Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 4:41 - Bibeli Mimọ

41 Awọn ọ̀pọlọpọ si i si gbagbọ́ nitori ọ̀rọ rẹ̀;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

41 Ọpọlọpọ àwọn mìíràn tún gbàgbọ́ nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

41 Àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì gbàgbọ́ sí i nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 4:41
13 Iomraidhean Croise  

Ọpá-alade ki yio ti ọwọ́ Judah kuro, bẹ̃li olofin ki yio kuro lãrin ẹsẹ̀ rẹ̀, titi Ṣiloh yio fi dé; on li awọn enia yio gbọ́ tirẹ̀.


Ẹnu si yà wọn si ẹkọ́ rẹ̀: nitori taṣẹ-taṣẹ li ọ̀rọ rẹ̀.


Nitorina, nigbati awọn ara Samaria wá sọdọ rẹ̀, nwọn bẹ̀ ẹ pe, ki o ba wọn joko: o si gbé ibẹ̀ ni ijọ meji.


Nwọn si wi fun obinrin na pe, Ki iṣe nitori ọrọ rẹ mọ li awa ṣe gbagbọ: nitoriti awa tikarawa ti gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀, awa si mọ̀ pe, nitõtọ eyi ni Kristi na, Olugbala araiye.


Ẹmí ni isọni di ãye; ara kò ni ère kan; ọ̀rọ wọnni ti mo sọ fun nyin, ẹmi ni, ìye si ni.


Awọn onṣẹ dahùn wipe, Kò si ẹniti o ti isọ̀rọ bi ọkunrin yi ri.


Ṣugbọn ẹnyin ó gbà agbara, nigbati Ẹmí Mimọ́ ba bà le nyin: ẹ o si ma ṣe ẹlẹri mi ni Jerusalemu, ati ni gbogbo Judea, ati ni Samaria, ati titi de opin ilẹ aiye.


Nitorina nigbati ijọ si sìn wọn de ọna, nwọn là Fenike on Samaria kọja, nwọn nròhin iyipada awọn Keferi: nwọn si fi ayọ̀ nla fun gbogbo awọn arakunrin.


Ṣugbọn nigbati nwọn gbà Filippi gbọ́ ẹniti nwasu ihinrere ti ijọba Ọlọrun, ati orukọ Jesu Kristi, a baptisi wọn, ati ọkunrin ati obinrin.


Ati awọn nigbati nwọn si ti jẹri, ti nwọn si ti sọ ọrọ Oluwa, nwọn pada lọ si Jerusalemu, nwọn si wasu ihinrere ni iletò pipọ ti awọn ara Samaria.


Kò si si ẹda kan ti kò farahan niwaju rẹ̀, ṣugbọn ohun gbogbo ni o wà nihoho ti a si ṣipaya fun oju rẹ̀ ẹniti awa ni iba lo.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan