awọn òtoṣi li a nwasu ihinrere.


Adagun omi kan si wà ni Jerusalemu, leti bodè agutan, ti a npè ni Betesda li ède Heberu, ti o ni iloro marun.


Nitori angẹli a ma digbà sọkalẹ lọ sinu adagun na, a si ma rú omi: lẹhin igbati a ba ti rú omi na tan ẹnikẹni ti o ba kọ́ wọ̀ inu rẹ̀, a di alaradidá ninu arùnkárun ti o ni.


Ṣugbọn bi awa ba nreti eyi ti awa kò ri, njẹ awa nfi sũru duro dè e.


Nitorina ará, ẹ mu sũru titi di ipadawa Oluwa. Kiyesi i, àgbẹ a mã reti eso iyebiye ti ilẹ, a si mu sũru de e, titi di igbà akọrọ̀ ati arọ̀kuro òjo.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan