Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 19:4 - Bibeli Mimọ

4 Pilatu si tún jade, o si wi fun wọn pe, Wo o, mo mu u jade tọ̀ nyin wá, ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe, emi kò ri ẹ̀ṣẹ kan lọwọ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 Pilatu tún jáde lọ sóde, ó sọ fún àwọn Juu pé, “Mò ń mú un tọ̀ yín bọ̀ wá sóde, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi kò rí i pé ó jẹ̀bi ohunkohun.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Pilatu sì tún jáde, ó sì wí fún wọn pé, “Wò ó, mo mú u jáde tọ̀ yín wá, kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé, èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ rẹ̀.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 19:4
16 Iomraidhean Croise  

Nigbati o si joko lori itẹ́ idajọ, aya rẹ̀ ransẹ si i, wipe, Máṣe li ọwọ́ ninu ọ̀ran ọkunrin olododo nì: nitori ìyà ohun pipọ ni mo jẹ li oju àlá loni nitori rẹ̀.


Nigbati Pilatu ri pe, on ko le bori li ohunkohun, ṣugbọn pe a kuku sọ gbogbo rẹ̀ di ariwo, o bu omi, o si wẹ̀ ọwọ́ rẹ̀ li oju ijọ, o wipe, Ọrùn mi mọ́ kuro ninu ẹ̀jẹ enia olõtọ yi: ẹ mã bojuto o.


O wipe, emi ṣẹ̀ li eyiti mo fi ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ hàn. Nwọn si wipe, Kò kàn wa, mã bojuto o.


Nigbati balogun ọrún, ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀, ti nwọn nṣọ́ Jesu, ri isẹlẹ na, ati ohun wọnni ti ó ṣẹ̀, èru ba wọn gidigidi, nwọn wipe, Lõtọ Ọmọ Ọlọrun li eyi iṣe.


Pilatu si wi fun awọn olori alufa ati fun ijọ enia pe, Emi kò ri ẹ̀ṣẹ lọwọ ọkunrin yi.


Niti wa, nwọn jare nitori ère ohun ti a ṣe li awa njẹ: ṣugbọn ọkunrin yi kò ṣe ohun buburu kan.


Nigbati balogun ọrún ri ohun ti o ṣe, o yìn Ọlọrun logo, wipe, Dajudaju olododo li ọkunrin yi.


Nitorina Pilatu tún wọ̀ inu gbọ̀ngan idajọ lọ, o si pè Jesu, o si wi fun u pe, Ọba awọn Ju ni iwọ iṣe?


Pilatu wi fun u pe, Kili otitọ? Nigbati o si ti wi eyi tan, o tún jade tọ̀ awọn Ju lọ, o si wi fun wọn pe, Emi kò ri ẹ̀ṣẹ kan lọwọ rẹ̀.


Nitorina nigbati awọn olori alufa, ati awọn onṣẹ ri i, nwọn kigbe wipe, Kàn a mọ agbelebu, kàn a mọ agbelebu. Pilatu wi fun wọn pe, Ẹ mu u fun ara nyin, ki ẹ si kàn a mọ agbelebu: nitoriti emi ko ri ẹ̀ṣẹ lọwọ rẹ̀.


Nitori o ti fi i ṣe ẹ̀ṣẹ nitori wa, ẹniti kò mọ̀ ẹ̀ṣẹkẹṣẹ rí; ki awa le di ododo Ọlọrun ninu rẹ̀.


Nitoripe irú Olori Alufa bẹ̃ li o yẹ wa, mimọ́, ailẹgan, ailẽri, ti a yà si ọ̀tọ kuro ninu ẹlẹṣẹ, ti a si gbéga jù awọn ọrun lọ;


Bikoṣe ẹ̀jẹ iyebiye, bi ti ọdọ-agutan ti kò li abuku, ti kò si li abawọn, ani ẹ̀jẹ Kristi;


Ẹniti kò dẹṣẹ̀, bẹni a kò si ri arekereke lì ẹnu rẹ̀:


Nitoriti Kristi pẹlu jìya lẹ̃kan nitori ẹ̀ṣẹ wa, olõtọ fun awọn alaiṣõtọ, ki o le mu wa de ọdọ Ọlọrun, ẹniti a pa ninu ara, ṣugbọn ti a sọ di ãye ninu ẹmí:


Ẹnyin si mọ̀ pe, on farahàn lati mu ẹ̀ṣẹ kuro; ẹ̀ṣẹ kò si si ninu rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan