Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 4:19 - Bibeli Mimọ

19 Obinrin na wi fun u pe, Ọgbẹni, mo woye pe, woli ni iwọ iṣe.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

19 Obinrin náà sọ fún un pé, “Alàgbà, mo wòye pé wolii ni ọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

19 Obìnrin náà wí fún un pé, “Alàgbà, mo wòye pé, wòlíì ni ìwọ ń ṣe.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 4:19
14 Iomraidhean Croise  

On si wi fun u pe, Ọkàn mi kò ha ba ọ lọ, nigbati ọkunrin na fi yipada kuro ninu kẹkẹ́ rẹ̀ lati pade rẹ? Eyi ha iṣe akokò ati gbà fadakà, ati lati gbà aṣọ, ati ọgbà-olifi ati ọgbà-ajara, ati àgutan, ati malu, ati iranṣékunrin ati iranṣẹbinrin?


Ọkan ninu awọn iranṣẹ rẹ̀ si wipe, Kò si ẹnikan, oluwa mi, ọba; bikoṣe Eliṣa, woli ti mbẹ ni Israeli, ni nsọ fun ọba Israeli gbogbo ọ̀rọ ti iwọ nsọ ninu iyẹ̀wu rẹ.


Ijọ enia si wipe, Eyi ni Jesu wolĩ, lati Nasareti ti Galili.


O si bi wọn pe, Kini? Nwọn si wi fun u pe, Niti Jesu ti Nasareti, ẹniti iṣe woli, ti o pọ̀ ni iṣẹ ati li ọ̀rọ niwaju Ọlọrun ati gbogbo enia:


Ẹ̀rù si ba gbogbo wọn: nwọn si nyìn Ọlọrun logo, wipe, Woli nla dide ninu wa; ati pe, Ọlọrun si wa ibẹ̀ awọn enia rẹ̀ wò.


Nigbati Farisi ti o pè e si ri i, o wi ninu ara rẹ̀ pe, ọkunrin yi iba ṣe woli, iba mọ̀ ẹni ati irú ẹniti obinrin yi iṣe ti nfi ọwọ́ kan a: nitori ẹlẹṣẹ ni.


Nitoriti iwọ ti li ọkọ marun ri; ẹniti iwọ si ni nisisiyi kì iṣe ọkọ rẹ; iwọ sọ otitọ li eyini.


Ẹ wá wò ọkunrin kan, ẹniti o sọ ohun gbogbo ti mo ti ṣe ri fun mi: eyi ha le jẹ Kristi na?


Nitorina nigbati awọn ọkunrin na ri iṣẹ àmi ti Jesu ṣe, nwọn wipe, Lõtọ eyi ni woli na ti mbọ̀ wá aiye.


Nitorina nigbati ọ̀pọ ninu ijọ enia gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, nwọn wipe, Lotọ eyi ni woli na.


Nitorina nwọn si tun wi fun afọju na pe, Kini iwọ wi nitori rẹ̀, nitoriti o là ọ loju? O si wipe, Woli ni iṣe.


OLUWA Ọlọrun rẹ yio gbé wolĩ kan dide fun ọ lãrin rẹ, ninu awọn arakunrin rẹ, bi emi; on ni ki ẹnyin ki o fetisi;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan