Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 20:4 - Bibeli Mimọ

4 Awọn mejeji si jùmọ sare: eyi ọmọ-ẹhin miran nì si sare yà Peteru, o si tètekọ de ibojì.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 Àwọn mejeeji bẹ̀rẹ̀ sí sáré; ṣugbọn ọmọ-ẹ̀yìn keji ya Peteru sílẹ̀, òun ni ó kọ́ dé ibojì.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ sáré: èyí ọmọ-ẹ̀yìn náà sì sáré ya Peteru, ó sì kọ́kọ́ dé ibojì.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 20:4
7 Iomraidhean Croise  

O si wi pe, Bi o ti wu ki o ri, emi o sare. On si wi fun u pe, Sare. Ahimaasi si sare li ọ̀na pẹtẹlẹ, o si sare kọja Kuṣi.


Nigbana ni ki alufa ki o wò àrun na: si kiyesi i, bi o ba jìn jù awọ ara lọ li oju, bi irun tinrin pupa ba mbẹ ninu rẹ̀, nigbana ni ki alufa ki o pè e li aimọ́: ipẹ́ gbigbẹ ni, ani ẹ̀tẹ li ori tabi li àgbọn ni.


Nigbana ni Peteru jade, ati ọmọ-ẹhin miran na, nwọn si wá si ibojì.


O si bẹ̀rẹ, o si wò inu rẹ̀, o ri aṣọ ọgbọ na lelẹ; ṣugbọn on kò wọ̀ inu rẹ̀.


Nigbana li ọmọ-ẹhin miran na, ẹniti o kọ de ibojì, wọ̀ inu rẹ̀ pẹlu, o si ri, o si gbagbọ́.


Ẹnyin kò mọ̀ pe awọn ti nsáre ije, gbogbo nwọn ni nsáre nitõtọ, ṣugbọn ẹnikan ni ngbà ère na? Ẹ sáre bẹ̃, ki ẹnyin ki o le ri gbà.


Nitori bi imura-tẹlẹ ba wà ṣaju, o jasi itẹwọgbà gẹgẹ bi ohun ti enia bá ni, kì iṣe gẹgẹ bi ohun ti kò ni.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan