Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 5:2 - Bibeli Mimọ

2 Adagun omi kan si wà ni Jerusalemu, leti bodè agutan, ti a npè ni Betesda li ède Heberu, ti o ni iloro marun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Ẹnu ọ̀nà kan wà ní Jerusalẹmu tí wọn ń pè ní ẹnu ọ̀nà Aguntan. Adágún omi kan wà níbẹ̀ tí ń jẹ́ Betisata ní èdè Heberu. Adágún yìí ní ìloro marun-un tí wọn fi òrùlé bò.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Adágún omi kan sì wà ní Jerusalẹmu, létí bodè àgùntàn, tí a ń pè ní Betisaida ní èdè Heberu, tí ó ní ẹnu-ọ̀nà márùn-ún.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 5:2
14 Iomraidhean Croise  

Nwọn si rekọja oke ẹnu-bode Efraimu wá, ati lati oke ẹnu-bode lailai ati li oke ẹnu-bode ẹja, ati ile-iṣọ Hananieli, ati ile-iṣọ Mea, titi de ẹnu-bode agutan, nwọn si duro li ẹnu-bode tubu.


NIGBANA ni Eliaṣibu olori alufa dide pẹlu awọn alufa arakunrin rẹ̀, nwọn si mọ ẹnu-bode agutan; nwọn sọ ọ di mimọ́, nwọn si gbe ilẹkùn rẹ̀ duro, titi de ile-iṣọ Mea, ni nwọn sọ di mimọ́ titi de ile-iṣọ Hananeeli.


Ati larin yàra òke igun-odi titi de ẹnu-bode agutan ni awọn alagbẹdẹ wura ati awọn oniṣòwo tun ṣe.


Ẹnyin pẹlu ti wà yàra lãrin odi meji fun omi ikudu atijọ: ṣugbọn ẹnyin kò wò ẹniti o ṣe e, bẹ̃ni ẹ kò si buyìn fun ẹniti o ṣe e nigbãni,


Ẹnyin ti ri oju-iho ilu Dafidi pẹlu, pe, nwọn pọ̀: ẹnyin si gbá omi ikudu isalẹ jọ.


Nitorina nigbati Pilatu gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, o mu Jesu jade wá, o si joko lori itẹ́ idajọ ti a npè ni Okuta-titẹ, ṣugbọn li ede Heberu, Gabbata.


Nitorina nwọn mu Jesu, o si jade lọ, o rù agbelebu fun ara rẹ̀ si ibi ti a npè ni Ibi-agbari, li ede Heberu ti a npè ni Golgota:


Nitorina ọpọ awọn Ju li o kà iwe akọle yi: nitori ibi ti a gbé kàn Jesu mọ agbelebu sunmọ eti ilu: a si kọ ọ li ède Heberu, ati ti Latini, ati ti Helene.


Jesu wi fun u pe, Maria. O si yipada, o wi fun u pe, Rabboni; eyi ti o jẹ Olukọni.


Ninu wọnyi li ọ̀pọ awọn abirùn enia gbé dubulẹ si, awọn afọju, arọ ati awọn gbigbẹ, nwọn si nduro dè rirú omi.


Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Kìki iṣẹ àmi kan ni mo ṣe, ẹnu si yà gbogbo nyin.


Nigbati o si ti bùn u lãye, Paulu duro lori atẹgùn, o si juwọ́ si awọn enia. Nigbati nwọn si dakẹrọrọ o ba wọn sọrọ li ède Heberu, wipe,


O si gbá wọn jọ si ibikan ti a npè ni Har-mageddoni li ède Heberu.


Nwọn ni angẹli ọgbun na bi ọba lori wọn, orukọ rẹ̀ li ede Heberu ni Abaddoni, ati li ède Griki orukọ rẹ̀ amã jẹ Apollioni.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan