Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 3:20 - Bibeli Mimọ

20 Nitori olukuluku ẹniti o ba hùwa buburu ni ikorira imọlẹ, ki isi wá si imọlẹ, ki a máṣe ba iṣẹ rẹ̀ wí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

20 Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe burúkú a máa kórìíra ìmọ́lẹ̀; kò jẹ́ wá sí ibi tí ìmọ́lẹ̀ bá wà, kí eniyan má baà bá a wí nítorí iṣẹ́ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

20 Nítorí olúkúlùkù ẹni tí ó bá hùwà búburú ní ìkórìíra ìmọ́lẹ̀, kì í sì í wá sí ìmọ́lẹ̀, kí a má ṣe bá iṣẹ́ rẹ̀ wí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 3:20
18 Iomraidhean Croise  

On si mu awo na, o si dà a sinu awo miran niwaju rẹ̀; ṣugbọn o kọ̀ lati jẹ. Amnoni si wipe, jẹ ki gbogbo ọkunrin jade kuro lọdọ mi. Nwọn si jade olukuluku ọkunrin kuro lọdọ rẹ̀.


Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, ọkunrin kan Mikaiah, ọmọ Imla, mbẹ sibẹ, lọdọ ẹniti awa iba bère lọwọ Oluwa: ṣugbọn emi korira rẹ̀, nitori kì isọ asọtẹlẹ ire si mi, bikoṣe ibi. Jehoṣafati si wipe, Ki ọba má sọ bẹ̃.


O si dide li ọ̀ganjọ, o si gbe ọmọ mi lati iha mi, nigbati iranṣẹ-birin rẹ sun, o si tẹ́ ẹ si aiya rẹ̀, o si tẹ́ okú ọmọ tirẹ̀ si aiya mi.


Wò o, iwọ sa korira ẹkọ́, iwọ si ti ṣá ọ̀rọ mi tì lẹhin rẹ.


Nitori ti nwọn korira ìmọ, nwọn kò si yàn ibẹ̀ru Oluwa.


Ẹlẹgàn kò fẹ ẹniti mba a wi; bẹ̃ni kì yio tọ̀ awọn ọlọgbọ́n lọ.


On a di oju rẹ̀ lati gbèro ohun ayidayida: o ká ète rẹ̀ sinu, o pari ohun buburu.


Ẹniti o fi ipa-ọ̀na iduroṣinṣin silẹ, lati rìn li ọ̀na òkunkun;


Ṣugbọn ipa-ọ̀na awọn olõtọ dabi titàn imọlẹ, ti o ntàn siwaju ati siwaju titi di ọsangangan.


Iwọ a si wipe, emi ha ti korira ẹkọ́ to, ti aiya mi si gàn ìbawi:


Ibugbe rẹ mbẹ lãrin ẹ̀tan; nipa ẹ̀tan nwọn kọ̀ lati mọ̀ mi, li Oluwa wi.


Nigbana li ọkan ninu awọn amofin dahùn, o si wi fun u pe, Olukọni, li eyi ti iwọ nwi nì iwọ ngàn awa pẹlu.


Ṣugbọn ẹniti o ba nṣe otitọ ni iwá si imọlẹ, ki iṣẹ rẹ̀ ki o le fi ara hàn pe, a ṣe wọn nipa ti Ọlọrun.


Aiye kò le korira nyin; ṣugbọn emi li o korira, nitoriti mo jẹri gbe e pe, iṣẹ rẹ̀ buru.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan