Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 3:34 - Bibeli Mimọ

34 Nitori ẹniti Ọlọrun ti rán nsọ ọ̀rọ Ọlọrun: nitoriti Ọlọrun kò fi Ẹmí fun u nipa oṣuwọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

34 Nítorí pé ẹni tí Ọlọrun rán wá ń sọ ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Nítorí pé Ọlọrun fún un ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ẹ̀mí rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

34 Nítorí ẹni tí Ọlọ́run ti rán ń sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: nítorí tí Ọlọ́run fi Ẹ̀mí fún un láìsí gbèdéke.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 3:34
29 Iomraidhean Croise  

O si ṣe, nigbati nwọn kọja tan, ni Elijah wi fun Eliṣa pe, Bère ohun ti emi o ṣe fun ọ, ki a to gbà mi kuro lọwọ rẹ. Eliṣa si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ìlọ́po meji ẹmi rẹ ki o bà le mi.


Iwọ fẹ ododo, iwọ korira ìwa-buburu: nitori na li Ọlọrun, Ọlọrun rẹ, ṣe fi àmi ororo ayọ̀ yà ọ ṣolori awọn ọ̀gba rẹ.


Niti emi, eyi ni majẹmu mi pẹlu wọn, ni Oluwa wi; Ẹmi mi ti o wà lara rẹ̀, ati ọ̀rọ mi ti mo fi si ẹnu rẹ, kì yio kuro li ẹnu rẹ, tabi kuro lẹnu iru-ọmọ rẹ, tabi kuro lẹnu iru-ọmọ ọmọ rẹ, ni Oluwa wi, lati isisiyi lọ ati lailai.


Eyi ni ipín Aaroni, ati ìpín awọn ọmọ rẹ̀, ninu ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe, li ọjọ́ na ti o mú wọn wá lati ṣe alufa OLUWA;


OLUWA si sọkalẹ wá ninu awọsanma, o si bá a sọ̀rọ, o si mú ninu ẹmi ti o wà lara rẹ̀, o si fi i sara awọn ãdọrin àgba na: o si ṣe, nigbati ẹmi na bà lé wọn, nwọn sì sọtẹlẹ ṣugbọn nwọn kò ṣe bẹ̃ mọ́.


Wo iranṣẹ mi, ẹniti mo yàn; ayanfẹ mi, ẹniti inu mi dùn si gidigidi: Emi o fi ẹmí mi fun u, yio si fi idajọ hàn fun awọn keferi.


Ẹmi Oluwa mbẹ lara mi, nitoriti o fi àmi oróro yàn mi lati wasu ihinrere fun awọn òtoṣi; o ti rán mi wá lati ṣe iwosan awọn ọkàn onirobinujẹ, lati wasu idasilẹ fun awọn igbekun, itunriran fun awọn afọju, ati lati jọwọ awọn ti a pa lara lọwọ.


Nitori ninu ẹkún rẹ̀ ni gbogbo wa si ti gbà, ati ore-ọfẹ kún ore-ọfẹ.


Ṣugbọn nigbati Olutunu na ba de, ẹniti emi ó rán si nyin lati ọdọ Baba wá, ani Ẹmi otitọ nì, ti nti ọdọ Baba wá, on na ni yio jẹri mi:


Ṣugbọn otitọ li emi nsọ fun nyin; anfani ni yio jẹ fun nyin bi emi ba lọ: nitori bi emi kò ba lọ, Olutunu kì yio tọ̀ nyin wá: ṣugbọn bi mo ba lọ, emi o rán a si nyin.


Nitori Ọlọrun kò rán Ọmọ rẹ̀ si aiye lati da araiye lẹjọ; ṣugbọn ki a le ti ipasẹ rẹ̀ gbà araiye là.


Nitoripe gẹgẹ bi Baba ti ni iye ninu ara rẹ̀; gẹgẹ bẹ̃li o si fifun Ọmọ lati ni iye ninu ara rẹ̀;


Nitorina Jesu da wọn lohùn, o si wipe, Ẹkọ́ mi ki iṣe temi, bikoṣe ti ẹniti o rán mi.


Ṣugbọn nisisiyi ẹnyin nwá ọ̀na ati pa mi, ẹniti o sọ otitọ fun nyin, eyi ti mo ti gbọ́ lọdọ Ọlọrun: Abrahamu kò ṣe eyi.


Ẹniti iṣe ti Ọlọrun, a ma gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun: nitori eyi li ẹnyin kò ṣe gbọ, nitori ẹnyin kì iṣe ti Ọlọrun.


Titi o fi di ọjọ ti a gbà a lọ soke, lẹhin ti o ti ti ipa Ẹmi Mimọ́ paṣẹ fun awọn aposteli ti o yàn:


Ani Jesu ti Nasareti, bi Ọlọrun ti dà Ẹmi Mimọ́ ati agbara le e lori: ẹniti o nkiri ṣe ore, nṣe didá ara gbogbo awọn ti Èṣu si npọn loju; nitori Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀.


Nitori ofin Ẹmí ìye ninu Kristi Jesu ti sọ mi di omnira lọwọ ofin ẹ̀ṣẹ ati ti ikú.


Fun emi ti o kere ju ẹniti o kere julọ ninu gbogbo awọn enia mimọ́, li a fi ore-ọfẹ yi fun, lati wasu awamáridi ọrọ̀ Kristi fun awọn Keferi;


Nitori didun inu Baba ni pe ki ẹkún gbogbo le mã gbé inu rẹ̀;


Nitoripe ninu rẹ̀ ni gbogbo ẹ̀kún Iwa-Ọlọrun ngbé li ara-iyara.


O si wi fun mi pe, O pari. Emi ni Alfa ati Omega, ipilẹṣẹ ati opin. Emi ó si fi omi fun ẹniti ongbẹ ngbẹ lati orisun omi ìye lọfẹ̃.


O si fi odò omi ìye kan han mi, ti o mọ́ bi kristali, ti nti ibi itẹ́ Ọlọrun ati ti Ọdọ-Agutan jade wá.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan