Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 3:19 - Bibeli Mimọ

19 Eyi ni idajọ na pe, imọlẹ wá si aiye, awọn enia si fẹ òkunkun jù imọlẹ lọ, nitoriti iṣẹ wọn buru.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

19 Ìdálẹ́bi náà ni pé ìmọ́lẹ̀ ti dé sinu ayé, ṣugbọn aráyé fẹ́ràn òkùnkùn ju ìmọ́lẹ̀ lọ, nítorí iṣẹ́ wọn burú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

19 Èyí ni ìdájọ́ náà pé, ìmọ́lẹ̀ wá sí ayé, àwọn ènìyàn sì fẹ́ òkùnkùn ju ìmọ́lẹ̀ lọ, nítorí tí iṣẹ́ wọn burú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 3:19
33 Iomraidhean Croise  

Ẹniti o fi ipa-ọ̀na iduroṣinṣin silẹ, lati rìn li ọ̀na òkunkun;


Ibugbe rẹ mbẹ lãrin ẹ̀tan; nipa ẹ̀tan nwọn kọ̀ lati mọ̀ mi, li Oluwa wi.


Ati ogongo, ati owiwi, ati ẹlulu, ati awodi li onirũru rẹ̀,


Ki alufa ki o si wò o, si kiyesi i, bi iwú na ba funfun li awọ ara rẹ̀, ti o si sọ irun rẹ̀ di funfun, ti õju si mbẹ ninu iwú na,


Eyi ni yio si jẹ iyà Egipti, ati iyà gbogbo orilẹ-ède ti kò goke wá lati pa àse agọ mọ.


Ati ọmọ-ọdọ na, ti o mọ̀ ifẹ oluwa rẹ̀, ti kò si mura silẹ ti kò si ṣe gẹgẹ bi ifẹ rẹ̀, on li a o nà pipọ.


Awọn Farisi, ti nwọn ni ojukokoro si gbọ́ gbogbo nkan wọnyi, nwọn si yọ-ṣùti si i.


Ninu rẹ̀ ni ìye wà; ìye na si ni imọlẹ̀ araiye.


Imọlẹ na si nmọlẹ ninu òkunkun; òkunkun na kò si bori rẹ̀.


Nisisiyi ni idajọ aiye yi de: nisisiyi li a o lé alade aiye yi jade.


Nitori nwọn fẹ iyìn enia jù iyìn ti Ọlọrun lọ.


Emi ni imọlẹ ti o wá si aiye, ki ẹnikẹni ti o ba gbà mi gbọ́ ki o máṣe wà li òkunkun.


Ẹnyin o ti ṣe le gbagbọ́, ẹnyin ti ngbà ogo lọdọ ara nyin, ti kò wá ogo ti o ti ọdọ Ọlọrun nikan wá?


Bi ẹnikẹni ba fẹ lati ṣe ifẹ rẹ̀, yio mọ̀ niti ẹkọ́ na, bi iba ṣe ti Ọlọrun, tabi bi emi ba nsọ ti ara mi.


Aiye kò le korira nyin; ṣugbọn emi li o korira, nitoriti mo jẹri gbe e pe, iṣẹ rẹ̀ buru.


Jesu si tun sọ fun wọn pe, Emi ni imọlẹ aiye; ẹniti o ba tọ̀ mi lẹhin kì yio rìn ninu òkunkun, ṣugbọn yio ni imọlẹ ìye.


Niwọn igba ti mo wà li aiye, emi ni imọlẹ aiye.


Awọn ẹniti o mọ̀ ilana Ọlọrun pe, ẹniti o ba ṣe irú nkan wọnyi, o yẹ si ikú, nwọn kò ṣe bẹ̃ nikan, ṣugbọn nwọn ni inu didùn si awọn ti nṣe wọn.


Ṣugbọn fun awọn onijà, ti nwọn kò si gbà otitọ gbọ́, ṣugbọn ti nwọn ngbà aiṣododo gbọ́, irunu ati ibinu yio wà.


Ki a le ṣe idajọ gbogbo awọn ti kò gbà otitọ gbọ́, ṣugbọn ti nwọn ni inu didùn ninu aiṣododo.


Ati pẹlu, okuta idigbolu, on apata ikọsẹ̀. Nitori nwọn kọsẹ nipa ṣiṣe aigbọran si ọrọ na ninu eyiti a gbé yàn wọn si pẹlu.


Ki ẹ kọ́ mọ̀ eyi pe, nigba ọjọ ikẹhin, awọn ẹlẹgan yio de pẹlu ẹgan wọn, nwọn o mã rin nipa ifẹ ara wọn,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan