Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 3:14 - Bibeli Mimọ

14 Bi Mose si ti gbé ejò soke li aginjù, gẹgẹ bẹ̃li a kò le ṣe alaigbé Ọmọ-enia soke pẹlu:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

14 Bí Mose ti gbé ejò sókè ní aṣálẹ̀, bẹ́ẹ̀ gan-an ni a óo gbé Ọmọ-Eniyan sókè,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

14 Bí Mose sì ti gbé ejò sókè ní aginjù, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni a kò le ṣe aláìgbé Ọmọ Ènìyàn sókè pẹ̀lú:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 3:14
16 Iomraidhean Croise  

On mu ibi giga wọnni kuro, o si fọ́ awọn ere, o si wó awọn ere oriṣa lulẹ, o si fọ́ ejò idẹ na tútu ti Mose ti ṣe: nitori titi di ọjọ wọnni, awọn ọmọ Israeli nsun turari si i: a si pè e ni Nehuṣtani.


Nitoriti awọn aja yi mi ka: ijọ awọn enia buburu ti ká mi mọ́: nwọn lu mi li ọwọ, nwọn si lu mi li ẹsẹ.


Ati li ọjọ na kùkute Jesse kan yio wà, ti yio duro fun ọpágun awọn enia; on li awọn keferi yio wá ri: isimi rẹ̀ yio si li ogo.


Ṣugbọn iwe-mimọ́ yio ha ti ṣe ti yio fi ṣẹ, pe bẹ̃ni yio ri?


Jesu si wi fun u pe, Awọn kọ̀lọkọlọ ni ihò, ati awọn ẹiyẹ oju ọrun ni itẹ́; ṣugbọn Ọmọ-enia kò ni ibi ti yio gbé fi ori rẹ̀ le.


Ati bi awọn olori alufa ati awọn alàgba wa ti fi i le wọn lọwọ lati da a lẹbi iku, ati bi nwọn ti kàn a mọ agbelebu.


Ki ọ̀rọ Jesu ki o le ba ṣẹ, eyiti o sọ, ti o nṣapẹrẹ irú ikú ti on o kú.


Emi ni onjẹ ìye nì ti o ti ọrun sọkalẹ wá: bi ẹnikẹni ba jẹ ninu onjẹ yi, yio yè titi lailai: onjẹ na ti emi o si fifunni li ara mi, fun ìye araiye.


Nitorina Jesu wi fun wọn pe, Nigbati ẹ ba gbé Ọmọ-enia soke, nigbana li ẹ o mọ̀ pe, emi ni, ati pe emi kò dá ohunkohun ṣe fun ara mi; ṣugbọn bi Baba ti kọ́ mi, emi nsọ nkan wọnyi.


Ẹniti a ti fi le nyin lọwọ nipa ipinnu ìmọ ati imọtẹlẹ Ọlọrun; on li ẹnyin mu, ti ẹ ti ọwọ awọn enia buburu kàn mọ agbelebu, ti ẹ si pa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan