Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 19:11 - Bibeli Mimọ

11 Jesu da a lohun pe, Iwọ kì ba ti li agbara kan lori mi, bikoṣepe a fi i fun ọ lati oke wá: nitorina ẹniti o fi mi le ọ lọwọ li o ni ẹ̀ṣẹ pọ̀ju.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

11 Jesu dá a lóhùn pé, “O kò ní àṣẹ lórí mi àfi èyí tí a ti fi fún ọ láti òkè wá. Nítorí náà, ẹni tí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ pọ̀jù ni ẹni tí ó fà mí lé ọ lọ́wọ́.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 Jesu dá a lóhùn pé, “Ìwọ kì bá tí ní agbára kan lórí mi, bí kò ṣe pé a fi í fún ọ láti òkè wá: nítorí náà ẹni tí ó fi mí lé ọ lọ́wọ́ ni ó ní ẹ̀ṣẹ̀ pọ̀jù.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 19:11
37 Iomraidhean Croise  

Tirẹ Oluwa ni titobi, ati agbara, ati ogo, ati iṣẹgun, ati ọlá-nla: nitori ohun gbogbo li ọrun ati li aiye tirẹ ni; ijọba ni tirẹ, Oluwa, a si gbé ọ leke li ori fun ohun gbogbo.


Mo yadi, emi kò ya ẹnu mi; nitoripe iwọ li o ṣe e.


Ọlọrun ti sọ̀rọ lẹ̃kan; lẹ̃rinkeji ni mo gbọ́ eyi pe: ti Ọlọrun li agbara.


Tali ẹniti iwi, ti isi iṣẹ, nigbati Oluwa kò paṣẹ rẹ̀.


Nipa ọ̀rọ lati ọdọ awọn oluṣọ li ọ̀ran yi, ati aṣẹ nipa ọ̀rọ awọn ẹni mimọ́ nì; nitori ki awọn alàye ki o le mọ̀ pe Ọga-ogo li o nṣe olori ni ijọba enia, on a si fi fun ẹnikẹni ti o wù u, on a si gbé onirẹlẹ julọ leke lori rẹ̀.


Nwọn o le ọ kuro larin enia, ibugbe rẹ yio si wà pẹlu awọn ẹranko igbẹ nwọn o si mu ki iwọ ki o jẹ koriko bi malu, nwọn o si mu ki iri ọrun sẹ̀ si ọ lara, igba meje yio si kọja lori rẹ, titi iwọ o fi mọ̀ pe Ọga-ogo ni iṣe olori ni ijọba enia, on a si fi i fun ẹnikẹni ti o wù u.


A o si le ọ kuro larin enia, ibugbe rẹ yio si wà pẹlu awọn ẹranko igbẹ: nwọn o si mu ọ jẹ koriko bi malu, igba meje yio si kọja lori rẹ, titi iwọ o fi mọ̀ pe, Ọga-ogo ni iṣe olori ninu ijọba enia, on a si fi i fun ẹnikẹni ti o wù u.


Gbogbo awọn araiye li a si kà si bi ohun asan, on a si ma ṣe gẹgẹ bi o ti wù u ninu ogun ọrun, ati larin awọn araiye: kò si si ẹniti idá ọwọ rẹ̀ duro, tabi ẹniti iwi fun u pe, Kini iwọ nṣe nì?


A si le e kuro lãrin awọn ọmọ enia; a si ṣe aiya rẹ̀ dabi ti ẹranko, ibugbe rẹ̀ si wà lọdọ awọn kẹtẹkẹtẹ igbẹ; nwọn si fi koriko bọ́ ọ gẹgẹ bi malu, a si mu ki ìri ọrun sẹ̀ si i lara; titi on fi mọ̀ pe Ọlọrun Ọga-ogo ni iṣe alakoso ninu ijọba enia, on a si yàn ẹnikẹni ti o wù u ṣe olori rẹ̀.


Nigbana li olori alufa fà aṣọ rẹ̀ ya, o wipe, O sọ ọrọ-odi; ẹlẹri kili a si nwá? wo o, ẹnyin gbọ́ ọrọ-odi na nisisiyi.


Nigbati nwọn si dè e tan, nwọn mu u lọ, nwọn si fi i le Pontiu Pilatu lọwọ ti iṣe Bãlẹ.


Má si fà wa sinu idẹwò, ṣugbọn gbà wa lọwọ bilisi. Nitori ijọba ni tirẹ, ati agbara, ati ogo, lailai. Amin.


Ẹniti o si fi i hàn ti fi àmi fun wọn, wipe, Ẹnikẹni ti mo ba fi ẹnu kò li ẹnu, on na ni; ẹ mu u, ki ẹ si ma fà a lọ li alafia.


Nigbati emi wà pẹlu nyin lojojumọ ni tẹmpili, ẹnyin ko nà ọwọ́ mu mi: ṣugbọn akokò ti nyin li eyi, ati agbara òkunkun.


Nwọn kọ́ fa a lọ sọdọ Anna; nitori on ni iṣe ana Kaiafa, ẹniti iṣe olori alufa li ọdún na.


Nigbana ni Judasi, lẹhin ti o ti gbà ẹgbẹ ọmọ-ogun, ati awọn onṣẹ́ lati ọdọ awọn olori alufa ati awọn Farisi, wá sibẹ̀ ti awọn ti fitilà ati òguṣọ̀, ati ohun ijà.


Nitorina Pilatu wi fun u pe, Emi ni iwọ ko fọhun si? iwọ kò mọ̀ pe, emi li agbara lati dá ọ silẹ, emi si li agbara lati kàn ọ mọ agbelebu?


Johanu dahùn o si wipe, Enia ko le ri nkankan gbà, bikoṣepe a ba ti fifun u lati ọrun wá.


Nitorina nwọn nwá ọ̀na ati mú u: ṣugbọn kò si ẹnikan ti o gbé ọwọ́ le e, nitoriti wakati rẹ̀ kò ti ide.


Jesu wi fun wọn pe, Ibaṣepe ẹnyin fọju, ẹnyin kì ba ti li ẹ̀ṣẹ: ṣugbọn nisisiyi ẹnyin wipe, Awa riran; nitorina ẹ̀ṣẹ nyin wà sibẹ̀.


Ẹniti a ti fi le nyin lọwọ nipa ipinnu ìmọ ati imọtẹlẹ Ọlọrun; on li ẹnyin mu, ti ẹ ti ọwọ awọn enia buburu kàn mọ agbelebu, ti ẹ si pa.


Ọlọrun Abrahamu, ati ti Isaaki, ati ti Jakọbu, Ọlọrun awọn baba wa, on li o ti yìn Jesu Ọmọ rẹ̀ logo; ẹniti ẹnyin ti fi le wọn lọwọ, ti ẹnyin si sẹ́ niwaju Pilatu, nigbati o ti pinnu rẹ̀ lati da a silẹ.


Lati ṣe ohunkohun ti ọwọ́ rẹ ati imọ rẹ ti pinnu ṣaju pe yio ṣẹ.


Nitori lati ọdọ rẹ̀, ati nipa rẹ̀, ati fun u li ohun gbogbo: ẹniti ogo wà fun lailai. Amin.


KI olukuluku ọkàn ki o foribalẹ fun awọn alaṣẹ ti o wà ni ipo giga. Nitori kò si aṣẹ kan, bikoṣe lati ọdọ Ọlọrun wá: awọn alaṣẹ ti o si wà, lati ọdọ Ọlọrun li a ti làna rẹ̀ wá.


Gbogbo ẹ̀bun rere ati gbogbo ẹ̀bun pipé lati oke li o ti wá, o si nsọkalẹ lati ọdọ Baba imọlẹ wá, lọdọ Ẹniti kò le si iyipada tabi ojiji àyida.


Nitorina ẹniti o ba mọ̀ rere iṣe ti kò si ṣe, ẹ̀ṣẹ ni fun u.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan