Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 2:15 - Bibeli Mimọ

15 O si fi okùn tẹrẹ ṣe paṣan, o si lé gbogbo wọn jade kuro ninu tẹmpili, ati agutan ati malu; o si dà owo awọn onipaṣipàrọ owo nù, o si bì tabili wọn ṣubu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

15 Jesu bá fi okùn kan ṣe ẹgba, ó bẹ̀rẹ̀ sí lé gbogbo wọn jáde kúrò ninu àgbàlá Ilé Ìrúbọ. Ó lé àwọn tí ń ta aguntan ati mààlúù jáde. Ó da gbogbo owó àwọn onípàṣípààrọ̀ nù, ó sì ti tabili wọn ṣubú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

15 Ó sì fi okùn tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe pàṣán, ó sì lé gbogbo wọn jáde kúrò nínú tẹmpili, àti àgùntàn àti màlúù; ó sì da owó àwọn onípàṣípàrọ̀ owó nù, ó si ti tábìlì wọn ṣubú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 2:15
7 Iomraidhean Croise  

O si dahùn o si wi fun mi pe, Eyi ni ọ̀rọ Oluwa si Serubbabeli wipe, Kì iṣe nipa ipá, kì iṣe nipa agbara, bikoṣe nipa Ẹmi mi, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.


Jesu si wọ̀ inu tẹmpili Ọlọrun lọ, o si lé gbogbo awọn ẹniti ntà, ati awọn ti nrà ni tẹmpili jade, o si yi tabili awọn onipaṣiparọ owo danù, ati ijoko awọn ti ntà ẹiyẹle.


Nitorina bi o ti wi fun wọn pe, Emi niyi, nwọn bi sẹhin, nwọn si ṣubu lulẹ.


O si ri awọn ti ntà malu, ati agutan, ati àdaba ni tẹmpili, ati awọn onipaṣipàrọ owo joko:


O si wi fun awọn ti ntà àdaba pe, Ẹ gbe nkan wọnyi kuro nihin; ẹ máṣe sọ ile Baba mi di ile ọjà tità.


Nigbana li awọn ọmọ-ogun ke okùn igbaja, nwọn jọwọ rẹ̀ ki o ṣubu sọhún.


(Nitori ohun ija wa kì iṣe ti ara, ṣugbọn o li agbara ninu Ọlọrun lati wó ibi giga palẹ;)


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan