Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 4:31 - Bibeli Mimọ

31 Lãrin eyi awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nrọ̀ ọ, wipe, Rabbi, jẹun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

31 Lẹ́yìn tí obinrin náà ti lọ sí ààrin ìlú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ń bẹ̀ ẹ́ pé, “Rabi, jẹun.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

31 Láàrín èyí, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń rọ̀ ọ́ wí pé, “Rabbi, jẹun.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 4:31
18 Iomraidhean Croise  

A si gbé onjẹ kalẹ fun u lati jẹ: ṣugbọn on si wipe, Emi ki yio jẹun titi emi o fi jiṣẹ mi tán. On si wipe, Ma wi.


Ati ikíni li ọjà, ati ki awọn enia mã pè wọn pe, Rabbi, Rabbi.


Ṣugbọn ki a máṣe pè ẹnyin ni Rabbi: nitoripe ẹnikan ni Olukọ nyin, ani Kristi; ará si ni gbogbo nyin.


Nigbana ni Judasi, ti o fi i hàn, dahùn wipe, Rabbi, emi ni bi? O si wi fun u pe, Iwọ wi i.


Lojukanna o wá sọdọ Jesu, o si wipe, Alafia, Olukọni; o si fi ẹnu ko o li ẹnu.


Peteru si wa iranti o wi fun u pe, Rabbi, wò bi igi ọpọtọ ti iwọ fi bú ti gbẹ.


Nigbati o de, o tọ̀ ọ lọ gan, o wipe, Olukọni, olukọni! o si fi ẹnu kò o li ẹnu.


Peteru si dahùn o si wi fun Jesu pe, Olukọni, o dara fun wa lati ma gbé ihinyi: si jẹ ki a pa agọ́ mẹta, ọkan fun ọ, ati ọkan fun Mose, ati ọkan fun Elijah.


Nigbana ni Jesu yipada, o ri nwọn ntọ̀ on lẹhin, o si wi fun wọn pe, Kili ẹnyin nwá? Nwọn wi fun u pe, Rabbi, (itumọ̀ eyi ti ijẹ Olukọni,) nibo ni iwọ ngbé?


Natanaeli dahùn, o si wi fun u pe, Rabbi, iwọ li Ọmọ Ọlọrun; iwọ li Ọba Israeli.


Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si wi fun u pe, Rabbi, ni lọ̃lọ̃ yi li awọn Ju nwá ọ̀na ati sọ ọ li okuta; iwọ si ntún pada lọ sibẹ̀?


On na li o tọ̀ Jesu wá li oru, o si wi fun u pe, Rabbi, awa mọ̀ pe olukọni lati ọdọ Ọlọrun wá ni iwọ iṣe: nitoripe kò si ẹniti o le ṣe iṣẹ àmi wọnyi ti iwọ nṣe, bikoṣepe Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀.


Nwọn si tọ̀ Johanu wá, nwọn si wi fun u pe, Rabbi, ẹniti o ti wà pẹlu rẹ loke odò Jordani, ti iwọ ti jẹrí rẹ̀, wo o, on mbaptisi, gbogbo enia si ntọ̀ ọ̀ wá.


Nigbana ni nwọn ti ilu jade, nwọn si tọ̀ ọ wá.


Ṣugbọn o wi fun wọn pe, Emi li onjẹ lati jẹ, ti ẹnyin kò mọ̀.


Nigbati nwọn si ri i li apakeji okun nwọn wi fun u pe, Rabbi, nigbawo ni iwọ wá sihinyi?


Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si bi i lẽre, wipe. Olukọni, tani dẹṣẹ, ọkunrin yi tabi awọn obi rẹ̀, ti a fi bi i li afọju?


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan