Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 5:22 - Bibeli Mimọ

22 Nitoripe Baba ki iṣe idajọ ẹnikẹni, ṣugbọn o ti fi gbogbo idajọ le Ọmọ lọwọ:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

22 Nítorí Baba kò ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni, ṣugbọn ó ti fi gbogbo ìdájọ́ lé Ọmọ lọ́wọ́,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

22 Nítorí pé Baba kì í ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni, ṣùgbọ́n ó ti fi gbogbo ìdájọ́ lé ọmọ lọ́wọ́:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 5:22
23 Iomraidhean Croise  

Niwaju Oluwa: nitoriti mbọwa, nitori ti mbọwa ṣe idajọ aiye: yio fi ododo ṣe idajọ aiye, ati ti enia ni yio fi otitọ rẹ̀ ṣe.


Niwaju Oluwa; nitori ti mbọwa iṣe idajọ aiye: pẹlu ododo ni yio fi ṣe idajọ aiye, ati awọn orilẹ-ède li aiṣègbe.


Mã yọ̀, iwọ ọdọmọde ninu ewe rẹ; ki o si jẹ ki ọkàn rẹ ki o mu ọ laraya li ọjọ ewe rẹ, ki o si ma rìn nipa ọ̀na ọkàn rẹ ati nipa irí oju rẹ; ṣugbọn iwọ mọ̀ eyi pe, nitori nkan wọnyi Ọlọrun yio mu ọ wá si idajọ.


Nitoripe Ọlọrun yio mu olukuluku iṣẹ wa sinu idajọ, ati olukuluku ohun ìkọkọ, ibã ṣe rere, ibã ṣe buburu.


Ohun gbogbo li a fifun mi lati ọdọ Baba mi wá: kò si si ẹniti o mọ̀ Ọmọ, bikoṣe Baba; bẹ̃ni kò si ẹniti o mọ̀ Baba bikoṣe Ọmọ, ati ẹnikẹni ti Ọmọ fẹ fi i hàn fun.


Nitori Ọmọ-enia yio wá ninu ogo Baba rẹ̀ pẹlu awọn angẹli rẹ̀; nigbana ni yio san a fun olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀.


Jesu si wá, o si sọ fun wọn, wipe, Gbogbo agbara li ọrun ati li aiye li a fifun mi.


Gẹgẹ bi iwọ ti fun u li aṣẹ lori enia gbogbo, ki o le fi iye ainipẹkun fun gbogbo awọn ti o fifun u.


Baba fẹ Ọmọ, o si ti fi ohun gbogbo le e lọwọ.


O si fun u li aṣẹ lati mã ṣe idajọ pẹlu, nitoriti on iṣe Ọmọ-enia.


Jesu si wipe, Nitori idajọ ni mo ṣe wá si aiye yi, ki awọn ti kò riran, le riran; ati ki awọn ti o riran le di afọju.


O si paṣẹ fun wa lati wasu fun awọn enia, ati lati jẹri pe, on li a ti ọwọ Ọlọrun yàn ṣe Onidajọ ãye on okú.


Niwọnbi o ti da ọjọ kan, ninu eyi ti yio ṣe idajọ aiye li ododo, nipasẹ ọkunrin na ti o ti yàn, nigbati o ti fi ohun idaniloju fun gbogbo enia, niti o jí i dide kuro ninu okú.


Li ọjọ na nigbati Ọlọrun yio ti ipa Jesu Kristi ṣe idajọ aṣiri enia gẹgẹ bi ihinrere mi.


Nitoripe gbogbo wa kò le ṣaima fi ara hàn niwaju itẹ́ idajọ Kristi; ki olukuluku ki o le gbà nkan wọnni ti o ṣe ninu ara, gẹgẹ bi eyi ti o ti ṣe, ibã ṣe rere ibã ṣe buburu.


NITORINA mo paṣẹ fun ọ niwaju Ọlọrun, ati Kristi Jesu, ẹniti yio ṣe idajọ alãye ati okú, ati nitori ifarahàn rẹ̀ ati ijọba rẹ̀,


Awọn ẹniti yio jihin fun ẹniti o mura ati ṣe idajọ ãye on okú.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan