Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 2:16 - Bibeli Mimọ

16 O si wi fun awọn ti ntà àdaba pe, Ẹ gbe nkan wọnyi kuro nihin; ẹ máṣe sọ ile Baba mi di ile ọjà tità.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

16 Ó sọ fún àwọn tí ń ta ẹyẹlé pé, “Ẹ gbé gbogbo nǹkan wọnyi kúrò níhìn-ín, ẹ má ṣe sọ ilé Baba mi di ilé ìtajà!”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 Ó sì wí fún àwọn tí ń ta àdàbà pé, “Ẹ gbé nǹkan wọ̀nyí kúrò níhìn-ín; ẹ má ṣe sọ ilé Baba mi di ilé ọjà títà.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 2:16
17 Iomraidhean Croise  

Ile yi, ti ẹ fi orukọ mi pè, o ha di iho olè li oju nyin? sa wò o, emi tikarami ti ri i, li Oluwa wi.


Jesu si wọ̀ inu tẹmpili Ọlọrun lọ, o si lé gbogbo awọn ẹniti ntà, ati awọn ti nrà ni tẹmpili jade, o si yi tabili awọn onipaṣiparọ owo danù, ati ijoko awọn ti ntà ẹiyẹle.


O si wi fun wọn pe, A ti kọ ọ pe, Ile adura li a ó ma pè ile mi; ṣugbọn ẹnyin sọ ọ di ihò ọlọṣà.


Ṣugbọn nwọn ko fi pè nkan, nwọn ba tiwọn lọ, ọkan si ọ̀na oko rẹ̀, omiran si ọ̀na òwò rẹ̀:


O si nkọ́ni, o nwi fun wọn pe, A ko ti kọwe rẹ̀ pe, Ile adura fun gbogbo orilẹ-ède li a o ma pè ile mi? ṣugbọn ẹnyin ti ṣọ di ihò awọn ọlọsà.


O si dahùn wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nwá mi kiri? ẹnyin kò mọ pe, emi kò le ṣàima wà nibi iṣẹ Baba mi?


Baba mi, ẹniti o fi wọn fun mi, pọ̀ ju gbogbo wọn lọ; kò si si ẹniti o le já wọn kuro li ọwọ́ Baba mi.


O si fi okùn tẹrẹ ṣe paṣan, o si lé gbogbo wọn jade kuro ninu tẹmpili, ati agutan ati malu; o si dà owo awọn onipaṣipàrọ owo nù, o si bì tabili wọn ṣubu.


Jesu wi fun u pe, Máṣe fi ọwọ́ kàn mi; nitoriti emi kò ti igòke lọ sọdọ Baba mi: ṣugbọn lọ sọdọ awọn arakunrin mi, si wi fun wọn pe, Emi ngòke lọ sọdọ Baba mi, ati Baba nyin; ati sọdọ Ọlọrun mi, ati Ọlọrun nyin.


Ṣugbọn Jesu da wọn lohùn wipe, Baba mi nṣiṣẹ titi di isisiyi, emi si nṣiṣẹ.


Jesu dahùn wipe, Emi kò li ẹmi èṣu; ṣugbọn emi mbọlá fun Baba mi, ẹnyin kò si bọla fun mi.


Ọ̀rọ̀ ayipo awọn enia ọlọkan ẽri ti kò si otitọ ninu wọn, ti nwọn ṣebi ọna si ere ni ìwa-bi-Ọlọrun: yẹra lọdọ irú awọn wọnni.


Ati ninu ojukòkoro ni nwọn o mã fi nyin ṣe ere jẹ nipa ọrọ ẹtàn: idajọ ẹniti kò falẹ̀ lati ọjọ ìwa, ìparun wọn kò si tõgbé.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan