Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 21:7 - Bibeli Mimọ

7 Nitorina li ọmọ-ẹhin na ti Jesu fẹran wi fun Peteru pe, Oluwa ni. Nigbati Simoni Peteru gbọ́ pe Oluwa ni, bẹli o di amure ẹ̀wu rẹ̀ mọra, (nitori o wà ni ìhoho), o si gbé ara rẹ̀ sọ sinu okun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

7 Ọmọ-ẹ̀yìn tí Jesu fẹ́ràn sọ fún Peteru pé, “Oluwa ni!” Nígbà tí Simoni Peteru gbọ́ pé Oluwa ni, ó wọ ẹ̀wù rẹ̀, nítorí ó ti bọ́ra sílẹ̀ fún iṣẹ́, ó bá bẹ́ sinu òkun, ó ń lúwẹ̀ẹ́ lọ sébùúté.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà tí Jesu fẹ́ràn wí fún Peteru pé, “Olúwa ni!” Nígbà tí Simoni Peteru gbọ́ pé Olúwa ni, bẹ́ẹ̀ ni ó di àmùrè ẹ̀wù rẹ̀ mọ́ra, nítorí tí ó wà ní ìhòhò, ó sì gbé ara rẹ̀ sọ sínú Òkun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 21:7
20 Iomraidhean Croise  

Lati ọdọ Oluwa li eyi: o ṣe iyanu li oju wa.


Omi pupọ kò le paná ifẹ, bẹ̃ni kikún omi kò le gbá a lọ, bi enia fẹ fi gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ fun ifẹ, a o kẹgàn rẹ̀ patapata.


Bi ẹnikẹni ba si wi fun nyin pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nṣe eyi? ẹ wipe, Oluwa ni fi ṣe; lojukanna yio si rán a wá sihinyi.


Ẹ di amure nyin, ki fitila nyin ki o si mã jo:


Nitori a bí Olugbala fun nyin loni ni ilu Dafidi, ti iṣe Kristi Oluwa.


Njẹ mo wi fun ọ, A dari ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o pọ̀ jì i; nitoriti o ni ifẹ pipọ: ẹniti a si dari diẹ jì, on na li o ni ifẹ diẹ.


Njẹ ẹnikan rọ̀gún si àiya Jesu, ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ẹniti Jesu fẹràn.


Nitorina nigbati Jesu ri iya rẹ̀, ati ọmọ-ẹhin na duro, ẹniti Jesu fẹràn, o wi fun iya rẹ̀ pe, Obinrin, wò ọmọ rẹ!


Nitorina o sare, o si tọ̀ Simoni Peteru wá, ati ọmọ-ẹhin miran na ẹniti Jesu fẹran, o si wi fun wọn pe, Nwọn ti gbé Oluwa kuro ninu ibojì, awa kò si mọ̀ ibi ti nwọn gbé tẹ́ ẹ si.


Nigbati o si ti wi bẹ̃ tan, o fi ọwọ́ ati ìha rẹ̀ hàn wọn. Nitorina li awọn ọmọ-ẹhin yọ̀, nigbati nwọn ri Oluwa.


Tomasi dahun o si wi fun u pe, Oluwa mi ati Ọlọrun mi!


Peteru si yipada, o ri ọmọ-ẹhin nì, ẹniti Jesu fẹràn, mbọ̀ lẹhin; ẹniti o si rọ̀gun si àiya rẹ̀ nigba onjẹ alẹ ti o si wi fun u pe, Oluwa, tali ẹniti yõ fi ọ hàn?


Eyi li ọmọ-ẹhin na, ti o jẹri nkan wọnyi, ti o si kọwe nkan wọnyi: awa si mọ̀ pe, otitọ ni ẹ̀rí rẹ̀.


Ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin iyoku mu ọkọ̀ kekere kan wá (nitoriti nwọn kò jina silẹ, ṣugbọn bi iwọn igba igbọnwọ); nwọn nwọ́ àwọn nã ti o kún fun ẹja.


Ọ̀rọ ti Ọlọrun rán si awọn ọmọ Israeli, nigbati o wasu alafia nipa Jesu Kristi (on li Oluwa ohun gbogbo),


Njẹ ki gbogbo ile Israeli ki o mọ̀ dajudaju pe, Ọlọrun ti fi Jesu na, ti ẹnyin kàn mọ agbelebu, jẹ Oluwa ati Kristi.


Ọkunrin iṣaju ti inu erupẹ̀ wá, ẹni erupẹ̀: ọkunrin ekeji Oluwa lati ọrun wá ni.


Nitori ifẹ Kristi nrọ̀ wa; nitori awa rò bayi, pe bi ẹnikan ba ti kú fun gbogbo enia, njẹ gbogbo wọn li o ti kú:


ẸNYIN ará mi, ẹ máṣe fi iṣãju enia dì igbagbọ́ Oluwa wa Jesu Kristi Oluwa ogo mu.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan