Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 3:10 - Bibeli Mimọ

10 Jesu dahùn, o si wi fun u pe, Ṣe olukọni ni Israeli ni iwọ iṣe, o kò si mọ̀ nkan wọnyi?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

10 Jesu ní, “Mo ṣebí olùkọ́ni olókìkí ní Israẹli ni ọ́, sibẹ o kò mọ nǹkan wọnyi?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Jesu dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ṣé olùkọ́ni ní Israẹli ni ìwọ ń ṣe, o kò sì mọ nǹkan wọ̀nyí?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 3:10
28 Iomraidhean Croise  

Si fi ọkàn pipe fun Solomoni ọmọ mi lati pa ofin rẹ, ẹri rẹ, ati ilana rẹ mọ́, ati lati ṣe ohun gbogbo, ati lati kọ́ ãfin, fun eyi ti mo ti pèse silẹ.


Da aiya titun sinu mi, Ọlọrun; ki o si tún ọkàn diduroṣinṣin ṣe sinu mi.


Kiyesi i, iwọ fẹ otitọ ni inu: ati niha ìkọkọ ni iwọ o mu mi mọ̀ ọgbọ́n.


NITÕTỌ Ọlọrun ṣeun fun Israeli, fun iru awọn ti iṣe alaiya mimọ́.


Afọju li awọn alore rẹ̀: òpe ni gbogbo wọn, odi ajá ni nwọn, nwọn kò le igbó, nwọn a ma sùn, nwọn ndubulẹ, nwọn fẹ ma tõgbé.


Nitori awọn olori enia yi mu wọn ṣìna: awọn ti a si tọ́ li ọ̀na ninu wọn li a parun.


Ṣugbọn eyi ni majẹmu ti emi o ba ile Israeli da; Lẹhin ọjọ wọnni, li Oluwa wi, emi o fi ofin mi si inu wọn, emi o si kọ ọ si aiya wọn; emi o si jẹ Ọlọrun wọn, awọn o si jẹ enia mi.


Emi o si fun wọn li ọkàn kan, emi o si fi ẹmi titun sinu nyin; emi o si mu ọkàn okuta kuro lara wọn, emi o si fun wọn li ọkàn ẹran:


Lakokò na ni Jesu dahùn, o si wipe, Mo dupẹ lọwọ rẹ Baba, Oluwa ọrun on aiye, nitoriti iwọ pa nkan wọnyi mọ́ kuro li oju awọn ọlọ́gbọn ati amoye, iwọ si fi wọn hàn fun awọn ọmọ-ọwọ́.


Ẹ jọwọ wọn si: afọju ti nfọ̀nahàn afọju ni nwọn. Bi afọju ba si nfọnahàn afọju, awọn mejeji ni yio ṣubu sinu ihò.


Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹnyin ṣìna, nitori ẹnyin kò mọ̀ iwe-mimọ́, ẹ kò si mọ̀ agbara Ọlọrun.


O si ṣe, lẹhin ijọ mẹta nwọn ri i ninu tẹmpili o joko li arin awọn olukọni, o ngbọ́ ti wọn, o si mbi wọn lẽre.


O si ṣe ni ijọ kan, bi o si ti nkọ́ni, awọn Farisi ati awọn amofin joko ni ìha ibẹ̀, awọn ti o ti ilu Galili gbogbo, ati Judea, ati Jerusalemu wá: agbara Oluwa si mbẹ lati mu wọn larada.


Nikodemu dahùn, o si wi fun u pe, Nkan wọnyi yio ti ṣe le ri bẹ̃?


Ṣugbọn ọkan ninu ajọ igbimọ, ti a npè ni Gamalieli, Farisi ati amofin, ti o ni iyìn gidigidi lọdọ gbogbo enia, o dide duro, o ni ki a mu awọn aposteli bì sẹhin diẹ;


Kì iṣe eyi ti o farahan ni Ju, bẹni kì iṣe eyi ti o farahan li ara ni ikọla:


Nitorina ẹ kọ àiya nyin nilà, ki ẹ má si ṣe ọlọrùn lile mọ́.


OLUWA Ọlọrun rẹ yio si kọ àiya rẹ nilà, ati àiya irú-ọmọ rẹ, lati ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ pẹlu àiya rẹ gbogbo, ati pẹlu ọkàn rẹ gbogbo, ki iwọ ki o le yè.


Nitori awa ni onilà, ti nsìn Ọlọrun nipa ti Ẹmí, awa si nṣogo ninu Kristi Jesu, awa kò si ni igbẹkẹle ninu ẹran-ara;


Ninu ẹniti a ti fi ikọla ti a kò fi ọwọ kọ kọ nyin ni ila, ni bibọ ara ẹ̀ṣẹ silẹ, ninu ikọla Kristi:


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan