Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 18:18 - Bibeli Mimọ

18 Awọn ọmọ-ọdọ ati awọn onṣẹ si duro nibẹ̀, awọn ẹniti o ti daná ẹyín; nitori otutù mu, nwọn si nyána: Peteru si duro pẹlu wọn, o nyána.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

18 Àwọn ẹrú ati àwọn ẹ̀ṣọ́ jọ dúró ní àgbàlá, wọ́n ń yáná tí wọ́n fi èédú dá, nítorí òtútù mú. Peteru náà dúró lọ́dọ̀ wọn, òun náà ń yáná.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

18 Àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ àti àwọn aláṣẹ sì dúró níbẹ̀, àwọn ẹni tí ó ti dáná nítorí ti òtútù mú, wọ́n sì ń yáná: Peteru sì dúró pẹ̀lú wọn, ó ń yáná.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 18:18
16 Iomraidhean Croise  

Ọkàn mi, iwọ máṣe wọ̀ ìmọ wọn; ninu ajọ wọn, ọlá mi, máṣe bá wọn dàpọ; nitoripe, ni ibinu wọn nwọn pa ọkunrin kan, ati ni girimakayi wọn, nwọn já malu ni patì.


O si de ibẹ̀, si ibi ihò okuta, o si wọ̀ sibẹ, si kiyesi i, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ ọ wá, o si wi fun u pe, Kini iwọ nṣe nihinyi, Elijah?


IBUKÚN ni fun ọkunrin na ti kò rìn ni ìmọ awọn enia buburu, ti kò duro li ọ̀na awọn ẹlẹṣẹ, ati ti kò si joko ni ibujoko awọn ẹlẹgàn.


Ẹniti o mba ọlọgbọ́n rìn yio gbọ́n; ṣugbọn ẹgbẹ awọn aṣiwere ni yio ṣegbe.


Peteru si tọ̀ ọ lẹhin li òkere wọ̀ inu ile, titi fi de agbala olori alufa; o si bá awọn ọmọ-ọdọ joko, o si nyána.


Nigbati o si ri ti Peteru nyána, o wò o, o si wipe, Iwọ pẹlu ti wà pẹlu Jesu ti Nasareti.


Bi o si ti wà ni iwaya-ija o ngbadura si i kikankikan: õgùn rẹ̀ si dabi iro ẹ̀jẹ nla, o nkán silẹ.


Ṣugbọn Simoni Peteru duro, o si nyána. Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Iwọ pẹlu ha ṣe ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀? O si sẹ́, o si wipe, Emi kọ́.


Nigbana ni Judasi, lẹhin ti o ti gbà ẹgbẹ ọmọ-ogun, ati awọn onṣẹ́ lati ọdọ awọn olori alufa ati awọn Farisi, wá sibẹ̀ ti awọn ti fitilà ati òguṣọ̀, ati ohun ijà.


Nigbati nwọn gúnlẹ, nwọn ri iná ẹyín nibẹ, ati ẹja lori rẹ̀, ati akara.


Nigbati nwọn si jọwọ wọn lọwọ lọ, nwọn lọ sọdọ awọn ẹgbẹ wọn, nwọn si ròhin ohun gbogbo ti awọn olori alufa ati awọn agbàgba sọ fun wọn.


Ki a má tàn nyin jẹ: ẹgbẹ́ buburu bà ìwa rere jẹ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan