Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 4:36 - Bibeli Mimọ

36 Ẹniti nkorè ngba owo ọ̀ya, o si nkó eso jọ si ìye ainipẹkun: ki ẹniti o nfunrugbin ati ẹniti nkore le jọ mã yọ̀ pọ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

36 Ẹni tí ń kórè a máa rí èrè gbà, ó ń kó irè jọ sí ìyè ainipẹkun, kí inú ẹni tí ń fúnrúgbìn ati ti ẹni tí ń kórè lè jọ máa dùn pọ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

36 Kódà báyìí, ẹni tí ó ń kórè ń gba owó ọ̀yà rẹ̀, ó si ń kó èso jọ sí ìyè àìnípẹ̀kun: kí ẹni tí ó ń fúnrúgbìn àti ẹni tí ń kórè lè jọ máa yọ̀ pọ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 4:36
20 Iomraidhean Croise  

Enia buburu nṣiṣẹ ère-ẹ̀tan; ṣugbọn ẹniti ngbin ododo ni ère otitọ wà fun.


Eso ododo ni igi ìye; ẹniti o ba si yi ọkàn enia pada, ọlọgbọ́n ni.


Awọn ọlọgbọ́n yio si ma tàn bi imọlẹ ofurufu: awọn ti o si nyi ọ̀pọlọpọ pada si ododo yio si ma tàn bi irawọ̀ lai ati lailai.


Ati gbogbo ẹniti o fi ile silẹ, tabi arakunrin, tabi arabinrin, tabi baba, tabi iya, tabi aya, tabi ọmọ, tabi ilẹ, nitori orukọ mi, nwọn o ri ọ̀rọrun gbà, nwọn o si jogún ìye ainipẹkun.


Ẹniti o ba gbà Ọmọ gbọ́, o ni iye ainipẹkun: ẹniti kò ba si gbà Ọmọ gbọ, kì yio ri ìye; ṣugbọn ibinu Ọlọrun mbẹ lori rẹ̀.


Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba mu ninu omi ti emi o fifun u, orùngbẹ kì yio gbẹ ẹ mọ́ lai; ṣugbọn omi ti emi o fifun u yio di kanga omi ninu rẹ̀, ti yio ma sun si ìye ainipẹkun.


Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba gbọ́ ọ̀rọ mi, ti o ba si gbà ẹniti o rán mi gbọ́, o ni iye ti kò nipẹkun, on kì yio si wá si idajọ; ṣugbọn o ti ré ikú kọja bọ si ìye.


Ará, emi kò si fẹ ki ẹnyin ki o ṣe alaimọ̀ pe, nigba-pupọ li emi npinnu rẹ̀ lati tọ̀ nyin wá (ṣugbọn o di ẹtì fun mi di isisiyi,) ki emi ki o le ni eso diẹ ninu nyin pẹlu, gẹgẹ bi lãrin awọn Keferi iyokù.


Fun awọn ti nfi sũru ni rere-iṣe wá ogo ati ọlá ati aidibajẹ, ìye ainipẹkun;


Ṣugbọn nisisiyi ti a sọ nyin di omnira kuro ninu ẹ̀ṣẹ, ti ẹnyin si di ẹrú Ọlọrun, ẹnyin ni eso nyin si ìwa mimọ́, ati opin rẹ̀ ìye ainipẹkun.


Nitori ikú li ère ẹ̀ṣẹ; ṣugbọn ẹ̀bun ọfẹ Ọlọrun ni ìye ti kò nipẹkun, ninu Kristi Jesu Oluwa wa.


Nitoripe bi mo ba nṣe nkan yi tinutinu mi, mo li ère kan: ṣugbọn bi kò ba ṣe tinutinu mi, a ti fi iṣẹ iriju le mi lọwọ.


Njẹ kini ha li ère mi? pe, nigbati mo ba nwasu ihinrere Kristi fun-ni laini inawo, ki emi ki o máṣe lo agbara mi ninu ihinrere ni kikun.


Nitori kini ireti wa, tabi ayọ̀ wa, tabi ade iṣogo wa? kì ha iṣe ẹnyin ni niwaju Jesu Oluwa wa ni àbọ rẹ̀?


Mã ṣe itọju ara rẹ ati ẹkọ́ rẹ; mã duro laiyẹsẹ ninu nkan wọnyi: nitori ni ṣiṣe eyi, iwọ ó gbà ara rẹ ati awọn ti ngbọ́ ọ̀rọ rẹ là.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan