Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 18:1 - Bibeli Mimọ

1 NIGBATI Jesu si ti sọ nkan wọnyi tan, o jade pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lọ soke odò Kedroni, nibiti agbala kan wà, ninu eyi ti o wọ̀, on ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Lẹ́yìn tí Jesu ti gba adura yìí tán, òun ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jáde lọ sí òdìkejì àfonífojì odò Kidironi. Ọgbà kan wà níbẹ̀. Ó wọ inú ọgbà náà, òun ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Nígbà tí Jesu sì ti sọ nǹkan wọ̀nyí tán, ó jáde pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sókè odò Kidironi, níbi tí àgbàlá kan wà, nínú èyí tí ó wọ̀, Òun àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 18:1
25 Iomraidhean Croise  

OLUWA Ọlọrun si mu ọkunrin na, o si fi i sinu ọgbà Edeni lati ma ro o, ati lati ma ṣọ́ ọ.


Nitorina OLUWA Ọlọrun lé e jade kuro ninu ọgbà Edeni, lati ma ro ilẹ ninu eyiti a ti mu u jade wá.


Gbogbo ilu na si fi ohùn rara sọkun, gbogbo enia si rekọja; ọba si rekọja odo Kidroni, gbogbo awọn enia na si rekọja, si ihà ọ̀na iju.


Ati Maaka iya rẹ̀ papã, li o si mu kuro lati ma ṣe ayaba, nitori ti o yá ere kan fun oriṣa rẹ̀; Asa si ke ere na kuro; o si daná sun u nibi odò Kidroni.


Yio si ṣe li ọjọ ti iwọ ba jade, ti iwọ ba si kọja odò Kidroni, ki iwọ mọ̀ dajudaju pe, Kikú ni iwọ o kú; ẹ̀jẹ rẹ yio wà lori ara rẹ.


Ati pẹpẹ wọnni ti mbẹ lori iyara òke Ahasi, ti awọn ọba Juda ti tẹ́, ati pẹpẹ wọnni ti Manasse ti tẹ́ li ãfin mejeji ile Oluwa ni ọba wó lulẹ, o si yara lati ibẹ, o si da ekuru wọn sinu odò Kidroni.


Ọba si paṣẹ fun Hilkiah olori alufa, ati awọn alufa ẹgbẹ keji, ati awọn alabojuto iloro, lati kó gbogbo ohun-èlo ti a ṣe fun Baali, ati fun ere òriṣa, ati fun gbogbo ogun ọrun jade kuro ni tempili Oluwa: o si sun wọn lẹhin ode Jerusalemu ninu pápa Kidroni, o si kó ẽru wọn lọ si Beteli.


O si gbé ere-oriṣa jade kuro ni ile Oluwa, sẹhin ode Jerusalemu lọ si odò Kidroni, o si sun u nibi odò Kidroni, o si lọ̀ ọ lũlu, o si dà ẽrú rẹ̀ sori isà-okú awọn ọmọ enia na.


Pẹlupẹlu Maaka, iya Asa, li ọba mu u kuro lati má ṣe ayaba, nitoriti o yá ere fun oriṣa rẹ̀: Asa si ké ere rẹ̀ lulẹ, o si tẹ̀ ẹ mọlẹ, o si sun u nibi odò Kidroni.


Awọn alufa si wọ inu ile Oluwa lọhun lọ, lati gbá a mọ́, nwọn si mu gbogbo ẽri ti nwọn ri ninu tempili Oluwa jade si inu agbala ile Oluwa. Awọn ọmọ Lefi si kó o, nwọn si rù u jade gbangba lọ si odò Kidroni.


Nwọn si dide, nwọn si kó gbogbo pẹpẹ ti o wà ni Jerusalemu lọ, ati gbogbo pẹpẹ turari ni nwọn kó lọ, nwọn si dà wọn si odò Kidroni.


Nigbana ni mo goke lọ li oru lẹba odò, mo si wò odi na: mo si yipada, mo si tún wọ̀ bode afonifoji, mo si yipada.


Ati gbogbo afonifoji okú, ati ti ẽru, ati gbogbo oko titi de odò Kidroni, titi de igun ẹnubode-ẹṣin niha ilà-õrun, ni yio jẹ mimọ́ fun Oluwa; a kì yio fà a tu, bẹ̃ni a kì yio si wó o lulẹ mọ lailai.


Ki iwọ ki o si dá a kelekele, ki o si dà oróro sori rẹ̀: ẹbọ ohunjijẹ ni.


Nigbati nwọn si kọ orin kan tan, nwọn jade lọ sori òke Olifi.


Nigbana ni Jesu bá wọn wá si ibi kan ti a npè ni Getsemane, o si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ joko nihinyi nigbati mo ba lọ igbadura lọhúnyi.


Nigbati nwọn si kọ orin kan tan, nwọn jade lọ sori òke Olifi.


Nwọn si wá si ibi kan ti a npè ni Getsemane: o si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ joko nihinyi, nigbati mo ba lọ igbadura.


Ẹ dide, ki a ma lọ; wo o, ẹniti o fi mi hàn sunmọ tosi.


Ṣugbọn nitori ki aiye le mọ̀ pe emi fẹràn Baba; gẹgẹ bi Baba si ti fi aṣẹ fun mi, bẹ̃ni emi nṣe. Ẹ dide, ẹ jẹ ki a lọ kuro nihinyi.


Ọkan ninu awọn ọmọ-ọdọ olori alufa, ti iṣe ibatan ẹniti Peteru ke etí rẹ̀ sọnù, wipe, Emi kò ha ri ọ pẹlu rẹ̀ li agbala?


Nigbati o si de ọdọ wa, o mu amure Paulu, o si de ara rẹ̀ li ọwọ́ on ẹsẹ, o si wipe, Bayi li Ẹmí Mimọ́ wi, Bayi li awọn Ju ti o wà ni Jerusalemu yio de ọkunrin ti o ni amure yi, nwọn o si fi i le awọn Keferi lọwọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan