Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 3:30 - Bibeli Mimọ

30 On kò le ṣaima pọsi i, ṣugbọn emi kò le ṣaima rẹ̀hin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

30 Dandan ni pé kí òun túbọ̀ jẹ́ pataki sí i, ṣugbọn kí jíjẹ́ pataki tèmi máa dínkù.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

30 Òun kò lè ṣàì máa pọ̀ sí i, ṣùgbọ́n èmi kò lè ṣàìmá rẹlẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 3:30
15 Iomraidhean Croise  

Nitorina emi o fun u ni ipín pẹlu awọn ẹni-nla, yio si ba awọn alagbara pín ikogun, nitori o ti tú ẹmi rẹ̀ jade si ikú: a si kà a mọ awọn alarekọja, o si rù ẹ̀ṣẹ ọ̀pọlọpọ; o si nṣipẹ̀ fun awọn alarekọja.


Ijọba yio bi si i, alafia ki yio ni ipẹkun: lori itẹ Dafidi, ati lori ijọba rẹ̀, lati ma tọ́ ọ, ati lati fi idi rẹ̀ mulẹ, nipa idajọ, ati ododo lati isisiyi lọ, ani titi lai. Itara Oluwa awọn ọmọ-ogun yio ṣe eyi.


Ẹniti o ba ni iyawo ni ọkọ iyawo; ṣugbọn ọrẹ́ ọkọ iyawo ti o duro ti o si ngbohùn rẹ̀, o nyọ̀ gidigidi nitori ohùn ọkọ iyawo; nitorina ayọ̀ mi yi di kíkun.


Ẹniti o ti oke wá ju gbogbo enia lọ: ẹniti o ti aiye wá ti aiye ni, a si ma sọ̀ ohun ti aiye: ẹniti o ti ọrun wá ju gbogbo enia lọ.


Kini Apollo ha jẹ? kini Paulu si jẹ? bikoṣe awọn iranṣẹ nipasẹ ẹniti ẹnyin ti gbagbọ́, ati olukuluku gẹgẹ bi Oluwa ti fun.


On si jẹ ori fun ara, eyini ni ìjọ: ẹniti iṣe ipilẹṣẹ, akọbi lati inu okú wá; pe, ninu ohun gbogbo ki on ki o le ni ipò ti o ga julọ.


Angẹli keje si fun ipè; a si gbọ́ ohùn nla lati ọrun wá, wipe, Ijọba aiye di ti Oluwa wa, ati ti Kristi rẹ̀; on o si jọba lai ati lailai.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan