Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 16:10 - Bibeli Mimọ

10 Niti ododo, nitoriti emi nlọ sọdọ Baba, ẹnyin kò si ri mi mọ́;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

10 Wọ́n ṣìnà ní ti òdodo nítorí mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba, ẹ kò sì ní rí mi mọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Ní ti òdodo, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba, ẹ̀yin kò sì mọ̀ mí;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 16:10
26 Iomraidhean Croise  

Inu Oluwa dùn gidigidi nitori ododo rẹ̀; yio gbe ofin ga, yio si sọ ọ di ọlọlá.


Adọrin ọ̀sẹ li a pinnu sori awọn enia rẹ, ati sori ilu mimọ́ rẹ, lati ṣe ipari irekọja, ati lati fi edidi di ẹ̀ṣẹ, ati lati ṣe ilaja fun aiṣedẽde ati lati mu ododo ainipẹkun wá ati lati ṣe edidi iran ati woli, ati lati fi ororo yàn Ẹni-mimọ́ julọ nì.


Mo ti ọdọ Baba jade wá, mo si wá si aiye: ẹ̀wẹ, mo fi aiye silẹ, mo si nlọ sọdọ Baba.


Ṣugbọn nisisiyi emi nlọ sọdọ ẹniti o rán mi; kò si si ẹnikan ninu nyin ti o bi mi lẽre pe, Nibo ni iwọ nlọ?


Bi Mose si ti gbé ejò soke li aginjù, gẹgẹ bẹ̃li a kò le ṣe alaigbé Ọmọ-enia soke pẹlu:


Ẹlomiran li ẹniti njẹri mi; emi si mọ̀ pe, otitọ li ẹrí mi ti o jẹ́.


Nitorina Jesu wi fun wọn pe, Niwọn igba diẹ si i li emi wà pẹlu nyin, emi o si lọ sọdọ ẹniti o rán mi.


Niwọnbi o ti da ọjọ kan, ninu eyi ti yio ṣe idajọ aiye li ododo, nipasẹ ọkunrin na ti o ti yàn, nigbati o ti fi ohun idaniloju fun gbogbo enia, niti o jí i dide kuro ninu okú.


Jesu na yi li Ọlọrun ti ji dide, ẹlẹri eyiti gbogbo wa iṣe.


Ṣugbọn ẹnyin sẹ́ Ẹni-Mimọ́ ati Olõtọ nì, ẹnyin si bere ki a fi apania fun nyin;


Tani ninu awọn woli ti awọn baba nyin kò ṣe inunibini si? nwọn si ti pa awọn ti o ti nsọ asọtẹlẹ ti wíwa Ẹni Olõtọ nì; ẹniti ẹnyin si ti di olufihàn ati olupa:


Nitori ninu rẹ̀ li ododo Ọlọrun hàn lati igbagbọ́ de igbagbọ́: gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ṣugbọn olododo yio wà nipa igbagbọ́.


Ṣugbọn nipasẹ rẹ̀ li ẹnyin wà ninu Kristi Jesu, ẹniti Ọlọrun fi ṣe ọgbọ́n, ati ododo, ati isọdimimọ́, ati idande fun wa:


Nitori o ti fi i ṣe ẹ̀ṣẹ nitori wa, ẹniti kò mọ̀ ẹ̀ṣẹkẹṣẹ rí; ki awa le di ododo Ọlọrun ninu rẹ̀.


Nitori nipa Ẹmí awa nfi igbagbọ duro de ireti ododo.


Laiṣiyemeji, titobi ni ohun ijinlẹ ìwa-bi-Ọlọrun, ẹniti a fihan ninu ara, ti a dalare ninu Ẹmí, ti awọn angẹli ri, ti a wasu rẹ̀ lãrin awọn orilẹ-ede, ti a gbagbọ ninu aiye, ti a gba soke sinu ogo.


Nitoriti Kristi pẹlu jìya lẹ̃kan nitori ẹ̀ṣẹ wa, olõtọ fun awọn alaiṣõtọ, ki o le mu wa de ọdọ Ọlọrun, ẹniti a pa ninu ara, ṣugbọn ti a sọ di ãye ninu ẹmí:


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan