Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 18:4 - Bibeli Mimọ

4 Nitorina bi Jesu ti mọ̀ ohun gbogbo ti mbọ̀ wá ba on, o jade lọ, o si wi fun wọn pe, Tali ẹ nwá?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 Nígbà tí Jesu rí ohun gbogbo tí yóo ṣẹlẹ̀ sí òun, ó jáde lọ pàdé wọn, ó bi wọ́n pé, “Ta ni ẹ̀ ń wá?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Nítorí náà bí Jesu ti mọ ohun gbogbo tí ń bọ̀ wá bá òun, ó jáde lọ, ó sì wí fún wọn pé, “Ta ni ẹyin ń wá?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 18:4
27 Iomraidhean Croise  

Bi Oluwa Ọlọrun rẹ ti wà, kò si orilẹ-ède tabi ijọba kan, nibiti oluwa mi kò ranṣẹ de lati wò ọ: nigbati nwọn ba si wipe, Kò si; on a mu ki ijọba tabi orilẹ-ède na bura pe: awọn kò ri ọ.


Mo si wipe, Enia bi emi a ma sa? Tali o si dabi emi, ti o jẹ wọ inu tempili lọ lati gba ẹmi rẹ̀ là? Emi kì yio wọ̀ ọ lọ.


Bi ogun tilẹ dótì mi, aiya mi kì yio fò: bi ogun tilẹ dide si mi, ninu eyi li ọkàn mi yio le.


Emi kì yio bẹ̀ru ọ̀pọlọpọ enia, ti nwọn rọ̀gba yi mi ka.


ENIA buburu sá nigbati ẹnikan kò le e: ṣugbọn olododo laiya bi kiniun.


Lati igbana lọ ni Jesu ti bẹ̀rẹ si ifihàn awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, bi on ko ti le ṣailọ si Jerusalemu, lati jẹ ọ̀pọ ìya lọwọ awọn àgbagbà ati awọn olori alufa, ati awọn akọwe, ki a si pa on, ati ni ijọ kẹta, ki o si jinde.


Ẹnyin mọ̀ pe lẹhin ọjọ meji ni ajọ irekọja, a o si fi Ọmọ-enia le ni lọwọ, lati kàn a mọ agbelebu.


Bi nwọn si ti njẹun, o wipe, Lõtọ, ni mo wi fun nyin, ọkan ninu nyin yio fi mi hàn.


Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Gbogbo nyin ni yio kọsẹ̀ lara mi li oru yi: nitoriti a ti kọwe rẹ̀ pe, Emi o kọlù oluṣọ-agutan, a o si tú agbo agutan na ká kiri.


O si wi fun wọn pe, Nwọnyi li ọrọ ti mo sọ fun nyin, nigbati emi ti wà pẹlu nyin pe, A kò le ṣe alaimu ohun gbogbo ṣẹ, ti a ti kọ ninu ofin Mose, ati ninu iwe awọn woli, ati ninu Psalmu, nipasẹ̀ mi.


NJE ki ajọ irekọja ki o to de, nigbati Jesu mọ̀ pe wakati rẹ̀ de tan, ti on ó ti aiye yi kuro lọ sọdọ Baba, fifẹ ti o fẹ awọn tirẹ̀ ti o wà li aiye, o fẹ wọn titi de opin.


Nitoriti o mọ̀ ẹniti yio fi on hàn; nitorina li o ṣe wipe, Kì iṣe gbogbo nyin li o mọ́.


Nwọn si da a lohùn wipe, Jesu ti Nasareti. Jesu si wi fun wọn pe, Emi niyi. Ati Judasi pẹlu, ẹniti o fi i hàn, duro pẹlu wọn.


Nitorina o tún bi wọn lẽre, wipe, Tali ẹ nwá? Nwọn si wipe, Jesu ti Nasareti.


Lẹhin eyi, bi Jesu ti mọ̀ pe, a ti pari ohun gbogbo tan, ki iwe-mimọ́ le ba ṣẹ, o wipe, Orungbẹ ngbẹ mi.


Ṣugbọn awọn kan wà ninu nyin ti kò gbagbọ́. Nitori Jesu mọ̀ lati ìbẹrẹ wá ẹniti nwọn iṣe ti ko gbagbọ́, ati ẹniti yio fi on hàn.


Iwọ mu mi mọ̀ ọ̀na iye; iwọ ó mu mi kún fun ayọ̀ ni iwaju rẹ.


NJẸ bi Kristi ti jìya fun wa nipa ti ara, irú inu kanna ni ki ẹnyin fi hamọra: nitori ẹniti o ba ti jìya nipa ti ara, o ti bọ́ lọwọ ẹ̀ṣẹ;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan