Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 2:19 - Bibeli Mimọ

19 Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹ wó tẹmpili yi palẹ̀, ni ijọ mẹta Emi o si gbé e ró.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

19 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Bí ẹ bá wó Tẹmpili yìí, èmi yóo tún un kọ́ ní ọjọ́ mẹta.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

19 Jesu dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wó tẹmpili yìí palẹ̀, Èmi ó sì tún un kọ ní ọjọ́ mẹ́ta.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 2:19
23 Iomraidhean Croise  

Nitori bi Jona ti gbé ọsán mẹta ati oru mẹta ninu ẹja; bẹ̃li Ọmọ-enia yio gbé ọsán mẹta on oru mẹta ni inu ilẹ.


Lati igbana lọ ni Jesu ti bẹ̀rẹ si ifihàn awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, bi on ko ti le ṣailọ si Jerusalemu, lati jẹ ọ̀pọ ìya lọwọ awọn àgbagbà ati awọn olori alufa, ati awọn akọwe, ki a si pa on, ati ni ijọ kẹta, ki o si jinde.


Wipe, Iwọ ti o wó tẹmpili, ti o si kọ́ ọ ni ijọ mẹta, gbà ara rẹ là. Bi iwọ ba ṣe Ọmọ Ọlọrun, sọkalẹ lati ori agbelebu wá.


Nwọn wipe, Alàgba, awa ranti pe ẹlẹtan nì wi nigbati o wà lãye pe, Lẹhin ijọ mẹta, emi o jinde.


Awa gbọ́ o wipe, Emi ó wó tẹmpili yi ti a fi ọwọ́ ṣe, niwọn ijọ́ mẹta emi o si kọ́ omiran ti a kò fi ọwọ́ ṣe.


Awọn ti nrekọja lọ si nfi i ṣe ẹlẹyà, nwọn si nmì ori wọn, wipe, A, Iwọ ti o wó tẹmpili, ti o si kọ́ ọ ni ijọ mẹta,


O si bẹ̀rẹ si ikọ́ wọn, pe, Ọmọ-enia ko le ṣaima jìya ohun pipọ, a o si kọ̀ ọ lati ọdọ awọn àgbagba ati awọn olori alufa, ati awọn akọwe, a o si pa a, lẹhin ijọ mẹta yio si jinde.


Jesu wi fun u pe, Emi ni ajinde, ati ìye: ẹniti o ba gbà mi gbọ́, bi o tilẹ kú, yio yè:


Nigbana ni Jesu dahùn, o si wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ọmọ kò le ṣe ohunkohun fun ara rẹ̀, bikoṣe ohun ti o ba ri pe Baba nṣe: nitori ohunkohun ti o ba nṣe, wọnyi li Ọmọ si nṣe bẹ̃ gẹgẹ.


Ẹniti Ọlọrun gbé dide, nigbati o ti tú irora ikú: nitoriti kò ṣe iṣe fun u lati dì i mu.


Jesu na yi li Ọlọrun ti ji dide, ẹlẹri eyiti gbogbo wa iṣe.


Ẹnyin si pa Olupilẹṣẹ ìye, ẹniti Ọlọrun si ti ji dide kuro ninu okú; ẹlẹri eyiti awa nṣe.


Nigbati Ọlọrun jí Jesu Ọmọ rẹ̀ dide, o kọ́ rán a si nyin lati busi i fun nyin, nipa yiyi olukuluku nyin pada kuro ninu iwa buburu rẹ̀.


Nitori awa gbọ́ o wipe, Jesu ti Nasareti yi yio fọ́ ibi yi, yio si pa iṣe ti Mose fifun wa dà.


Ṣugbọn nitori tiwa pẹlu, ẹniti a o si kà a si fun, bi awa ba gbà a gbọ́, ẹniti o gbé Jesu Oluwa wa dide kuro ninu okú;


Njẹ a fi baptismu sinu ikú sin wa pọ̀ pẹlu rẹ̀: pe gẹgẹ bi a ti jí Kristi dide kuro ninu okú nipa ogo Baba bẹ̃ni ki awa pẹlu ki o mã rìn li ọtun ìwa.


Ṣugbọn bi Ẹmí ẹniti o jí Jesu dide kuro ninu okú ba ngbe inu nyin, ẹniti o ji Kristi Jesu dide kuro ninu okú yio fi Ẹmí rẹ̀ ti ngbe inu nyin, sọ ara kikú nyin di ãye pẹlu.


Njẹ bi a ba nwasu Kristi pe o ti jinde kuro ninu okú, ẽhatiṣe ti awọn miran ninu nyin fi wipe, ajinde okú kò si?


Bi a si ti sin nyin pọ̀ pẹlu rẹ̀ ninu baptismu, ninu eyiti a si ti jí nyin dide pẹlu rẹ̀ nipa igbagbọ́ ninu iṣẹ Ọlọrun, ẹniti o jí i dide kuro ninu okú.


Nitoriti Kristi pẹlu jìya lẹ̃kan nitori ẹ̀ṣẹ wa, olõtọ fun awọn alaiṣõtọ, ki o le mu wa de ọdọ Ọlọrun, ẹniti a pa ninu ara, ṣugbọn ti a sọ di ãye ninu ẹmí:


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan