Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 14:9 - Bibeli Mimọ

9 Jesu wi fun u pe, Bi akokò ti mo ba nyin gbé ti pẹ to yi, iwọ kò si ti imọ̀ mi sibẹ̀ Filippi? Ẹniti o ba ti ri mi, o ti ri Baba; iwọ ha ti ṣe wipe, Fi Baba hàn wa?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 Jesu wí fún un pé, “Bí mo ti pẹ́ lọ́dọ̀ yín tó yìí, sibẹ ìwọ kò mọ̀ mí, Filipi? Ẹni tí ó bá ti rí mi ti rí Baba. Kí ló dé tí o fi tún ń sọ pé, ‘Fi Baba hàn wá?’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Jesu wí fún un pé, “Bí àkókò tí mo bá yín gbé ti tó yìí, ìwọ, kò sì tí ì mọ̀ mí síbẹ̀ Filipi? Ẹni tí ó bá ti rí mi, ó ti rí Baba: Ìwọ ha ti ṣe wí pé, ‘Fi Baba hàn wá!’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 14:9
16 Iomraidhean Croise  

Abimeleki si pè Isaaki, o si wipe, Kiyesi i, nitõtọ aya rẹ ni iṣe: iwọ ha ti ṣe wipe, Arabinrin mi ni? Isaaki si wi fun u pe, Nitoriti mo wipe, ki emi ki o má ba kú nitori rẹ̀.


OLUWA ni mo gbẹkẹ mi le: ẹ ha ti ṣe wi fun ọkàn mi pe, sá bi ẹiyẹ lọ si òke nyin?


Bawo li o ṣe wipe, emi kò ṣe alaimọ́, emi kò tọpa Baalimu? wò ọ̀na rẹ li afonifoji, mọ̀ ohun ti iwọ ti ṣe, iwọ dabi abo ibakasiẹ ayasẹ̀ ti nrin ọ̀na rẹ̀ ka.


O si da wọn lohùn, o si wipe, Iran alaigbagbọ́ yi, emi o ti ba nyin gbé pẹ to? emi o si ti mu sũru fun nyin pẹ to? ẹ mu u wá sọdọ mi.


Ẹnyin agabagebe, ẹnyin le moye oju ọrun ati ti aiye; ẽhatiṣe ti ẹnyin kò le mọ̀ akokò yi?


Ọ̀rọ na si di ara, on si mba wa gbé, (awa si nwò ogo rẹ̀, ogo bi ti ọmọ bíbi kanṣoṣo lati ọdọ Baba wá,) o kún fun ore-ọfẹ ati otitọ.


Ọ̀kan li emi ati Baba mi jasi.


Ẹniti o ba si ri mi, o ri ẹniti o rán mi.


Li ọjọ na li ẹnyin o mọ̀ pe, emi wà ninu Baba mi, ati ẹnyin ninu mi, ati emi ninu nyin.


Ibaṣepe ẹnyin ti mọ̀ mi, ẹnyin iba ti mọ̀ Baba mi pẹlu: lati isisiyi lọ ẹnyin mọ̀ ọ, ẹ si ti ri i.


Nitorina nwọn wi fun u pe, Nibo ni Baba rẹ wà? Jesu dahùn pe, Ẹnyin kò mọ̀ mi, bẹli ẹ kò mọ̀ Baba mi: ibaṣepe ẹnyin mọ̀ mi, ẹnyin iba si ti mọ̀ Baba mi pẹlu.


Njẹ bi a ba nwasu Kristi pe o ti jinde kuro ninu okú, ẽhatiṣe ti awọn miran ninu nyin fi wipe, ajinde okú kò si?


Ẹniti o tilẹ jẹ aworan Ọlọrun, ti kò ka a si iwọra lati ba Ọlọrun dọgba:


Ẹniti iṣe aworan Ọlọrun ti a kò ri, akọbi gbogbo ẹda:


Ẹniti iṣe itanṣan ogo rẹ̀, ati aworan on tikararẹ, ti o si nfi ọ̀rọ agbara rẹ̀ mu ohun gbogbo duro, lẹhin ti o ti ṣe ìwẹnu ẹ̀ṣẹ, o joko li ọwọ́ ọtún Ọlánla li oke;


Awa si mọ̀ pe Ọmọ Ọlọrun de, o si ti fi òye fun wa, ki awa ki o le mọ̀ ẹniti iṣe otitọ, awa si mbẹ ninu ẹniti iṣe otitọ, ani ninu Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi. Eyi li Ọlọrun otitọ, ati ìye ainipẹkun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan