Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 5:23 - Bibeli Mimọ

23 Ki gbogbo enia ki o le mã fi ọlá fun Ọmọ gẹgẹ bi nwọn ti nfi ọlá fun Baba. Ẹniti kò ba fi ọlá fun Ọmọ, kò fi ọlá fun Baba ti o rán a.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

23 kí gbogbo eniyan lè bu ọlá fún Ọmọ bí wọ́n ti ń bu ọlá fún Baba. Ẹni tí kò bá bu ọlá fún Ọmọ kò bu ọlá fún Baba tí ó rán an wá sí ayé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

23 Kí gbogbo ènìyàn lè máa fi ọlá fún ọmọ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń fi ọlá fún Baba. Ẹnikẹ́ni tí kò bá fi ọlá fún ọmọ, kò fi ọlá fún Baba tí ó ran an.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 5:23
47 Iomraidhean Croise  

Fi ẹnu kò Ọmọ na lẹnu, ki o máṣe binu, ẹnyin a si ṣegbe li ọ̀na na, bi inu rẹ̀ ba ru diẹ kiun. Ibukún ni fun gbogbo awọn ti o gbẹkẹ wọn le e.


Emi li Oluwa: eyi ni orukọ mi: ogo mi li emi kì yio fi fun ẹlòmiran, bẹ̃ni emi kì yio fi iyìn mi fun ere gbigbẹ́.


Bayi ni Oluwa wi, Ọba Israeli, ati Olurapada rẹ, Oluwa awọn ọmọ-ogun; Emi ni ẹni-ikini, ati ẹni-ikẹhin; ati lẹhin mi ko si Ọlọrun kan.


Lõtọ iwọ li Ọlọrun ti o fi ara rẹ pamọ, Ọlọrun Israeli, Olugbala.


Ẹ sọ ọ, ki ẹ si mu wá, lõtọ, ki nwọn ki o jọ gbimọ̀ pọ̀: tali o mu ni gbọ́ eyi lati igbãni wa? tali o ti sọ ọ lati igba na wá? emi Oluwa kọ? ko si Ọlọrun miran pẹlu mi; Ọlọrun ododo ati Olugbala; ko si ẹlomiran lẹhin mi.


Yọ̀ gidigidi, iwọ ọmọbinrin Sioni; ho, Iwọ ọmọbinrin Jerusalemu: kiye si i, Ọba rẹ mbọ̀wá sọdọ rẹ: ododo li on, o si ni igbalà; o ni irẹ̀lẹ, o si ngùn kẹtẹkẹtẹ, ani ọmọ kẹtẹkẹtẹ.


Ẹniti o ba fẹ baba tabi iya jù mi lọ, kò yẹ ni temi: ẹniti o ba si fẹ ọmọkunrin tabi ọmọbinrin jù mi lọ, kò si yẹ ni temi.


Ohun gbogbo li a fifun mi lati ọdọ Baba mi wá: kò si si ẹniti o mọ̀ Ọmọ, bikoṣe Baba; bẹ̃ni kò si ẹniti o mọ̀ Baba bikoṣe Ọmọ, ati ẹnikẹni ti Ọmọ fẹ fi i hàn fun.


Orukọ rẹ̀ li awọn keferi yio ma gbẹkẹle.


Awọn enia yi nfi ẹnu wọn sunmọ mi, nwọn si nfi ète wọn bọla fun mi; ṣugbọn ọkàn wọn jìna si mi.


Nitorina ẹ lọ, ẹ ma kọ́ orilẹ-ède gbogbo, ki ẹ si mã baptisi wọn ni orukọ Baba, ati ni ti Ọmọ, ati ni ti Ẹmí Mimọ́:


Ẹniti o ba gbọ́ ti nyin, o gbọ́ ti emi: ẹniti o ba si kọ̀ nyin, o kọ̀ mi; ẹniti o ba si kọ̀ mi, o kọ̀ ẹniti o rán mi.


Ẹ maṣe jẹ ki ọkàn nyin dàru: ẹ gbà Ọlọrun gbọ́, ẹ gbà mi gbọ́ pẹlu.


On o ma yìn mi logo: nitoriti yio gbà ninu ti emi, yio si ma sọ ọ fun nyin.


Tirẹ sá ni gbogbo ohun ti iṣe temi, ati temi si ni gbogbo ohun ti iṣe tirẹ; a si ti ṣe mi logo ninu wọn.


Si gbogbo ẹniti o wà ni Romu, olufẹ Ọlọrun, ti a pè lati jẹ mimọ́: Ore-ọfẹ si nyin ati alafia lati ọdọ Ọlọrun Baba wa wá, ati Jesu Kristi Oluwa.


Isaiah si tún wipe, Gbòngbo Jesse kan mbọ̀ wá, ati ẹniti yio dide ṣe akoso awọn Keferi; on li awọn Keferi yio ni ireti si.


Ṣugbọn nisisiyi ti a sọ nyin di omnira kuro ninu ẹ̀ṣẹ, ti ẹnyin si di ẹrú Ọlọrun, ẹnyin ni eso nyin si ìwa mimọ́, ati opin rẹ̀ ìye ainipẹkun.


Ṣugbọn ẹnyin kò si ninu ti ara, bikoṣe ninu ti Ẹmí, biobaṣepe Ẹmí Ọlọrun ngbe inu nyin. Ṣugbọn bi ẹnikẹni kò ba ni Ẹmí Kristi, on kò si ninu ẹni tirẹ̀.


Ore-ọfẹ si nyin, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Oluwa wa Jesu Kristi.


Nitorina bi ẹnyin ba njẹ, tabi bi ẹnyin ba nmu, tabi ohunkohun ti ẹnyin ba nṣe, ẹ mã ṣe gbogbo wọn fun ogo Ọlọrun.


Bi ẹnikẹni kò ba fẹ Jesu Kristi Oluwa, ẹ jẹ ki o di Anatema. Maranata.


Tabi, ẹnyin kò mọ̀ pe ara nyin ni tẹmpili Ẹmí Mimọ́, ti mbẹ ninu nyin, ti ẹnyin ti gbà lọwọ Ọlọrun? ẹnyin kì si iṣe ti ara nyin,


Ṣugbọn awa ni idahùn ikú ninu ara wa, ki awa ki o máṣe gbẹkẹle ara wa, bikoṣe Ọlọrun ti njí okú dide:


Ore-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa, ati ifẹ Ọlọrun, ati ìdapọ ti Ẹmí Mimọ́, ki o wà pẹlu gbogbo nyin. Amin.


Nitori ifẹ Kristi nrọ̀ wa; nitori awa rò bayi, pe bi ẹnikan ba ti kú fun gbogbo enia, njẹ gbogbo wọn li o ti kú:


Eyini ni pe, Ọlọrun wà nínu Kristi, o mba araiye làja sọdọ ara rẹ̀, kò si kà irekọja wọn si wọn lọrùn; o si ti fi ọ̀rọ ìlaja le wa lọwọ.


Ki ore-ọfẹ wà pẹlu gbogbo awọn ti o fẹ Oluwa wa Jesu Kristi li aiṣẹ̀tan.


Nitori idi eyiti emi ṣe njìya wọnyi pẹlu: ṣugbọn oju kò tì mi: nitori emi mọ̀ ẹniti emi gbagbọ́, o si da mi loju pe, on le pa ohun ti mo fi le e lọwọ mọ́ titi di ọjọ nì.


Ati pẹlu, nigbati o mu akọbi ni wá si aiye, o wipe, Ki gbogbo awọn angẹli Ọlọrun ki o foribalẹ fun u.


SIMONI Peteru, iranṣẹ ati Aposteli Jesu Kristi, si awọn ti o ti gbà irú iyebiye igbagbọ́ kanna pẹlu wa, ninu ododo Ọlọrun wa ati ti Jesu Kristi Olugbala:


Ṣugbọn ẹ mã dàgba ninu õre-ọfẹ ati ninu ìmọ Oluwa ati Olugbala wa Jesu Kristi; ẹniti ogo wà fun nisisiyi ati titi lai. Amin.


Ẹnikẹni ti o ba sẹ́ Ọmọ, on na ni kò gbà Baba: ṣugbọn ẹniti o ba jẹwọ Ọmọ, o gbà Baba pẹlu.


Olukuluku ẹniti o ba nru ofin ti kò si duro ninu ẹkọ́ Kristi, kò gba Ọlọrun. Ẹniti o ba duro ninu ẹkọ́, on li o gbà ati Baba ati Ọmọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan