Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 4:23 - Bibeli Mimọ

23 Ṣugbọn wakati mbọ̀, o si de tan nisisiyi, nigbati awọn olusin tõtọ yio ma sìn Baba li ẹmí ati li otitọ: nitori irú wọn ni Baba nwá ki o ma sìn on.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

23 Ṣugbọn àkókò ń bọ̀, ó tilẹ̀ dé tán báyìí, nígbà tí àwọn tí ń jọ́sìn tòótọ́ yóo máa sin Baba ní ẹ̀mí ati ní òtítọ́, nítorí irú àwọn bẹ́ẹ̀ ni Baba ń wá kí wọ́n máa sin òun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

23 Ṣùgbọ́n àkókò ń bọ̀, ó sì dé tán nísinsin yìí, nígbà tí àwọn olùsìn tòótọ́ yóò máa sin Baba ní Ẹ̀mí àti ní òtítọ́: nítorí irú wọn ni Baba ń wá kí ó máa sin òun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 4:23
39 Iomraidhean Croise  

Emi mọ̀ pẹlu, Ọlọrun mi, pe iwọ ndan ọkàn wò, iwọ si ni inudidún si ododo. Bi o ṣe ti emi, ninu ododo ọkàn mi li emi ti fi tinutinu ṣe iranlọwọ gbogbo nkan wọnyi; ati nisisiyi pẹlu ayọ̀ ni mo ti ri awọn enia rẹ ti o wá nihin, lati fi tinutinu ṣe iranlọwọ fun ọ.


Oluwa nṣe inudidùn si awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, si awọn ti nṣe ireti ãnu rẹ̀.


GBỌ́ otiọ́, Oluwa, fiyesi igbe mi, fi eti si adura mi, ti kò ti ète ẹ̀tan jade.


Ibukún ni fun ọkunrin na ẹniti Oluwa kò kà ẹ̀ṣẹ si lọrun, ati ninu ẹmi ẹniti ẹ̀tan kò si.


Kiyesi i, iwọ fẹ otitọ ni inu: ati niha ìkọkọ ni iwọ o mu mi mọ̀ ọgbọ́n.


Ẹbọ awọn enia buburu, irira ni loju Oluwa; ṣugbọn adura awọn aduroṣinṣin ni didùn-inu rẹ̀.


Adaba mi, ti o wà ninu pàlapala okuta, ni ibi ìkọkọ okuta, jẹ ki emi ri oju rẹ, jẹ ki emi gbọ́ ohùn rẹ; nitori didùn ni ohùn rẹ, oju rẹ si li ẹwà.


Yio si ṣe li ọjọ na, iyokù Israeli, ati iru awọn ti o salà ni ile Jakobu, ki yio tun duro tì ẹniti o lù wọn mọ; ṣugbọn nwọn o duro tì Oluwa, Ẹni-Mimọ Israeli, li otitọ.


Nitorina Oluwa wipe, Niwọ̀n bi awọn enia yi ti nfi ẹnu wọn fà mọ mi, ti nwọn si nfi etè wọn yìn mi, ṣugbọn ti ọkàn wọn jìna si mi, ti nwọn si bẹru mi nipa ilana enia ti a kọ́ wọn.


Awọn enia yi ni mo ti mọ fun ara mi; nwọn o fi iyìn mi hàn.


Ṣugbọn nwọn nwá mi lojojumọ, nwọn si ni inu didun lati mọ̀ ọ̀na mi, bi orilẹ-ède ti nṣe ododo, ti kò si fi ilàna Ọlọrun wọn silẹ: nwọn mbere ilàna ododo wọnnì lọwọ mi; nwọn a ma ṣe inu didun ati sunmọ Ọlọrun.


Lẹhin gbogbo wọnyi, sibẹ Juda, alarekereke arabinrin rẹ̀, kò yipada si mi tọkàntọkàn ṣugbọn li agabagebe; li Oluwa wi.


Iwọ o si bura pe, Oluwa mbẹ ni otitọ, ni idajọ, ati ni ododo; ati nipasẹ rẹ̀ ni gbogbo orilẹ-ède yio fi ibukun fun ara wọn, nwọn o si ṣe ogo ninu rẹ̀.


Emi si wá ẹnikan lãrin wọn, ti ibá tun odi na mọ, ti ibá duro ni ibiti o ya na niwaju mi fun ilẹ na, ki emi má bà parun: ṣugbọn emi kò ri ẹnikan.


Nitoripe nipasẹ Mose li a ti fi ofin funni, ṣugbọn ore-ọfẹ ati otitọ tipasẹ Jesu Kristi wá.


Jesu si da wọn lohùn wipe, Wakati na de, ti a o ṣe Ọmọ-enia logo.


Nwọn o yọ nyin kuro ninu sinagogu: ani, akokò mbọ̀, ti ẹnikẹni ti o ba pa nyin, yio rò pe on nṣe ìsin fun Ọlọrun.


Kiyesi i, wakati mbọ̀, ani o de tan nisisiyi, ti a o fọ́n nyin ká kiri, olukuluku si ile rẹ̀; ẹ ó si fi emi nikan silẹ: ṣugbọn kì yio si ṣe emi nikan, nitoriti Baba mbẹ pẹlu mi.


Jesu wi fun u pe, Gbà mi gbọ́, obinrin yi, wakati na mbọ̀, nigbati kì yio ṣe lori òke yi, tabi Jerusalemu, li ẹnyin o ma sìn Baba.


Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Wakati na mbọ̀, o si de tan nisisiyi, nigbati awọn okú yio gbọ́ ohùn Ọmọ Ọlọrun: awọn ti o ba gbọ yio si yè.


Ki eyi ki o máṣe yà nyin li ẹnu; nitoripe wakati mbọ̀, ninu eyiti gbogbo awọn ti o wà ni isà okú yio gbọ́ ohùn rẹ̀.


Ọlọrun sá li ẹlẹri mi, ẹniti emi nfi ẹmi mi sìn ninu ihinrere Ọmọ rẹ̀, biotiṣepe li aisimi li emi nranti nyin nigbagbogbo ninu adura mi;


Nitori ẹnyin kò tun gbà ẹmí ẹrú lati mã bẹ̀ru mọ́: ṣugbọn ẹnyin ti gbà ẹmí isọdọmọ, nipa eyi ti awa fi nke pé, Abba, Baba.


Bẹ̃ gẹgẹ li Ẹmí pẹlu si nràn ailera wa lọwọ: nitori a kò mọ̀ bi ã ti igbadura gẹgẹ bi o ti yẹ: ṣugbọn Ẹmí tikararẹ̀ nfi irora ti a kò le fi ẹnu sọ bẹ̀bẹ fun wa.


Ati nitoriti ẹnyin nṣe ọmọ, Ọlọrun si ti rán Ẹmí Ọmọ rẹ̀ wá sinu ọkàn nyin, ti nke pe, Abba, Baba.


Pẹlu gbogbo adura ati ẹbẹ ni ki ẹ mã gbadura nigbagbogbo ninu Ẹmí, ki ẹ si mã ṣọra si i ninu iduroṣinṣin gbogbo, ati ẹ̀bẹ fun gbogbo enia mimọ́;


Nitori awa ni onilà, ti nsìn Ọlọrun nipa ti Ẹmí, awa si nṣogo ninu Kristi Jesu, awa kò si ni igbẹkẹle ninu ẹran-ara;


Njẹ nitorina ẹ bẹ̀ru OLUWA, ki ẹ si ma sìn i li ododo ati li otitọ: ki ẹ si mu oriṣa wọnni kuro ti awọn baba nyin sìn ni ìha keji Odò nì, ati ni Egipti; ki ẹ si ma sìn OLUWA.


Ṣugbọn ẹnyin ni iran ti a yàn, olu-alufa, orilẹ-ède mimọ́, enia ọ̀tọ; ki ẹnyin ki o le fi ọla nla ẹniti o pè nyin jade kuro ninu òkunkun sinu imọlẹ iyanu rẹ̀ hàn:


Ṣugbọn ẹ bẹ̀ru Oluwa, ki ẹ si fi gbogbo ọkàn nyin sin i lododo: njẹ, ẹ ronu ohun nlanla ti o ṣe fun nyin.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan