Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 4:9 - Bibeli Mimọ

9 Nigbana li obinrin ara Samaria na wi fun u pe, Ẽti ri ti iwọ ti iṣe Ju, fi mbère ohun mimu lọwọ mi, emi ẹniti iṣe obinrin ara Samaria? nitoriti awọn Ju ki iba awọn ara Samaria da nkan pọ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 Obinrin ará Samaria náà dá Jesu lóhùn pé, “Kí ló dé tí ìwọ tí ó jẹ́ Juu fi ń bèèrè omi lọ́wọ́ èmi tí mo jẹ́ obinrin ará Samaria?” (Gbolohun yìí jáde nítorí àwọn Juu kì í ní ohunkohun ṣe pẹlu àwọn ará Samaria.)

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Obìnrin ará Samaria náà sọ fún un pé, “Júù ni ìwọ, obìnrin ará Samaria ni èmi. Èétirí tí ìwọ ń béèrè ohun mímu lọ́wọ́ mi?” (Nítorí tí àwọn Júù kì í bá àwọn ará Samaria ṣe pọ̀.)

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 4:9
12 Iomraidhean Croise  

Awọn mejejila wọnyi ni Jesu rán lọ, o si paṣẹ fun wọn pe, Ẹ máṣe lọ si ọ̀na awọn keferi, ẹ má si ṣe wọ̀ ilu awọn ará Samaria;


Ṣugbọn ara Samaria kan, bi o ti nrè àjo, o de ibi ti o gbé wà: nigbati o si ri i, ãnu ṣe e,


Lori eyi li awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ de, ẹnu si yà wọn, pe o mba obinrin sọ̀rọ: ṣugbọn kò si ẹnikan ti o wipe, Kini iwọ nwá? tabi, Ẽṣe ti iwọ fi mba a sọ̀rọ?


Awọn Ju dahùn nwọn si wi fun u pe, Awa kò wi nitõtọ pe, ara Samaria ni iwọ iṣe, ati pe iwọ li ẹmi èṣu?


Ṣugbọn ẹnyin ó gbà agbara, nigbati Ẹmí Mimọ́ ba bà le nyin: ẹ o si ma ṣe ẹlẹri mi ni Jerusalemu, ati ni gbogbo Judea, ati ni Samaria, ati titi de opin ilẹ aiye.


O si wi fun wọn pe, Ẹnyin mọ̀ bi o ti jẹ ẽwọ̀ fun ẹniti iṣe Ju, lati ba ẹniti iṣe ara ilẹ miran kẹgbẹ, tabi lati tọ̀ ọ wá; ṣugbọn Ọlọrun ti fihàn mi pe, ki emi ki o máṣe pè ẹnikẹni li ẽwọ̀ tabi alaimọ́.


Njẹ ranṣẹ lọ si Joppa, ki o si pè Simoni wá, ẹniti apele rẹ̀ jẹ Peteru; o wọ̀ ni ile Simoni alawọ leti okun: nigbati o ba de, yio sọ̀rọ fun ọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan