Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 5:12 - Bibeli Mimọ

12 Nigbana ni nwọn bi i lẽre wipe, Ọkunrin wo li ẹniti o wi fun ọ pe, Gbé akete rẹ, ki o si mã rìn?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

12 Wọ́n bi í pé, “Ta ni ẹni náà tí ó sọ fún ọ pé kí o ru ẹni, kí o máa rìn?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Nígbà náà ni wọ́n bi í lérè wí pé, “Ọkùnrin wo ni ẹni tí ó wí fún ọ pé gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 5:12
6 Iomraidhean Croise  

Nigbati o si de inu tẹmpili, awọn olori alufa ati awọn àgba awọn enia wá sọdọ rẹ̀ bi o ti nkọ́ awọn enia; nwọn wipe, Aṣẹ wo ni iwọ fi nṣe nkan wọnyi? tali o si fun ọ li aṣẹ yi?


O si da wọn lohùn wipe, Ẹniti o mu mi larada, on li o wi fun mi pe, Gbé akete rẹ, ki o si mã rìn.


Ẹniti a mu larada nã kò si mọ̀ ẹniti iṣe: nitori Jesu ti kuro nibẹ̀, nitori awọn enia pipọ wà nibẹ̀.


Nitori mo gbà ẹri wọn jẹ pe, nwọn ni itara fun Ọlọrun, ṣugbọn kì iṣe gẹgẹ bi ìmọ.


Nwọn si sọ fun ara wọn pe, Tali o ṣe nkan yi? Nigbati nwọn tọ̀sẹ̀, ti nwọn si bère, nwọn si wipe, Gideoni ọmọ Joaṣi li o ṣe nkan yi.


Saulu si wipe Mu gbogbo awọn àgba enia sunmọ ihinyi, ki ẹ mọ̀, ki ẹ si ri ibiti ẹ̀ṣẹ yi wà loni.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan