Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 17:9 - Bibeli Mimọ

9 Emi ngbadura fun wọn: emi kò gbadura fun araiye, ṣugbọn fun awọn ti iwọ ti fifun mi; nitoripe tirẹ ni nwọn iṣe.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 “Àwọn ni mò ń gbadura fún, n kò gbadura fún aráyé; ṣugbọn mò ń gbadura fún àwọn tí o ti fún mi, nítorí tìrẹ ni wọ́n.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Èmi ń gbàdúrà fún wọn: èmi kò gbàdúrà fún aráyé, ṣùgbọ́n fún àwọn tí ìwọ ti fi fún mi; nítorí pé tìrẹ ni wọ́n í ṣe.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 17:9
17 Iomraidhean Croise  

Ṣugbọn mo ti gbadura fun ọ, ki igbagbọ́ rẹ ki o má yẹ̀; ati iwọ nigbati iwọ ba si yipada, mu awọn arakunrin rẹ li ọkàn le.


Jesu si wipe, Baba, darijì wọn; nitoriti nwọn kò mọ̀ ohun ti nwọn nṣe. Nwọn si pín aṣọ rẹ̀ lãrin ara wọn, nwọn di ìbo rẹ̀.


Nigbati awọn ti mbọ́ wọn ri ohun ti o ṣe, nwọn sá, nwọn si lọ, nwọn si ròhin ni ilu ati ni ilẹ na.


Emi ó si bère lọwọ Baba, on ó si fun nyin li Olutunu miran, ki o le mã ba nyin gbé titi lailai,


Gẹgẹ bi iwọ ti fun u li aṣẹ lori enia gbogbo, ki o le fi iye ainipẹkun fun gbogbo awọn ti o fifun u.


Kì si iṣe kìki awọn wọnyi ni mo ngbadura fun, ṣugbọn fun awọn pẹlu ti yio gbà mi gbọ́ nipa ọ̀rọ wọn;


Emi ti fi orukọ rẹ hàn fun awọn enia ti iwọ ti fifun mi lati inu aiye wá: tirẹ ni nwọn ti jẹ ri, iwọ si ti fi wọn fun mi; nwọn si ti pa ọ̀rọ rẹ mọ́.


Ohun gbogbo ti Baba fifun mi, yio tọ̀ mi wá; ẹniti o ba si tọ̀ mi wá, emi kì yio ta a nù, bi o ti wù ki o ri.


Eyi si ni ifẹ Baba ti o rán mi, pe ohun gbogbo ti o fifun mi, ki emi ki o máṣe sọ ọkan nù ninu wọn, ṣugbọn ki emi ki o le ji wọn dide nikẹhin ọjọ.


Nitorina o si le gba wọn là pẹlu titi de opin, ẹniti o ba tọ̀ Ọlọrun wá nipasẹ rẹ̀, nitoriti o mbẹ lãye titi lai lati mã bẹ̀bẹ fun wọn.


Nitori Kristi kò wọ̀ ibi mimọ́ ti a fi ọwọ́ ṣe lọ ti iṣe apẹrẹ ti otitọ; ṣugbọn o lọ si ọ̀run pãpã, nisisiyi lati farahan ni iwaju Ọlọrun fun wa:


Awa mọ̀ pe ti Ọlọrun ni wa, ati gbogbo aiye li o wa ni agbara ẹni buburu nì.


A si lé dragoni nla na jade, ejò lailai nì, ti a npè ni Èṣu, ati Satani, ti ntàn gbogbo aiye jẹ, a si lé e jù si ilẹ aiye, a si le awọn angẹli rẹ̀ jade pẹlu rẹ̀.


Gbogbo awọn ti ngbe ori ilẹ aiye yio si mã sin i, olukuluku ẹniti a kò kọ orukọ rẹ̀ sinu iwe iyè Ọdọ-Agutan ti a ti pa lati ipilẹṣẹ aiye.


Bi a ba si ri ẹnikẹni ti a kò kọ orukọ rẹ̀ sinu iwe ìye, a sọ ọ sinu adagun iná.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan