Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 15:7 - Bibeli Mimọ

7 Bi ẹnyin ba ngbé inu mi, ti ọ̀rọ mi ba si ngbé inu nyin, ẹ ó bère ohunkohun ti ẹ ba fẹ, a o si ṣe e fun nyin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

7 Bí ẹ bá ń gbé inú mi, tí ọ̀rọ̀ mi ń gbé inú yín, ẹ óo bèèrè ohunkohun tí ẹ bá fẹ́, ẹ óo sì rí i gbà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Bí ẹ̀yin bá ń gbé inú mi, tí ọ̀rọ̀ mi bá sì gbé inú yín, ẹ ó béèrè ohunkóhun tí ẹ bá fẹ́, a ó sì ṣe é fún yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 15:7
24 Iomraidhean Croise  

Ni Gibeoni ni Oluwa fi ara rẹ̀ hàn Solomoni loju alá li oru: Ọlọrun si wipe, Bère ohun ti emi o fi fun ọ.


Lotitọ nigbana ni iwọ o ni inu didùn ninu Olodumare, iwọ o si gbe oju rẹ soke sọdọ Ọlọrun.


Bẹ̃ni emi kò pada sẹhin kuro ninu ofin ẹnu rẹ̀, emi si pa ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ mọ́ jù ofin inu mi lọ.


Ọ̀rọ rẹ ni mo pamọ́ li aiya mi, ki emi ki o má ba ṣẹ̀ si ọ.


Ṣe inu-didùn si Oluwa pẹlu, on o si fi ifẹ inu rẹ̀ fun ọ.


Ibẹ̀ru enia buburu mbọwá ba a: ṣugbọn ifẹ olododo li a o fi fun u.


On si kọ́ mi pẹlu, o si wi fun mi pe, jẹ ki aiya rẹ ki o gbà ọ̀rọ mi duro: pa ofin mi mọ́ ki iwọ ki o si yè.


Nigbana ni imọlẹ rẹ yio bẹ́ jade bi owurọ, ilera rẹ yio sọ jade kánkán: ododo rẹ yio si lọ ṣaju rẹ; ogo Oluwa yio kó ọ jọ.


Nigbati a ri ọ̀rọ rẹ, emi si jẹ wọn, ọ̀rọ rẹ si jẹ inu didùn mi, nitori orukọ rẹ li a fi npè mi, iwọ Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun!


Bère, a o si fifun nyin; wá kiri, ẹnyin o si ri; kànkun, a o si ṣí i silẹ fun nyin.


Ohunkohun ti ẹnyin ba si bère li orukọ mi, on na li emi ó ṣe, ki a le yìn Baba logo ninu Ọmọ.


Ki iṣe ẹnyin li o yàn mi, ṣugbọn emi li o yàn nyin, mo si fi nyin sipo, ki ẹnyin ki o le lọ, ki ẹ si so eso, ati ki eso nyin le duro; ki ohunkohun ti ẹ ba bère lọwọ Baba li orukọ mi, ki o le fi i fun nyin.


Ati ni ijọ na ẹnyin kì o bi mi lẽre ohunkohun. Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ohunkohun ti ẹnyin ba bère lọwọ Baba li orukọ mi, on o fifun nyin.


Nitorina Jesu wi fun awọn Ju ti o gbà a gbọ́ pe, Bi ẹnyin ba duro ninu ọ̀rọ mi, nigbana li ẹnyin jẹ ọmọ-ẹhin mi nitõtọ.


Mo mọ̀ pe irú-ọmọ Abrahamu li ẹnyin iṣe; ṣugbọn ẹ nwá ọ̀na ati pa mi, nitori ọ̀rọ mi kò ri àye ninu nyin.


Ṣugbọn o wà labẹ olutọju ati iriju titi fi di akokò ti baba ti yàn tẹlẹ.


Njẹ mo ni, Ẹ ma rìn nipa ti Ẹmí, ẹnyin kì yio si mu ifẹkufẹ ti ara ṣẹ.


Ati ọ̀rọ wọnyi, ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, ki o ma wà ni àiya rẹ:


Ẹ jẹ ki ọ̀rọ Kristi mã gbé inu nyin li ọ̀pọlọpọ ninu ọgbọ́n gbogbo; ki ẹ mã kọ́, ki ẹ si mã gbà ara nyin niyanju ninu psalmu, ati orin iyìn, ati orin ẹmí, ẹ mã fi ore-ọfẹ kọrin li ọkàn nyin si Oluwa.


Emi kọwe si nyin, ẹnyin baba, nitoriti ẹnyin ti mọ̀ ẹniti o wà li àtetekọṣe. Emi ti kọwe si nyin, ẹnyin ọdọmọkunrin, nitoriti ẹnyin li agbara, ti ọ̀rọ Ọlọrun si duro ninu nyin, ti ẹ si ṣẹgun ẹni buburu nì.


Ṣugbọn ìfororó-yàn ti ẹnyin ti gbà lọwọ rẹ̀, o ngbe inu nyin, ẹnyin kò si ni pe ẹnikan nkọ́ nyin: ṣugbọn ìfororó-yàn na nkọ́ nyin li ohun gbogbo ti o jẹ otitọ, ti kì si iṣe èké, ani gẹgẹ bi o si ti kọ́ nyin, ẹ mã gbe inu rẹ̀.


Ati ohunkohun ti awa ba bère, awa nri gbà lọdọ rẹ̀, nitoriti awa npa ofin rẹ̀ mọ́, awa si nṣe nkan wọnni ti o dara loju rẹ̀.


Eyi si ni igboiya ti awa ni niwaju rẹ̀, pe bi awa ba bère ohunkohun gẹgẹ bi ifẹ rẹ̀, o ngbọ ti wa:


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan