Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 3:32 - Bibeli Mimọ

32 Ohun ti o ti ri ti o si ti gbọ́ eyina si li on njẹri rẹ̀; ko si si ẹniti o gbà ẹrí rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

32 Ohun tí ó rí, tí ó sì gbọ́ ni ó ń jẹ́rìí sí, ṣugbọn ẹ̀yin kò gba ẹ̀rí rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

32 Ohun tí ó ti rí tí ó sì ti gbọ́ èyí náà sì ni òun ń jẹ́rìí rẹ̀; kò sì sí ẹni tí ó gba ẹ̀rí rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 3:32
13 Iomraidhean Croise  

Nitori nigbati mo de, kò si ẹnikan? nigbati mo pè, kò si ẹnikan lati dahùn? Ọwọ́ mi ha kuru tobẹ̃ ti kò fi le rapada? tabi emi kò ha li agbara lati gbani? Kiyesi i, ni ibawi mi mo gbẹ okun, mo sọ odò nla di aginjù, ẹja wọn nrùn nitori ti omi kò si, nwọn si kú fun ongbẹ.


TALI o ti gbà ihìn wa gbọ́? tali a si ti fi apá Oluwa hàn fun?


Nitori ẹnikẹni ti o bère nri gbà; ẹniti o ba si wá kiri nri: ẹniti o ba si nkànkun, li a o ṣí i silẹ fun.


O tọ̀ awọn tirẹ̀ wá, awọn ará tirẹ̀ kò si gbà a.


Emi kò pè nyin li ọmọ-ọdọ mọ́; nitori ọmọ-ọdọ kò mọ̀ ohun ti oluwa rẹ̀ nṣe: ṣugbọn emi pè nyin li ọrẹ́; nitori ohun gbogbo ti mo ti gbọ́ lati ọdọ Baba mi wá, mo ti fi hàn fun nyin.


Nitorina Pilatu wi fun u pe, Njẹ iwọ ha ṣe ọba bi? Jesu dahùn wipe, Iwọ wipe, ọba li emi iṣe. Nitori eyi li a ṣe bí mi, ati nitori idi eyi ni mo si ṣe wá si aiye, ki emi ki o le jẹri si otitọ. Olukuluku ẹniti iṣe ti otitọ ngbọ́ ohùn mi.


Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun ọ, Awa nsọ eyiti awa mọ̀, a si njẹri eyiti awa ti ri; ẹnyin kò si gbà ẹri wa.


Nwọn si tọ̀ Johanu wá, nwọn si wi fun u pe, Rabbi, ẹniti o ti wà pẹlu rẹ loke odò Jordani, ti iwọ ti jẹrí rẹ̀, wo o, on mbaptisi, gbogbo enia si ntọ̀ ọ̀ wá.


Ẹniti o gbà ẹrí rẹ̀ fi edidi di i pe, otitọ li Ọlọrun.


Nitori Baba fẹràn Ọmọ, o si fi ohun gbogbo ti on tikararẹ̀ nṣe hàn a: on ó si fi iṣẹ ti o tobi ju wọnyi lọ hàn a, ki ẹnu ki o le yà nyin.


Mo ni ohun pupọ̀ lati sọ, ati lati ṣe idajọ nipa nyin: ṣugbọn olõtọ li ẹniti o ran mi, ohun ti emi si ti gbọ lati ọdọ rẹ̀ wá, nwọnyi li emi nsọ fun araiye.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan