Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 2:18 - Bibeli Mimọ

18 Nigbana li awọn Ju dahùn, nwọn si wi fun u pe Àmi wo ni iwọ fi hàn wa, ti iwọ fi nṣe nkan wọnyi?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

18 Àwọn Juu wá bi í pé, “Àmì wo ni ìwọ óo fihàn wá gẹ́gẹ́ bíi ìdí tí o fi ń ṣe nǹkan wọnyi?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

18 Nígbà náà ní àwọn Júù dáhùn, wọ́n sì bi í pé, “Ààmì wo ni ìwọ lè fihàn wá, tí ìwọ fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 2:18
14 Iomraidhean Croise  

O si fun wọn li àmi kan li ọjọ kanna wipe, Eyi li àmi ti Oluwa ti ṣe; Kiyesi i, pẹpẹ na yio ya, ẽru ti mbẹ lori rẹ̀ yio si danu.


Nigbati Farao yio ba wi fun nyin pe, Ẹ fi iṣẹ-iyanu kan hàn: nigbana ni ki iwọ ki o wi fun Aaroni pe, Mú ọpá rẹ, ki o si fi i lelẹ niwaju Farao, yio si di ejò.


Nigbati o si de inu tẹmpili, awọn olori alufa ati awọn àgba awọn enia wá sọdọ rẹ̀ bi o ti nkọ́ awọn enia; nwọn wipe, Aṣẹ wo ni iwọ fi nṣe nkan wọnyi? tali o si fun ọ li aṣẹ yi?


Awọn Farisi si jade wá, nwọn bẹrẹ si bi i lẽre, nwọn nfẹ àmi lati ọrun wá lọwọ rẹ̀, nwọn ndán a wò.


Nigbati ijọ enia si ṣùjọ si ọdọ rẹ̀ o bẹ̀rẹ sí wipe, Iran buburu li eyi: nwọn nwá àmi; a kì yio si fi àmi kan fun u, bikoṣe àmi Jona woli.


Eyi si li ẹrí Johanu, nigbati awọn Ju rán awọn alufã ati awọn ọmọ Lefi lati Jerusalemu wá lati bi i lẽre pe, Tani iwọ ṣe?


Nwọn si bi i lẽre, nwọn si wi fun u pe, Njẹ ẽṣe ti iwọ fi mbaptisi, bi iwọ kì ibá ṣe Kristi na, tabi Elijah, tabi woli na?


Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Iṣẹ ami kini iwọ nṣe, ki awa le ri, ki a si gbà ọ gbọ́? Iṣẹ kini iwọ ṣe?


Nigbati nwọn si mu wọn duro li ãrin, nwọn bère pe, Agbara tabi orukọ wo li ẹnyin fi ṣe eyi?


Wipe, Awa kò ti kìlọ fun nyin gidigidi pe, ki ẹ maṣe fi orukọ yi kọ́ni mọ́? si wo o, ẹnyin ti fi ẹkọ́ nyin kún Jerusalemu, ẹ si npete ati mu ẹ̀jẹ ọkunrin yi wá si ori wa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan