Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 16:16 - Bibeli Mimọ

16 Nigba diẹ, ẹnyin kì o si ri mi: ati nigba diẹ ẹ̀wẹ, ẹ ó si ri mi, nitoriti emi nlọ sọdọ Baba.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

16 “Láìpẹ́ ẹ kò ní rí mi mọ́. Lẹ́yìn náà, láìpẹ́ ẹ óo sì tún rí mi.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 “Nígbà díẹ̀, ẹ̀yin kì ó sì rí mi: àti nígbà díẹ̀ si, ẹ ó sì rí mi, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 16:16
19 Iomraidhean Croise  

Bẹ̃ni nigbati Oluwa si ti ba wọn sọ̀rọ tan, a si gbà a lọ soke ọrun, o si joko li ọwọ́ ọtún Ọlọrun.


Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Nigba diẹ si i ni imọlẹ wà lãrin nyin. Ẹ mã rìn nigbati ẹnyin ni imọlẹ, ki òkunkun máṣe ba le nyin: ẹniti o ba si nrìn li òkunkun kò mọ̀ ibiti on gbé nlọ.


Ti Jesu si ti mọ̀ pe Baba ti fi ohun gbogbo le on lọwọ, ati pe lọdọ Ọlọrun li on ti wá, on si nlọ sọdọ Ọlọrun;


Ẹnyin ọmọde, nigba diẹ si i li emi wà pẹlu nyin. Ẹnyin ó wá mi: ati gẹgẹ bi mo ti wi fun awọn Ju pe, Nibiti emi gbé nlọ, ẹnyin kì o le wá; bẹ̃ni mo si wi fun nyin nisisiyi.


Niti ododo, nitoriti emi nlọ sọdọ Baba, ẹnyin kò si ri mi mọ́;


Nitorina ẹnyin ni ibinujẹ nisisiyi: ṣugbọn emi o tún ri nyin, ọkàn nyin yio si yọ̀, kò si si ẹniti yio gbà ayọ̀ nyin lọwọ nyin.


Mo ti ọdọ Baba jade wá, mo si wá si aiye: ẹ̀wẹ, mo fi aiye silẹ, mo si nlọ sọdọ Baba.


Ṣugbọn nisisiyi emi nlọ sọdọ ẹniti o rán mi; kò si si ẹnikan ninu nyin ti o bi mi lẽre pe, Nibo ni iwọ nlọ?


Ṣugbọn nisisiyi emi si mbọ̀ wá sọdọ rẹ, nkan wọnyi ni mo si nsọ li aiye, ki nwọn ki o le ni ayọ̀ mi ni kikun ninu awọn tikarawọn.


Njẹ nisisiyi, Baba, ṣe mi logo pẹlu ara rẹ, ogo ti mo ti ní pẹlu rẹ ki aiye ki o to wà.


Nitorina Jesu wi fun wọn pe, Niwọn igba diẹ si i li emi wà pẹlu nyin, emi o si lọ sọdọ ẹniti o rán mi.


Awọn ẹniti o si farahàn fun lãye lẹhin ìjiya rẹ̀ nipa ẹ̀rí pupọ ti o daju, ẹniti a ri lọdọ wọn li ogoji ọjọ ti o nsọ ohun ti iṣe ti ijọba Ọlọrun:


Ki a mã wò Jesu olupilẹṣẹ ati alaṣepe igbagbọ́ wa; ẹni, nitori ayọ̀ ti a gbé ká iwaju rẹ̀, ti o farada agbelebu, laika itiju si, ti o si joko li ọwọ́ ọtún itẹ́ Ọlọrun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan