Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 20:2 - Bibeli Mimọ

2 Nitorina o sare, o si tọ̀ Simoni Peteru wá, ati ọmọ-ẹhin miran na ẹniti Jesu fẹran, o si wi fun wọn pe, Nwọn ti gbé Oluwa kuro ninu ibojì, awa kò si mọ̀ ibi ti nwọn gbé tẹ́ ẹ si.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Ó bá sáré lọ sọ́dọ̀ Simoni Peteru ati ọmọ-ẹ̀yìn tí Jesu fẹ́ràn, ó sọ fún wọn pé, “Wọ́n ti gbé Oluwa kúrò ninu ibojì, a kò sì mọ ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Nítorí náà, ó sáré, ó sì tọ Simoni Peteru àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn wá, ẹni tí Jesu fẹ́ràn, ó sì wí fún wọn pé, “Wọ́n ti gbé Olúwa kúrò nínú ibojì, àwa kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 20:2
9 Iomraidhean Croise  

Njẹ ẹnikan rọ̀gún si àiya Jesu, ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ẹniti Jesu fẹràn.


Nitorina nigbati Jesu ri iya rẹ̀, ati ọmọ-ẹhin na duro, ẹniti Jesu fẹràn, o wi fun iya rẹ̀ pe, Obinrin, wò ọmọ rẹ!


Nwọn si wi fun u pe, Obinrin yi, ẽṣe ti iwọ fi nsọkun? O si wi fun wọn pe, Nitoriti nwọn ti gbé Oluwa mi, emi kò si mọ̀ ibiti nwọn gbé tẹ́ ẹ si.


Jesu wi fun u pe, Obinrin yi, ẽṣe ti iwọ fi nsọkun? Ta ni iwọ nwá? On ṣebi oluṣọgba ni iṣe, o wi fun u pe, Alàgba, bi iwọ ba ti gbé e kuro nihin, sọ ibiti o gbé tẹ ẹ si fun mi, emi o si gbé e kuro.


Nitoripe nwọn kò sá ti imọ̀ iwe-mimọ́ pe, on kò le ṣaima jinde kuro ninu okú.


Peteru si yipada, o ri ọmọ-ẹhin nì, ẹniti Jesu fẹràn, mbọ̀ lẹhin; ẹniti o si rọ̀gun si àiya rẹ̀ nigba onjẹ alẹ ti o si wi fun u pe, Oluwa, tali ẹniti yõ fi ọ hàn?


Eyi li ọmọ-ẹhin na, ti o jẹri nkan wọnyi, ti o si kọwe nkan wọnyi: awa si mọ̀ pe, otitọ ni ẹ̀rí rẹ̀.


Nitorina li ọmọ-ẹhin na ti Jesu fẹran wi fun Peteru pe, Oluwa ni. Nigbati Simoni Peteru gbọ́ pe Oluwa ni, bẹli o di amure ẹ̀wu rẹ̀ mọra, (nitori o wà ni ìhoho), o si gbé ara rẹ̀ sọ sinu okun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan