Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 15:5 - Bibeli Mimọ

5 Emi ni àjara, ẹnyin li ẹka. Ẹniti o ngbé inu mi, ati emi ninu rẹ̀, on ni yio so eso ọ̀pọlọpọ: nitori ni yiyara nyin kuro lọdọ mi, ẹ ko le ṣe ohun kan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

5 “Èmi ni àjàrà, ẹ̀yin ni ẹ̀ka. Ẹni tí ó bá ń gbé inú mi, tí èmi náà sì ń gbé inú rẹ̀, yóo máa so èso pupọ. Ẹ kò lè dá ohunkohun ṣe lẹ́yìn mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 “Èmi ni àjàrà, ẹ̀yin ni ẹ̀ka. Ẹni tí ó ń gbé inú mi, àti èmi nínú rẹ̀, òun ni yóò so èso lọ́pọ̀lọpọ̀: nítorí ní yíya ara yín kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ kò lè ṣe ohun kan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 15:5
28 Iomraidhean Croise  

Eso ododo ni igi ìye; ẹniti o ba si yi ọkàn enia pada, ọlọgbọ́n ni.


Nwọn jẹ ẹ̀ṣẹ awọn enia mi, nwọn si gbe ọkàn wọn si aiṣedẽde wọn.


Ṣugbọn ko ni gbongbo ninu ara rẹ̀, o si pẹ diẹ li akokò kan; nigbati wahalà tabi inunibini si dide nitori ọ̀rọ na, lojukanna a kọsẹ̀.


Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Bikoṣepe wóro alikama ba bọ́ si ilẹ̀, ti o ba si kú, o wà on nikan: ṣugbọn bi o ba kú, a si so ọ̀pọlọpọ eso.


Ki iṣe ẹnyin li o yàn mi, ṣugbọn emi li o yàn nyin, mo si fi nyin sipo, ki ẹnyin ki o le lọ, ki ẹ si so eso, ati ki eso nyin le duro; ki ohunkohun ti ẹ ba bère lọwọ Baba li orukọ mi, ki o le fi i fun nyin.


Nigbana ni Jesu dahùn, o si wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ọmọ kò le ṣe ohunkohun fun ara rẹ̀, bikoṣe ohun ti o ba ri pe Baba nṣe: nitori ohunkohun ti o ba nṣe, wọnyi li Ọmọ si nṣe bẹ̃ gẹgẹ.


Ibaṣepe ọkunrin yi ko ti ọdọ Ọlọrun wá, kì ba ti le ṣe ohunkohun.


Kò si si igbala lọdọ ẹlomiran: nitori kò si orukọ miran labẹ ọrun ti a fifunni ninu enia, nipa eyiti a le fi gbà wa là.


Bẹ̃li awa, ti a jẹ́ pipọ, a jẹ́ ara kan ninu Kristi, ati olukuluku ẹ̀ya ara ọmọnikeji rẹ̀.


Ṣugbọn nisisiyi ti a sọ nyin di omnira kuro ninu ẹ̀ṣẹ, ti ẹnyin si di ẹrú Ọlọrun, ẹnyin ni eso nyin si ìwa mimọ́, ati opin rẹ̀ ìye ainipẹkun.


Bẹ̃li ẹnyin ará mi, ẹnyin pẹlu ti di okú si ofin nipa ara Kristi: ki ẹnyin kì o le ni ẹlomiran, ani ẹniti a jinde kuro ninu okú, ki awa ki o le so eso fun Ọlọrun.


Ago ibukún ti awa nsure si, ìdapọ ẹ̀jẹ Kristi kọ́ iṣe? Akara ti awa mbù, ìdapọ ara Kristi kọ́ iṣe?


Nitori gẹgẹ bi ara ti jẹ ọ̀kan, ti o si li ẹ̀ya pupọ, ṣugbọn ti gbogbo ẹ̀ya ara ti iṣe pupọ jẹ́ ara kan: bẹ̃ si ni Kristi pẹlu.


Njẹ ara Kristi li ẹnyin iṣe, olukuluku nyin si jẹ ẹ̀ya ara rẹ̀.


Nitori awa kò le ṣe ohun kan lodi si otitọ, bikoṣe fun otitọ.


Njẹ ẹniti nfi irugbin fun afunrugbin, ati akara fun onjẹ, yio fi irugbin fun nyin, yio si sọ ọ di pipọ fun irugbin, yio si mu eso ododo nyin bi si i.)


Ṣugbọn eso ti Ẹmí ni ifẹ, ayọ̀, alafia, ipamọra, ìwa pẹlẹ, iṣore, igbagbọ́,


(Nitori eso Ẹmí wà niti iṣore gbogbo, ati ododo, ati otitọ;)


Lẹhin igbati ẹ ti kun fun eso ododo lati ọdọ Jesu Kristi, fun ogo ati iyìn Ọlọrun.


Emi le ṣe ohun gbogbo ninu Kristi ẹniti nfi agbara fun mi.


Kì iṣe nitoriti emi nfẹ ẹ̀bun na: ṣugbọn emi nfẹ eso ti yio mã di pupọ nitori nyin.


Ki ẹ le mã rìn ni yiyẹ niti Oluwa si ìwu gbogbo, ki ẹ ma so eso ninu iṣẹ rere gbogbo, ki ẹ si mã pọ si i ninu ìmọ Ọlọrun;


Eyiti o de ọdọ nyin, ani bi o ti nso eso pẹlu ni gbogbo aiye ti o si npọ si i, bi o ti nṣe ninu nyin pẹlu, lati ọjọ ti ẹnyin ti gbọ́, ti ẹnyin si ti mọ̀ ore-ọfẹ Ọlọrun li otitọ:


Gbogbo ẹ̀bun rere ati gbogbo ẹ̀bun pipé lati oke li o ti wá, o si nsọkalẹ lati ọdọ Baba imọlẹ wá, lọdọ Ẹniti kò le si iyipada tabi ojiji àyida.


Ẹniti ẹnyin ntọ̀ bọ̀, bi si okuta ãye, ti a ti ọwọ́ enia kọ̀ silẹ nitõtọ, ṣugbọn lọdọ Ọlọrun, àṣayan, iyebiye,


Ṣugbọn ẹ mã dàgba ninu õre-ọfẹ ati ninu ìmọ Oluwa ati Olugbala wa Jesu Kristi; ẹniti ogo wà fun nisisiyi ati titi lai. Amin.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan