Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 21:3 - Bibeli Mimọ

3 Simoni Peteru wi fun wọn pe, Emi nlọ ipẹja. Nwọn wi fun u pe, Awa pẹlu mba ọ lọ. Nwọn jade, nwọn si wọ̀ inú ọkọ̀; li oru na nwọn kò si mú ohunkohun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Simoni Peteru sọ fún wọn pé, “Mò ń lọ pa ẹja.” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwa náà yóo bá ọ lọ.” Wọ́n bá jáde lọ, wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi. Ní gbogbo alẹ́ ọjọ́ náà wọn kò rí ẹja kankan pa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Simoni Peteru wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ pẹja!” Wọ́n wí fún un pé, “Àwa pẹ̀lú ń bá ọ lọ.” Wọ́n jáde, wọ́n sì wọ inú ọkọ̀ ojú omi; ní òru náà wọn kò sì mú ohunkóhun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 21:3
11 Iomraidhean Croise  

Simoni si dahùn o si wi fun u pe, Olukọni, gbogbo oru aná li awa fi ṣìṣẹ, awa kò si mú nkan: ṣugbọn nitori ọrọ rẹ emi ó jù àwọn na si isalẹ.


Ṣugbọn nigbati ilẹ bẹrẹ si imọ́, Jesu duro leti okun: ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin kò mọ̀ pe Jesu ni.


Ati itori ti iṣe oniṣẹ ọnà kanna, o ba wọn joko, o si nṣiṣẹ: nitori agọ́ pipa ni iṣẹ ọnà wọn.


Ẹnyin tikaranyin sá mọ̀ pe, ọwọ́ wọnyi li o ṣiṣẹ fun aini mi, ati ti awọn ti o wà pẹlu mi.


Njẹ kì iṣe ẹniti o ngbìn nkankan, bẹ̃ni kì iṣe ẹniti mbomirin; bikoṣe Ọlọrun ti o nmu ibisi wá.


Tabi emi nikan ati Barnaba, awa kò ha li agbara lati joko li aiṣiṣẹ?


Nitori ẹnyin ranti, ará, ìṣẹ́ ati lãlã wa: nitori awa nṣe lãlã li ọsán ati li oru, ki awa ko má bã di ẹrù ru ẹnikẹni ninu nyin, awa wasu ihinrere Ọlọrun fun nyin.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan