Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 4:18 - Bibeli Mimọ

18 Nitoriti iwọ ti li ọkọ marun ri; ẹniti iwọ si ni nisisiyi kì iṣe ọkọ rẹ; iwọ sọ otitọ li eyini.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

18 nítorí o ti ní ọkọ marun-un rí, ẹni tí o wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nisinsinyii kì í sì í ṣe ọkọ rẹ. Òtítọ́ ni o sọ.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

18 Nítorí tí ìwọ ti ní ọkọ márùn-ún rí; ọkùnrin tí ìwọ sì ní báyìí kì í ṣe ọkọ rẹ. Ohun tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí, òtítọ́ ni.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 4:18
16 Iomraidhean Croise  

Ṣugbọn Ọlọrun tọ̀ Abimeleki wá li ojuran li oru, o si wi fun u pe, kiyesi i, okú ni iwọ, nitori obinrin ti iwọ mu nì; nitori aya ọkunrin kan ni iṣe.


Nigbati Ṣekemu, ọmọ Hamori, ara Hiffi, ọmọ alade ilu na ri i, o mú u, o si wọle tọ̀ ọ, o si bà a jẹ́.


Nwọn si wipe, Ki on ki o ha ṣe si arabinrin wa bi ẹnipe si panṣaga?


Nitõtọ gẹgẹ bi aya ti ifi arekereke lọ kuro lọdọ ọkọ rẹ̀, bẹ̃ni ẹnyin ti hùwa arekereke si mi, iwọ ile Israeli: li Oluwa wi.


Ṣugbọn gẹgẹ bi aya ti o ṣe panṣaga, ti o gbà alejo dipo ọkọ rẹ̀!


Nitorina, iwọ panṣaga, gbọ́ ọ̀rọ Oluwa:


Eyi li ofin owú, nigbati obinrin kan ba yapa, labẹ ọkọ rẹ̀, ti o si di ẹni ibàjẹ́;


Bi obinrin kan ba si fi ọkọ rẹ̀ silẹ, ti a ba si gbé e ni iyawo fun ẹlomiran, o ṣe panṣaga.


Jesu wi fun u pe, Lọ ipè ọkọ rẹ, ki o si wá si ihinyi.


Obinrin na dahùn, o si wi fun u pe, Emi kò li ọkọ. Jesu wi fun u pe, Iwọ wi rere pe, emi kò li ọkọ:


Obinrin na wi fun u pe, Ọgbẹni, mo woye pe, woli ni iwọ iṣe.


Njẹ bi o ba ni ọkọ miran nigbati ọkọ rẹ̀ wà lãye, panṣaga li a o pè e: ṣugbọn bi ọkọ rẹ̀ ba kú, o bọ lọwọ ofin na; ki yio si jẹ panṣaga bi o ba ni ọkọ miran.


Ki igbéyawo ki o li ọla larin gbogbo enia, ki akete si jẹ alailẽri: nitori awọn àgbere ati awọn panṣaga li Ọlọrun yio dá lẹjọ.


Pẹlupẹlu Rutu ara Moabu, aya Maloni ni mo rà li aya mi, lati gbé orukọ okú dide lori ilẹ-iní rẹ̀, ki orukọ okú ki o má ba run ninu awọn arakunrin rẹ̀, ati li ẹnu-bode ilu rẹ̀: ẹnyin li ẹlẹri li oni.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan