Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 15:12 - Bibeli Mimọ

12 Eyi li ofin mi, pe ki ẹnyin ki o fẹran ara nyin, gẹgẹ bi mo ti fẹràn nyin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

12 Àṣẹ mi nìyí; ẹ fẹ́ràn ara yín gẹ́gẹ́ bí mo ti fẹ́ràn yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Èyí ni òfin mi, pé kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ràn ara yín, gẹ́gẹ́ bí mo ti fẹ́ràn yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 15:12
16 Iomraidhean Croise  

Emi ti fẹ nyin, li Oluwa wi. Ṣugbọn ẹnyin wipe, Ninu kili o fẹ wa? Arakunrin Jakobu ki Esau iṣe? li Oluwa wi: bẹli emi sa fẹ Jakobu,


Ofin titun kan ni mo fifun nyin, Ki ẹnyin ki o fẹ ọmọnikeji nyin; gẹgẹ bi emi ti fẹran nyin, ki ẹnyin ki o si le fẹran ọmọnikeji nyin.


Nkan wọnyi ni mo palaṣẹ fun nyin pe, ki ẹnyin ki o fẹran ara nyin.


Niti ifẹ ará, ẹ mã fi iyọ́nu fẹran ara nyin: niti ọlá, ẹ mã fi ẹnikeji nyin ṣaju.


Ẹ si mã rìn ni ifẹ, gẹgẹ bi Kristi pẹlu ti fẹ wa, ti o si fi ara rẹ̀ fun wa li ọrẹ ati ẹbọ fun Ọlọrun fun õrùn didun.


Ki Oluwa si mã mu nyin bisi i, ki ẹ si mã pọ̀ ninu ifẹ si ọmọnikeji nyin, ati si gbogbo enia, gẹgẹ bi awa ti nṣe si nyin:


Ṣugbọn niti ifẹ awọn ará, ẹ kò tun fẹ ki ẹnikẹni kọwe si nyin: nitori a ti kọ́ ẹnyin tikaranyin lati ọdọ Ọlọrun wá lati mã fẹ ara nyin.


Iṣẹ wa ni lati mã dupẹ lọwọ Ọlọrun nigbagbogbo nitori nyin, ará, ani gẹgẹ bi o ti yẹ, nitoripe igbagbọ́ nyin ndàgba gidigidi, ati ifẹ olukuluku nyin gbogbo si ara nyin ndi pupọ;


Niwọnbi ẹnyin ti wẹ̀ ọkàn nyin mọ́ nipa ìgbọran nyin si otitọ nipa Ẹmí si ifẹ ará ti kò li ẹ̀tan, ẹ fẹ ọmọnikeji nyin gidigidi lati ọkàn wá.


Lakotan, ki gbogbo nyin ṣe oninu kan, ẹ mã ba ará nyin kẹdun, ẹ ni ifẹ ará, ẹ mã ṣe ìyọnú, ẹ ni ẹmí irẹlẹ.


Jù gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ ni ifẹ ti o gbóna larin ara nyin: nitori ifẹ ni mbò ọ̀pọlọpọ ẹ̀ṣẹ mọlẹ.


Eyi si li ofin rẹ̀, pe ki awa ki o gbà orukọ Jesu Kristi Ọmọ rẹ̀ gbọ́, ki a si fẹràn ara wa, gẹgẹ bi o ti fi ofin fun wa.


Ofin yi li awa si ri gbà lati ọwọ́ rẹ̀ wá, pe ẹniti o ba fẹran Ọlọrun ki o fẹran arakunrin rẹ̀ pẹlu.


Njẹ nisisiyi mo bẹ̀ ọ, obinrin ọlọlá, kì iṣe bi ẹnipe emi nkọwe ofin titun kan si ọ, bikọse eyi ti awa ti ni li àtetekọṣe, pe ki awa ki o fẹràn ara wa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan