Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 4:20 - Bibeli Mimọ

20 Awọn baba wa sìn lori òke yi; ẹnyin si wipe, Jerusalemu ni ibi ti o yẹ ti a ba ma sìn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

20 Ní orí òkè tí ó wà lọ́hùn-ún yìí ni àwọn baba wa ń sin Ọlọrun, ṣugbọn ẹ̀yin wí pé Jerusalẹmu ni ibi tí a níláti máa sìn ín.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

20 Àwọn baba wa sìn lórí òkè yìí; ẹ̀yin sì wí pé, Jerusalẹmu ni ibi tí ó yẹ tí à bá ti máa sìn.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 4:20
20 Iomraidhean Croise  

Oluwa si wi fun u pe, Mo ti gbọ́ adura rẹ ati ẹ̀bẹ rẹ, ti iwọ ti bẹ̀ niwaju mi, mo ti ya ile yi si mimọ́, ti iwọ ti kọ́, lati fi orukọ mi sibẹ titi lai; ati oju mi ati ọkàn mi yio wà nibẹ titi lai.


Dafidi si tẹ pẹpẹ kan nibẹ fun Oluwa, o si ru ẹbọ ọrẹ-sisun ati ẹbọ ọpẹ, o si kepe Oluwa; on si fi iná da a li ohùn lati ọrun wá lori pẹpẹ ẹbọ-ọrẹ sisun na.


NIGBANA ni Dafidi wipe, Eyi ni ile Oluwa Ọlọrun, eyi si ni pẹpẹ ọrẹ-sisun fun Israeli.


Ṣugbọn emi ti yàn Jerusalemu, ki orukọ mi ki o le wà nibẹ; mo si ti yàn Dafidi lati wà lori Israeli, enia mi.


Oluwa si fi ara hàn Solomoni li oru, o si wi fun u pe, Emi ti gbọ́ adura rẹ, emi si ti yàn ihinyi fun ara mi, fun ile ẹbọ.


Njẹ nisisiyi emi ti yàn, emi si ti yà ile yi si mimọ́, ki orukọ mi ki o le ma wà nibẹ lailai: ati oju mi ati ọkàn mi yio ma wà nibẹ nigbagbogbo.


Nitori ti Oluwa ti yàn Sioni; o ti fẹ ẹ fun ibujoko rẹ̀.


Ṣugbọn o yan ẹ̀ya Juda, òke Sioni ti o fẹ.


BAYI ni Oluwa wi, pe, Ọrun ni itẹ́ mi, aiye si ni apoti itisẹ̀ mi: nibo ni ile ti ẹ kọ́ fun mi gbé wà? ati nibo ni isimi mi gbe wà?


Nwọn kò si gbà a, nitoriti oju rẹ̀ dabi ẹnipe o nlọ si Jerusalemu.


Iwọ pọ̀ju Jakọbu baba wa lọ bí, ẹniti o fun wa ni kanga na, ti on tikararẹ̀ mu ninu rẹ̀, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn ẹran rẹ̀?


Yio si ṣe, nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba mú ọ dé ilẹ na, nibiti iwọ nlọ lati gbà a, ki iwọ ki o ma sure lori òke Gerisimu, ki iwọ ki o si ma gegun lori òke Ebali.


Awọn wọnyi ni ki o duro lori òke Gerisimu, lati ma sure fun awọn enia na, nigbati ẹnyin ba gòke Jordani; Simeoni, ati Lefi, ati Juda, ati Issakari, ati Josefu, ati Benjamini:


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan