Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 18:3 - Bibeli Mimọ

3 Nigbana ni Judasi, lẹhin ti o ti gbà ẹgbẹ ọmọ-ogun, ati awọn onṣẹ́ lati ọdọ awọn olori alufa ati awọn Farisi, wá sibẹ̀ ti awọn ti fitilà ati òguṣọ̀, ati ohun ijà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Judasi bá mú àwọn ọmọ-ogun ati àwọn ẹ̀ṣọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi, wọ́n wá sibẹ pẹlu ògùṣọ̀ ati àtùpà ati àwọn ohun ìjà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Nígbà náà ni Judasi, lẹ́yìn tí ó ti gba ẹgbẹ́ ọmọ-ogun, àti àwọn oníṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi wá síbẹ̀ ti àwọn ti fìtílà àti ògùṣọ̀, àti ohun ìjà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 18:3
15 Iomraidhean Croise  

Akọ-malu pipọ̀ li o yi mi ka: malu Baṣani ti o lagbara rọ̀gba yi mi ka.


NIGBANA li a o fi ijọba ọrun wé awọn wundia mẹwa, ti o mu fitila wọn, ti nwọn si jade lọ ipade ọkọ iyawo.


Bi nwọn si ti njẹ onjẹ alẹ, ti Èṣu ti fi i si ọkàn Judasi Iskariotu ọmọ Simoni lati fi i hàn;


Nigbana li ẹgbẹ ọmọ-ogun, ati olori ẹṣọ́, ati awọn onṣẹ awọn Ju mu Jesu, nwọn si dè e.


Awọn ọmọ-ọdọ ati awọn onṣẹ si duro nibẹ̀, awọn ẹniti o ti daná ẹyín; nitori otutù mu, nwọn si nyána: Peteru si duro pẹlu wọn, o nyána.


Bi o si ti wi eyi tan, ọkan ninu awọn onṣẹ ti o duro tì i fi ọwọ́ rẹ̀ lù Jesu, wipe, Olori alufa ni iwọ nda lohùn bẹ̃?


Nitorina nigbati awọn olori alufa, ati awọn onṣẹ ri i, nwọn kigbe wipe, Kàn a mọ agbelebu, kàn a mọ agbelebu. Pilatu wi fun wọn pe, Ẹ mu u fun ara nyin, ki ẹ si kàn a mọ agbelebu: nitoriti emi ko ri ẹ̀ṣẹ lọwọ rẹ̀.


Awọn Farisi gbọ́ pe, ijọ enia nsọ nkan wọnyi labẹlẹ̀ nipa rẹ̀; awọn Farisi ati awọn olori alufã si rán awọn onṣẹ lọ lati mu u.


Ẹnyin ará, Iwe-mimọ́ kò le ṣe ki o má ṣẹ, ti Ẹmi Mimọ́ ti sọtẹlẹ lati ẹnu Dafidi niti Judasi, ti o ṣe amọ̀na fun awọn ti o mu Jesu.


ỌKUNRIN kan si wà ni Kesarea ti a npè ni Korneliu, balogun ọrún ti ẹgbẹ́ ọmọ-ogun ti a npè ni ti Itali,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan