Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 2:10 - Bibeli Mimọ

10 O si wi fun u pe, Olukuluku enia a mã kọ́ gbé waini rere kalẹ; nigbati awọn enia ba si mu yó tan, nigbana ni imu eyi ti kò dara tobẹ̃ wá: ṣugbọn iwọ ti pa waini daradara yi mọ́ titi o fi di isisiyi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

10 Ó ní, “Ọtí tí ó bá dùn ni gbogbo eniyan kọ́ ń gbé kalẹ̀. Nígbà tí àwọn eniyan bá ti mu ọtí yó tán, wọn á wá gbé ọtí èyí tí kò dára tóbẹ́ẹ̀ wá. Ṣugbọn ìwọ fi àtàtà ọtí yìí pamọ́ di àkókò yìí!”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Ó sì wí fún un pé, “Olúkúlùkù a máa kọ́kọ́ gbé wáìnì tí ó dára jùlọ kalẹ̀; nígbà tí àwọn ènìyàn bá sì mu ún yó tan, nígbà náà ní wọn a mú èyí tí kò dára tó bẹ́ẹ̀ wá; ṣùgbọ́n ìwọ ti pa wáìnì dáradára yìí mọ́ títí ó fi di ìsinsin yìí.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 2:10
15 Iomraidhean Croise  

O si bù onjẹ fun wọn lati iwaju rẹ̀ lọ: ṣugbọn onjẹ Benjamini jù ti ẹnikẹni wọn lẹrinmarun. Nwọn si mu, nwọn si bá a ṣe ariya.


Ati ọti-waini ti imu inu enia dùn, ati oróro ti imu oju rẹ̀ dan, ati onjẹ ti imu enia li aiya le.


MO de inu ọgbà mi, arabinrin mi, iyawo! mo ti kó ojia mi pẹlu õrùn didùn mi jọ; mo ti jẹ afara mi pẹlu oyin mi; mo ti mu ọti-waini mi pẹlu wàra mi: Ẹ jẹun, ẹnyin ọrẹ́; mu, ani mu amuyo, ẹnyin olufẹ.


Ti o si bẹ̀rẹ si ilù awọn ọmọ-ọdọ ẹlẹgbẹ rẹ̀, ati si ijẹ ati si imu pẹlu awọn ọ̀muti;


Ṣugbọn bi ọmọ-ọdọ na ba wi li ọkàn rẹ̀ pe, Oluwa mi yẹ̀ igba atibọ̀ rẹ̀; ti o si bẹ̀rẹ si ilù awọn iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin, ti o si bẹ̀rẹ si ijẹ ati si imu amupara;


Ṣugbọn Abrahamu wipe, Ọmọ, ranti pe, nigba aiye rẹ, iwọ ti gbà ohun rere tirẹ, ati Lasaru ohun buburu: ṣugbọn nisisiyi ara rọ̀ ọ, iwọ si njoro.


Nitori awọn wọnyi kò mutiyó, bi ẹnyin ti fi pè; wakati kẹta ọjọ sá li eyi.


Nitoripe nigbati ẹnyin ba njẹun, olukuluku nkọ́ jẹ onjẹ tirẹ̀, ebi a si mã pa ẹnikan, ọti a si mã pa ẹnikeji.


Ẹ má si ṣe mu waini li amupara, ninu eyiti rudurudu wà; ṣugbọn ẹ kún fun Ẹmí;


Nitori awọn ti nsùn, ama sùn li oru; ati awọn ti nmutipara, ama mutipara li oru.


Ẹniti awọn ọba aiye ba ṣe àgbere, ti a si ti fi ọti-waini àgbere rẹ̀ pa awọn ti ngbe inu aiye.


Mo si ri obinrin na mu ẹ̀jẹ awọn enia mimọ́, ati ẹ̀jẹ awọn ajẹrikú Jesu li amuyo: nigbati mo si ri i, ẹnu yà mi gidigidi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan