Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 21:23 - Bibeli Mimọ

23 Nitorina ọ̀rọ yi si tàn ka lãrin awọn arakunrin pe, ọmọ-ẹhin nì kì yio kú: ṣugbọn Jesu kò wi fun u pe, On kì yio kú; ṣugbọn, Bi emi ba fẹ ki o duro titi emi o fi de, kili eyinì si ọ?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

23 Nígbà tí gbolohun yìí dé etí àwọn onigbagbọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé ọmọ-ẹ̀yìn náà kò ní kú. Ṣugbọn kò sọ fún un pé kò ní kú. Ohun tí ó wí ni pé, “Bí mo bá fẹ́ kí ó wà títí n óo fi dé, èwo ni ó kàn ọ́?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

23 Ọ̀rọ̀ yìí sì tàn ká láàrín àwọn arákùnrin pé, ọmọ-ẹ̀yìn náà kì yóò kú: ṣùgbọ́n Jesu kò wí fún un pé, òun kì yóò kú; ṣùgbọ́n, “Bí èmi bá fẹ́ kí ó dúró títí èmi ó fi dé, kín ni èyí jẹ́ sí ọ?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 21:23
12 Iomraidhean Croise  

Nitori kini iwọ ṣe mba a jà pe: on kì isọrọ̀kọrọ kan nitori iṣẹ rẹ̀?


Ti OLUWA Ọlọrun wa ni ohun ìkọkọ: ṣugbọn ohun ti afihàn ni tiwa ati ti awọn ọmọ wa lailai, ki awa ki o le ma ṣe gbogbo ọ̀rọ ofin yi.


Ni ijọ wọnni ni Peteru si dide duro li awujọ awọn ọmọ-ẹhin (iye awọn enia gbogbo ninu ijọ jẹ ọgọfa,) o ni,


Gbogbo awọn araiye li a si kà si bi ohun asan, on a si ma ṣe gẹgẹ bi o ti wù u ninu ogun ọrun, ati larin awọn araiye: kò si si ẹniti idá ọwọ rẹ̀ duro, tabi ẹniti iwi fun u pe, Kini iwọ nṣe nì?


Ati fun enia li o wipe, kiyesi i; Ẹru Oluwa, eyi li ọgbọ́n, ati lati jade kuro ninu ìwa-buburu eyi li oye!


Nitori Ọmọ-enia yio wá ninu ogo Baba rẹ̀ pẹlu awọn angẹli rẹ̀; nigbana ni yio san a fun olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀.


Nitorina, ará, ẹ wo ọkunrin meje ninu nyin, olorukọ rere, ẹniti o kún fun Ẹmí Mimọ́ ati fun ọgbọ́n, ẹniti awa iba yàn si iṣẹ yi.


Nibiti a gbé ri awọn arakunrin, ti nwọn si bẹ̀ wa lati ba wọn gbé ni ijọ meje: bẹ̃li awa si lọ si ìha Romu.


Nitorina, ẹ máṣe ṣe idajọ ohunkohun ṣaju akokò na, titi Oluwa yio fi de, ẹniti yio mu ohun òkunkun ti o farasin wá si imọlẹ, ti yio si fi ìmọ ọkàn hàn: nigbana li olukuluku yio si ni iyìn tirẹ̀ lọdọ Ọlọrun.


Nitori nigbakugba ti ẹnyin ba njẹ akara yi, ti ẹnyin ba si nmu ago yi, ẹnyin nkede ikú Oluwa titi yio fi de.


Nitorina ará, ẹ mu sũru titi di ipadawa Oluwa. Kiyesi i, àgbẹ a mã reti eso iyebiye ti ilẹ, a si mu sũru de e, titi di igbà akọrọ̀ ati arọ̀kuro òjo.


Ṣugbọn eyi ti ẹnyin ni, ẹ di i mu ṣinṣin titi emi o fi de.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan