Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 3:26 - Bibeli Mimọ

26 Nwọn si tọ̀ Johanu wá, nwọn si wi fun u pe, Rabbi, ẹniti o ti wà pẹlu rẹ loke odò Jordani, ti iwọ ti jẹrí rẹ̀, wo o, on mbaptisi, gbogbo enia si ntọ̀ ọ̀ wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

26 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà bá lọ sọ́dọ̀ Johanu, wọ́n wí fún un pé, “Olùkọ́ni, ọkunrin tí ó wà pẹlu rẹ ní òdìkejì odò Jọdani, tí o jẹ́rìí nípa rẹ̀, ń ṣe ìrìbọmi, gbogbo eniyan sì ń tọ̀ ọ́ lọ.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

26 Wọ́n sì tọ Johanu wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Rabbi, ẹni tí ó ti wà pẹ̀lú rẹ lókè odò Jordani, tí ìwọ ti jẹ́rìí rẹ̀, wò ó, òun tẹ àwọn ènìyàn bọ omi, gbogbo ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ wá.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 3:26
23 Iomraidhean Croise  

Iwọ ti ngbọ́ adura, si ọdọ rẹ ni gbogbo enia mbọ̀.


Ati pẹlu, mo rò gbogbo lãla ati ìmọ iṣẹ gbogbo, pe eyiyi ni ilara ẹnikini lati ọdọ ẹnikeji rẹ̀. Asan li eyi pẹlu ati imulẹmofo.


Mo ti fi ara mi bura, ọ̀rọ na ti ti ẹnu ododo mi jade, ki yio si pada, pe, Gbogbo ẽkún yio kunlẹ fun mi, gbogbọ ahọn yio bura.


Ati ikíni li ọjà, ati ki awọn enia mã pè wọn pe, Rabbi, Rabbi.


Ṣugbọn ki a máṣe pè ẹnyin ni Rabbi: nitoripe ẹnikan ni Olukọ nyin, ani Kristi; ará si ni gbogbo nyin.


Johanu si jẹri rẹ̀ o si kigbe, wipe, Eyi ni ẹniti mo sọrọ rẹ̀ pe, Ẹniti mbọ̀ lẹhin mi, o pọ̀ju mi lọ: nitori o wà ṣiwaju mi.


On na li a si rán fun ẹri, ki o le ṣe ẹlẹri fun imọlẹ na, ki gbogbo enia ki o le gbagbọ́ nipasẹ rẹ̀.


Imọlẹ otitọ mbẹ ti ntàn mọlẹ fun olúkulùku enia ti o wá si aiye.


Bi awa ba jọwọ rẹ̀ bẹ̃, gbogbo enia ni yio gbà a gbọ́: awọn ará Romu yio si wá gbà ilẹ ati orilẹ-ède wa pẹlu.


Nitorina awọn Farisi wi fun ara wọn pe, Ẹ kiyesi bi ẹ kò ti le bori li ohunkohun? ẹ wò bi gbogbo aiye ti nwọ́ tọ̀ ọ.


On na li o tọ̀ Jesu wá li oru, o si wi fun u pe, Rabbi, awa mọ̀ pe olukọni lati ọdọ Ọlọrun wá ni iwọ iṣe: nitoripe kò si ẹniti o le ṣe iṣẹ àmi wọnyi ti iwọ nṣe, bikoṣepe Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀.


NITORINA nigbati Oluwa ti mọ̀ bi awọn Farisi ti gbọ́ pe, Jesu nṣe o si mbaptisi awọn ọmọ-ẹhin pupọ jù Johanu lọ,


(Ṣugbọn Jesu tikararẹ̀ kò baptisi bikoṣe awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀,)


Lãrin eyi awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nrọ̀ ọ, wipe, Rabbi, jẹun.


Ẹnyin ti ranṣẹ lọ sọdọ Johanu, on si ti jẹri si otitọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan