Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 4:10 - Bibeli Mimọ

10 Jesu dahùn, o si wi fun u pe, Ibaṣepe iwọ mọ̀ ẹ̀bun Ọlọrun, ati ẹniti o wi fun ọ pe, Fun mi mu, iwọ iba si ti bère lọwọ rẹ̀, on iba ti fi omi ìye fun ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

10 Jesu dá a lóhùn pé, “Bí ó bá jẹ́ pé o mọ ẹ̀bùn Ọlọrun ati ẹni tí ó wí fún ọ pé, ‘Fún mi ní omi mu,’ Ìwọ ìbá bèèrè omi ìyè lọ́wọ́ rẹ̀, òun ìbá sì fún ọ.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Jesu dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ìbá ṣe pé ìwọ mọ ẹ̀bùn Ọlọ́run, àti ẹni tí ó wí fún ọ pé, Fún mi ni omi mu, ìwọ ìbá sì ti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, òun ìbá ti fi omi ìyè fún ọ.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 4:10
49 Iomraidhean Croise  

Oluwa, iwọ ti gbọ́ ifẹ onirẹlẹ: iwọ o mu ọkàn wọn duro, iwọ o dẹ eti rẹ si i.


Odò nla kan wà, ṣiṣan eyiti yio mu inu ilu Ọlọrun dùn, ibi mimọ́ agọ wọnni ti Ọga-ogo.


Kiyesi i, emi o duro niwaju rẹ nibẹ̀ lori okuta ni Horebu; iwọ o si lù okuta na, omi yio si jade ninu rẹ̀, ki awọn enia ki o le mu. Mose si ṣe bẹ̃ li oju awọn àgbagba Israeli.


Orisun ninu ọgba kanga omi iyè, ti nṣan lati Lebanoni wá.


Ẹnyin o si fi ayọ̀ fà omi jade lati inu kanga igbala wá.


Nigbana li awọn arọ yio fò bi agbọ̀nrin, ati ahọ́n odi yio kọrin: nitori omi yio tú jade li aginju, ati iṣàn omi ni ijù.


Emi Oluwa li o ti pè ọ ninu ododo, emi o si di ọwọ́ rẹ mu, emi o si pa ọ mọ, emi o si fi ọ ṣe majẹmu awọn enia, imọlẹ awọn keferi.


Awọn ẹran igbẹ yio yìn mi logo, awọn dragoni ati awọn owiwi; nitori emi o funni li omi li aginjù, ati odo ni aṣalẹ̀, lati fi ohun mimu fun awọn enia mi, ayanfẹ mi;


Nitori emi o dà omi lu ẹniti ongbẹ ngbẹ, ati iṣàn-omi si ilẹ gbigbẹ: emi o dà ẹmi mi si iru rẹ, ati ibukun mi si iru-ọmọ rẹ.


Ebi kì yio pa wọn, bẹ̃ni ongbẹ kì yio si gbẹ wọn; õru kì yio mu wọn, bẹ̃ni õrùn kì yio si pa wọn: nitori ẹniti o ti ṣãnu fun wọn yio tọ́ wọn, ani nihà isun omi ni yio dà wọn.


Nitori a bi ọmọ kan fun wa, a fi ọmọkunrin kan fun wa: ijọba yio si wà li ejika rẹ̀: a o si ma pe orukọ rẹ̀ ni Iyanu, Oludamọ̀ran, Ọlọrun Alagbara, Baba Aiyeraiye, Ọmọ-Alade Alafia.


Nitori awọn enia mi ṣe ibi meji: nwọn fi Emi, isun omi-ìye silẹ, nwọn si wà kanga omi fun ara wọn, kanga fifọ́ ti kò le da omi duro.


Nitorina, iwọ panṣaga, gbọ́ ọ̀rọ Oluwa:


LI ọjọ na isun kan yio ṣi silẹ fun ile Dafidi ati fun awọn ara Jerusalemu, fun ẹ̀ṣẹ ati fun ìwa aimọ́.


Yio si ṣe li ọjọ na, omi iyè yio ti Jerusalemu ṣàn lọ; idajì wọn sihà kun ilà-õrun, ati idajì wọn sihà okun ẹhìn: nigbà ẹ̀run ati nigbà otutù ni yio ri bẹ̃.


Njẹ bi ẹnyin ti iṣe enia buburu ba mọ̀ bi ãti ifi ẹ̀bun didara fun awọn ọmọ nyin: melomelo ni Baba nyin ti mbẹ li ọrun yio fi Ẹmí Mimọ́ rẹ̀ fun awọn ti o mbère lọdọ rẹ̀?


Nkan wọnyi ni nwọn o si ṣe, nitoriti nwọn kò mọ̀ Baba, nwọn kò si mọ̀ mi.


Iye ainipẹkun na si li eyi, ki nwọn ki o le mọ̀ ọ, iwọ nikan Ọlọrun otitọ, ati Jesu Kristi, ẹniti iwọ rán.


Nitori Ọlọrun fẹ araiye tobẹ̃ gẹ, ti o fi Ọmọ bíbi rẹ̀ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ́ má bà ṣegbé, ṣugbọn ki o le ni ìye ainipẹkun.


Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba mu ninu omi ti emi o fifun u, orùngbẹ kì yio gbẹ ẹ mọ́ lai; ṣugbọn omi ti emi o fifun u yio di kanga omi ninu rẹ̀, ti yio ma sun si ìye ainipẹkun.


Jesu wi fun wọn pe, Emi li onjẹ ìye: ẹnikẹni ti o ba tọ̀ mi wá, ebi kì yio pa a; ẹniti o ba si gbà mi gbọ́, orungbẹ kì yio gbẹ ẹ mọ́ lai.


Emi ni onjẹ ìye nì ti o ti ọrun sọkalẹ wá: bi ẹnikẹni ba jẹ ninu onjẹ yi, yio yè titi lailai: onjẹ na ti emi o si fifunni li ara mi, fun ìye araiye.


Oluwa si wi fun u pe, Dide, ki o si lọ si ita ti a npè ni Ọgãnran, ki o si bère ẹniti a npè ni Saulu, ara Tarsu, ni ile Juda: sá wo o, o ngbadura.


Ẹniti kò da Ọmọ on tikararẹ̀ si, ṣugbọn ti o jọwọ rẹ̀ lọwọ fun gbogbo wa, yio ha ti ṣe ti kì yio fun wa li ohun gbogbo pẹlu rẹ̀ lọfẹ?


Ṣugbọn nipasẹ rẹ̀ li ẹnyin wà ninu Kristi Jesu, ẹniti Ọlọrun fi ṣe ọgbọ́n, ati ododo, ati isọdimimọ́, ati idande fun wa:


Ti gbogbo wọn si mu ohun mimu ẹmí kanna: nitoripe nwọn nmu ninu Apata ẹmí ti ntọ̀ wọn lẹhin: Kristi si li Apata na.


Ọpẹ́ ni fun Ọlọrun nitori alailesọ ẹ̀bun rẹ̀.


Nitori ore-ọfẹ li a ti fi gbà nyin là nipa igbagbọ́; ati eyini kì iṣe ti ẹnyin tikaranyin: ẹ̀bun Ọlọrun ni:


Nitori awọn ti a ti là loju lẹ̃kan, ti nwọn si ti tọ́ ẹ̀bùn ọ̀run wò, ti nwọn si ti di alabapin Ẹmí Mimọ́,


Awa si mọ̀ pe Ọmọ Ọlọrun de, o si ti fi òye fun wa, ki awa ki o le mọ̀ ẹniti iṣe otitọ, awa si mbẹ ninu ẹniti iṣe otitọ, ani ninu Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi. Eyi li Ọlọrun otitọ, ati ìye ainipẹkun.


O si wi fun mi pe, O pari. Emi ni Alfa ati Omega, ipilẹṣẹ ati opin. Emi ó si fi omi fun ẹniti ongbẹ ngbẹ lati orisun omi ìye lọfẹ̃.


Ati Ẹmí ati iyawo wipe, Mã bọ̀. Ati ẹniti o ngbọ́ ki o wipe, Mã bọ̀. Ati ẹniti ongbẹ ngbẹ ki o wá. Ẹnikẹni ti o ba si fẹ, ki o gbà omi ìye na lọfẹ.


Nitori Ọdọ-Agutan ti mbẹ li arin itẹ́ na ni yio mã ṣe oluṣọ-agutan wọn, ti yio si mã ṣe amọna wọn si ibi orisun omi iyè: Ọlọrun yio si nù omije gbogbo nù kuro li oju wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan