Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 16:11 - Bibeli Mimọ

11 Niti idajọ, nitoriti a ti ṣe idajọ alade aiye yi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

11 Wọ́n ṣìnà ní ti ìdájọ́ nítorí pé Ọlọrun ti dá aláṣẹ ayé yìí lẹ́bi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 Ní ti ìdájọ́, nítorí tí a ti ṣe ìdájọ́ ọmọ-aládé ayé yìí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 16:11
34 Iomraidhean Croise  

Emi o si fi ọta sãrin iwọ ati obinrin na, ati sãrin irú-ọmọ rẹ ati irú-ọmọ rẹ̀: on o fọ́ ọ li ori, iwọ o si pa a ni gigĩsẹ.


Iwọ ti gòke si ibi giga, iwọ ti di igbekun ni igbekun lọ: iwọ ti gbà ẹ̀bun fun enia: nitõtọ, fun awọn ọlọtẹ̀ pẹlu, ki Oluwa Ọlọrun ki o le ma ba wọn gbe.


Wo iranṣẹ mi, ẹniti mo yàn; ayanfẹ mi, ẹniti inu mi dùn si gidigidi: Emi o fi ẹmí mi fun u, yio si fi idajọ hàn fun awọn keferi.


Ṣugbọn mo wi fun nyin, gbogbo ọ̀rọ wère ti enia nsọ, nwọn o jihìn rẹ̀ li ọjọ idajọ.


O si wi fun wọn pe, Emi ri Satani ṣubu bi manamana lati ọrun wá.


Nisisiyi ni idajọ aiye yi de: nisisiyi li a o lé alade aiye yi jade.


Emi kì o ba nyin sọ̀rọ pipọ: nitori aladé aiye yi wá, kò si ni nkankan lọdọ mi.


Mo ni ohun pipọ lati sọ fun nyin pẹlu, ṣugbọn ẹ kò le gbà wọn nisisiyi.


O si paṣẹ fun wa lati wasu fun awọn enia, ati lati jẹri pe, on li a ti ọwọ Ọlọrun yàn ṣe Onidajọ ãye on okú.


Bi o si ti nsọ asọye nipa ti ododo ati airekọja ati idajọ ti mbọ̀, ẹ̀ru ba Feliksi, o dahùn wipe, Mã lọ nisisiyi na; nigbati mo ba si ni akokò ti o wọ̀, emi o ranṣẹ pè ọ.


Lati là wọn li oju, ki nwọn ki o le yipada kuro ninu òkunkun si imọlẹ, ati kuro lọwọ agbara Satani si Ọlọrun, ki nwọn ki o le gbà idariji ẹ̀ṣẹ, ati ogún pẹlu awọn ti a sọ di mimọ́ nipa igbagbọ ninu mi.


Ọlọrun alafia yio si tẹ̀ Satani mọlẹ li atẹlẹsẹ nyin ni lọ̃lọ. Ore-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa wa ki o wà pẹlu nyin. Amin.


Li ọjọ na nigbati Ọlọrun yio ti ipa Jesu Kristi ṣe idajọ aṣiri enia gẹgẹ bi ihinrere mi.


Nitorina, ẹ máṣe ṣe idajọ ohunkohun ṣaju akokò na, titi Oluwa yio fi de, ẹniti yio mu ohun òkunkun ti o farasin wá si imọlẹ, ti yio si fi ìmọ ọkàn hàn: nigbana li olukuluku yio si ni iyìn tirẹ̀ lọdọ Ọlọrun.


Ninu awọn ẹniti ọlọrun aiye yi ti sọ ọkàn awọn ti kò gbagbọ́ di afọju, ki imọlẹ ihinrere Kristi ti o logo, ẹniti iṣe aworan Ọlọrun, ki o máṣe mọlẹ ninu wọn.


Ninu eyiti ẹnyin ti nrin rí gẹgẹ bi ipa ti aiye yi, gẹgẹ bi alaṣẹ agbara oju ọrun, ẹmí ti nṣiṣẹ nisisiyi ninu awọn ọmọ alaigbọran:


O si ti já awọn ijọba ati agbara kuro li ara rẹ̀, o si ti dojuti wọn ni gbangba, o nyọ̀ ayọ̀ iṣẹgun lori wọn ninu rẹ̀.


Njẹ niwọn bi awọn ọmọ ti ṣe alabapin ara on ẹ̀jẹ, bẹ̃ gẹgẹ li on pẹlu si ṣe alabapin ninu ọkanna; ki o le ti ipa ikú pa ẹniti o ni agbara ikú run, eyini ni Eṣu;


Ati ti ẹkọ́ ti iwẹnu, ati ti igbọwọle-ni, ati ti ajinde okú, ati ti idajọ ainipẹkun.


Niwọn bi a si ti fi lelẹ fun gbogbo enia lati kú lẹ̃kanṣoṣo, ṣugbọn lẹhin eyi idajọ:


Ṣugbọn awọn ọrun ati aiye, ti mbẹ nisisiyi, nipa ọ̀rọ kanna li a ti tojọ bi iṣura fun iná, a pa wọn mọ́ dè ọjọ idajọ ati iparun awọn alaiwa-bi-Ọlọrun.


Ẹniti o ba ndẹṣẹ ti Èṣu ni; nitori lati àtetekọṣe ni Èṣu ti ndẹṣẹ. Nitori eyi li Ọmọ Ọlọrun ṣe farahàn, ki o le pa iṣẹ Èṣu run.


Kiyesi i, o mbọ̀ ninu awọsanma; gbogbo oju ni yio si ri i, ati awọn ti o gún u li ọ̀kọ pẹlu; ati gbogbo orilẹ-ede aiye ni yio si mã pohùnrere ẹkún niwaju rẹ̀. Bẹ̃na ni. Amin.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan